Onitsha Building Collapse: Ilé alájà mẹ́ta wó lúlẹ̀, ènìyàn kan ti kú

Ile alaja mẹta kan ti wọn n kọ lọwọ ti dawo lulẹ nilu Onitsha, nipinlẹ Anambra.

Ilu naa lo wo lulẹ l'ọsan oni lasiko ti awọn oṣiṣẹ abanikọle n ṣiṣẹ lọwọ.

A gbọ wi pe eniyan meje ni ile naa wo lu mọlẹ. Wọn ti ri awọn mẹẹrin gbe lọ sile iwosan lara wọn.

Ṣugbọn o ṣeni laanu pe onimọ-ẹrọ to n mojuto kikọ ile naa ti jẹ Ọlọrun ni pe.

Wọn ko si ti i ri awọn to ku yọ