You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sleeping at work: Ǹjẹ o yẹ kí èèyàn máa sùn lẹ́nu iṣẹ́?
Ijọba ilẹ̀ Amẹrika ti sọ pé ewú wà ti ẹnikẹni bá n sún òòrun lẹnu iṣẹ́, sùgbọ́n àwọn onimọ nipa oorun sàlàye pé ìjọba ni láti tún èrò rẹ̀ pa.
Ijọba ti pinnu láti gbé ìgbẹ́sẹ̀ to nípọn lóri ẹni to ba ń sùn lẹ́nu iṣẹ́.
John Berr to jẹ onímọ nípa oorun sọ pe bó tilẹ̀ jé pé àwọn òṣiṣẹ́ ìjọba tí ń ja ìjà yìí típẹ̀, ṣùgbọ́n ti ìjọba ko kọbíara síi.
"Wọn ò gbà àwọn ènìyàn láàyẹ lati sùn ní ẹnu iṣẹ́ pàápàá jùlọ ni àwọn ilé iṣẹ́ ìjọba àyàfi tí ẹni náà ba gba àṣẹ, èyí wà nínú àtẹjáde ti ìjọba fi síta nínú oṣù yìí.
Kò si ẹni to yé ìdí ti ìjọba fi gbé ìgbésẹ̀ yìí ṣugbọn wọ́n si kọ̀ láti sọ ǹkankan lée lóri bí gbogbo ènìyàn ṣe ń bẹnu ẹ̀tẹ́ lùú.
Ní ọdun 2018 ọfíísì agbẹjọrò àgbà fún ìpínlẹ̀ California fí àbájade ìwádìí kan nípa òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ mọ́tò kan to ń sún oorun wákàti mẹ́ta lójòòjúmọ lẹ́nu iṣẹ́ sita.
Ìròyìn sọ pé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì dọ́la ni ìjọba ń pàdànú láàrin ọdún mẹrin.
Bákan náà ní òṣìṣẹ́ tó ń sùn lẹ́nu iṣẹ́ n kó ìnira bá àwọn òṣìṣẹ́ to kù ni, nítorí àwọn kan ló ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ lásìkò tó n sùn.
Ọgá àgbà ilé ẹkọ kan ni iporuuru dé bi pé o ró pé òṣìṣẹ́ òhun ni àìsàn kan ti o ń mú kí o maa sùn lẹ́nú iṣẹ́.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bi ìjọba ṣe dẹkun ki òṣìṣẹ́ máa sùn lẹ́nu iṣẹ́ lé mu ọkàn pòruuru, síbẹ̀ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ o dúró lóri rẹ̀.
Ààrẹ ilé ìwòsàn obinrin Boston, Ọniṣegun oyinbo Lawrence Epstein, sọ pé o lé ni èèyan ààdọrin mílíọnù to ni ìṣòrò oorun ni ilẹ̀ Amerika.