Usman vs Masvidal: Àlùbami ní Kamuru na Jorge Masvidal láti dí Àmí Ẹ̀yẹ rẹ mú!

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ti ijakadi kọ, baba ni ba n jẹ ni rọ ri fun ọmọ Naijiria, Kamaru Usman lẹyin to lu Jorge Masvidal ni alubami lati di Ami Ẹyẹ UFC Welterweight Champion rẹ mu.

Kamaru Usman ti wọn tun ma n pe ni ‘Nigerian Nightmare’ lo wọ gbagede ifẹsẹkubiojo pẹlu igboya to si lu akẹgbẹ rẹ ni alubami.

Usman, ẹni dun mẹtalelọgbọn naa jẹ ọmọ Naijiria ati ti orilẹede Amerika naa.

Idije to waye ni Ilu Abu Dhabi, ni orilẹede United Arab Emirates naa yẹ ko jẹ ija laarin Usman ati Gilbert Burns ni, amọ o lugbadi arun Coronavirus ni ko ṣe le kopa ninu ija naa.

Lẹyin naa ni Aarẹ Afẹṣẹkubiojo, Dana White wa kesi Masvidal boya o le ja ija naa.

Masvidal gba lati ja, ti o si gbiyanju, koda o ru lara si pẹlu gbogbo akitiyan rẹ lati gbaradi fun idije naa laarin ọjọ mẹwaa.

Amọ, ẹpa o boro mọ ni pẹlu iru iya ti Usman fi jẹ Masvidal lati di Ami Ẹyẹ rẹ mu gẹgẹ bi Alami Ẹyẹ UFC Welterweight Champion.