You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Lagos Collapsed Buildings: Ẹ yọ ilé náà kúrò pátápátá - LASEMA
Eeyan mẹta lo padanu ẹmi ninu iṣẹlẹ ijamba ile alaja mẹta kan to dawo nilu Eko.
Ladugbo Freeman Street ni Isalẹ Eko ni ijamba yi ti waye lowurọ ọjọ Abamẹta.
Ọga ileeṣẹ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri nilu Eko, Femi Osanyintolu fidi ọrọ yi mulẹ fun BBC ti o si sọ pe awọn doola ẹmi eeyan mẹsan nibẹ.
Gẹgẹ bi awọn ileeṣẹ iroyin Naijiria kan ti ṣe sọ,ni nkan bi ago mẹrin kọja diẹ lowurọ ni ile naa dawo nigba ti awọn olugbe rẹ ṣi n sun lọwọ.
Osanyintolu ni pe ninu awọn to ku ninu iṣẹlẹ naa ni ọmọdekunrin kan ati agbalagba ọkunrin kan.
''A ṣi wa nibi iṣẹlẹ naa bayi ti a ṣi n gbiyanju lati doola ẹmi awọn miran ninu ijamba yi.''
Nigba ti BBC beere pe ki lo ṣe okunfa iṣẹlẹ naa Osanyintolu sọ pe ile yii ti wa lara awọn ile ti wọn ti pinu lati wo teletele.
Loju opo Twitter awọn eeyan ti n ṣalabapin fidio iṣẹlẹ naa
Ninu fọnran fidio ta ri loju opo ayelujara niṣe lawọn eeyan pe jọ laibikita itankalẹ arun Covid-19.
Lọpọ igba ti ile ba ti wo ni ilu Eko, ipenija nla ni o ma n jẹ fawọn to n ṣeto idoola ẹmi lati ṣiṣẹ wọn nitori ero ti ma n pọju to wa woran nibẹ.