You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Chadwick Boseman wife: Simone Ledward ni ìyàwó Chadwick Boseman, wọ́n sì 'sègbéyàwó kó tó jáde láyé
Gbajugbaja oṣere sinima ni, Chadwick Boseman to ku laipẹ yii ko ku laapọn o, o ṣe igbeyawo pẹlu iyawo rẹ Taylor Simeone Ledward ki o to jade laye.
Ni osu kẹwaa, ọdun 2019 lawọn mejeeji ṣe eto mọmi n mọ ọ ki wọn to ṣe igbeyawo bonkẹlẹ ki o to jade laye.
Ni ọdun 2015 ni aniyan ifẹ laarin awọn mejeeji yii kọkọ lu sita nigba ti awọn ayaworan kọkọ kofiri wọn pọ ni papakọ ofurufu ilu Los Angeles International Airport.
Ni oṣu kẹta ọdun 2019 ni oloogbe Chadwick Boseman kọkọ sọrọ ni pa ọrọ ifẹ oun ati Ledward ni ibi eto ami ẹyẹ 50th NAACP Image Awards.
- Èèyàn méjì kú, méjìdínlógóje míì ṣẹ̀ṣẹ̀ kó COVID-19 lọ́jọ́ Àìkú
- Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Tolanibaj, Wathoni àti Brighto ni wọ́n lé kúrò ni BbNaija l'ọ́sẹ̀ yìí
- Irọ́ ni, kò sí olóyún nínú àwọn tí Tírélà pa ní Ondo ṣùgbọ́n awakọ̀ ti sá lọ- Ọlọ́pàá Ondo
- Ààrùn coronavirus tó ràn mí jẹ́ kí n mọ̀ pé àlààfo díẹ̀ ló wà láàrin ikú àti ìyè - Lola Alao
Boseman jade laye lẹyin ọdun mẹrin ti aisan jẹjẹrẹ ti n ba a finra, iyawo rẹ naa si wa pẹlu rẹ ni ile rẹ to wa ni Los Angeles nigba to mi eemi ikẹyin.
Akọrin ni Ledward, ileewe giga Carlifornia State lo lọ.
Iya iya Ledward pẹlu sọ si ọrọ ifẹ aarin awọn mejeeji yii to si ni ifẹ wa laarin wọn, inu awọn mejeeji si dun si ara wọn.
Wọn bọwọ fun ara wọn, inu ọkọ dun, inu iyawo naa si dun pẹlu.
Oṣu kẹwaa lẹyin ti wọn ṣe mọ mi n mọ o ni Chadwick jade laye
.Ni eyi to fi jẹ ki Boseman fi iyawo ati ẹbi silẹ lọ.
Ṣe ọmọ ilẹ̀ Afirika ni Boseman Chadwick?
Oṣere Wakanda ti gbogbo aye n pe ni Black Panther le sọ ede isiXhosa to jẹ ede South Africa.
Awọn ibudo itan inu sinima Black Panther to jẹ ibi ala rere naa fi ara pẹ ila oorun Naijiria ninu ere Black Panther to jẹ kikida alawọ dudu lo ṣee lọdun 2018.
Ọpọ ọdọ lo n wo Chadwick gẹgẹ bii awokọṣẹ rere ni gbogbo agbaye nitori pe o fi ifẹ han si awọn alarun jẹjẹrẹ pupọ lai naani pe oun naa n ba aisan naa finra de gongon lọdun mẹrin gbako.
Wo ọ̀rọ̀ tí gbogbo agbàyé fẹ́ràn jùlọ lójú òpó Twitter
Gbogbo aye lo ṣedaro iku gbajumọ oṣere tiata to ṣe ere Black Panther, Chadwick Boseman to jade laye lẹni ọdun mẹtalelogoji.
Boseman jade laye lẹyin idojukọ ọdun mẹrin pẹlu aisan jẹjẹrẹ.
- Wọ́n tún ti pa omidan ẹni ọdún 18 míràn l'Akinyele ní ìlú Ibadan
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko kéde ọjọ́ tí àwọn iléèwé gígá yóò wọlé
- Fún ọjọ́ kẹ́ta, ìpínlẹ̀ Plateau gbé ipò kínní lórí àtẹ COVID-19! Èèyàn 250 míràn lárùn náà
- Ìdí tí mo fi gbàdúrà ìyàwó bíi Chanel Chin fáwọn tó d'ẹ̀bi ìkọ̀sílẹ̀ rẹ̀ rù mí rèé - Oluwo
Loju opo Twitter rẹ si ni wọn ti tufọ iku rẹ laṣalẹ ọjọ Ẹti.
Atẹjade to waye loju opo twitter rẹ leyi ti wọn fi tufọ rẹ ti di ọrọ ori twitter ti awọn eeyan fi ifẹ han si julọ lagbaye ninu itan idasilẹ oju opo ayelujara Twitter.
Awọn alaṣẹ oju opo ikansiraẹni Twitter lo fi idi eyi mulẹ ninu atẹjade kan ti wọn fi sita ni ọjọ Abamẹta.
Lati igba ti atẹjade ti a n sọrọ rẹ ọhun ti jade loju opo Twitter Chadwick Boseman ni irọlẹ ọjọ Ẹti, o din diẹ ni miliọnu mẹfa eeyan (6.5 million) to ti tẹ eroja ififẹ han (Likes) to wa ni isalẹ oju opo naa.
Ipa ti Boseman ko ninu sinima agbelewo to fọnrere agbara eeyan alawọ dudu ni, Black Panther lo sọ ọ di gbajugbaja.
ọdun 2016 lo bẹrẹ si ni wọ iya ija pẹlu aisan jẹjẹrẹ ki o to kọja afarada, to si gba ẹmi rẹ ni Los Angeles ni ipinlẹ California, Amẹrika.
Wo àpẹẹrẹ, àti ǹkan tó ń fa 'colon cancer' tó pa Chadwick Boseman 'Black Panther'
Aarun Colon cancer lo ṣokunfa iku to pa gbajugbaja oṣere Chadwick Aaron Boseman 'Black Panther'.
Iyalẹnu ni iku gbajugbaja naa jẹ fun ọpọlọpọ eniyan kaakiri agbaye, nitori pe ko fẹẹ si ẹni to mọ pe iru aisan bẹẹ n ṣe e ko to ku.
Ọdun mẹrin sẹyin ni awọn dokita sọ fun un pe o ni jẹjẹrẹ inu ifun, to si ti wọ ipele kẹta nigba naa. Aisan naa lo pada pa a , lẹyin to wọ ipele kẹrin.
- Wo ọ̀nà márùn ún tí o lè gbà dáàbò bò ara rẹ lọ́wọ́ ìjàmbá láì gbé ìbọn!
- A fí ara mọ́ ìdájọ́ ikú Sharia tó tọ́ sí Olórin Yahaya- ẹgbẹ́ Amòfin Mùsùlùmí ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Kano
- Ilé ẹjọ́ ju olè orí omi mẹ́ta sí ẹ̀wọ̀n, ó tún ní kí wọ́n san 60 miliọ̀nù
- Àlàyé rèé lórí bo ṣe le è dá Emèrè mọ̀ tàbí dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ wọn
- Ìdè jáá! Ọmọkùnrin tí bàbá rẹ̀ tì mọ́lé bíi ẹlẹ́wọ̀n f'ọ́dún méje ní Kano gba ìtúsílẹ̀!
Nitori eyi, ọpọ lo ti n wadii irufẹ jẹjẹrẹ ti wọn n pe ni colon cancer, ati awọn nkan to le fa a.
Gẹgẹ bi akọsilẹ to wa ni ori ayelujara ileeṣẹ eto ilera ilẹ United Kingdom, inu ifun to tobi ju ninu ara, ni jẹjẹrẹ naa ti ma n bẹrẹ.
O si jẹ ọkan lara awọn aisan jẹjẹrẹ to wọpọ julọ. Awọn ti ọjọ ori wọn si ti le ni ọgọta ọdun lo ṣaba ma n ni aisan yii.
Awọn apẹẹrẹ wo lo ma n fihan?
- Yiya igbẹ ju bo ṣe yẹ lọ lai dawọ duro, ti yoo si tun jẹ eyi to ṣan
- Ẹjẹ yoo ma wa ninu igbẹ lai ni idi kankan
- Inu rirun ni gbogbo igba, inira ninu ikun, tabi ki ikun o wu - eyi le waye lẹyin ounjẹ jijẹ, o si le mu ki ounjẹ kankan o ma wu eeyan jẹ
- Ẹni naa yoo ma a ru.
Awọn apẹẹrẹ yii le jẹ ti aisan miran, yatọ si colon cancer. Nitori naa lo ṣe gbọdọ ri dokita ti o ba ṣe akiyesi naa to jẹ ajeji ni ara rẹ.
Awọn nkan to ma n fa jẹjẹrẹ colon cancer
Gẹgẹ bi ileeṣẹ eto ilera ilẹ UK ṣe sọ, ko si ẹni to mọ nkan to n fa jẹjẹrẹ yii ni pato, ṣugbọn awọn nkankan wa to le fi eniyan sinu ewu rẹ bii:
Ọjọ ori - eeyan bi i mẹsan ninu mẹwaa to ni aisan yii lo ti pe tabi le ni ọgọta ọdun
Ounjẹ - jijẹ ounjẹ to kun fun ẹran bi ti maalu, ewurẹ, agutan tabi ẹran ẹlẹdẹ le ṣokunfa jẹjẹrẹ yii Ko yọ awọn ẹran inu agolo naa silẹ.
Bi ara ba ṣe tobi si - Aisan yii tun wọpọ laarin awọn to ba sanra ju bo ṣe yẹ lọ
Ere idaraya - Ẹni ti kii ba ṣe ere idaraya, tabi fi ara ṣiṣẹ daadaa wa ninu ewu lati ni aisan yii
Ọti - mimu ọti le ṣakoba fun ọ, lati ni aisan colon cancer
Ẹni to ba n mu siga, igbo, ati awọn nkan miran naa le ni aisan yii
Ẹbí - ti o ba ni ibatan to sun mọ ọ (iya, baba, ẹgbọn tabi aburo) to ni aisan yii nigba ti ọjọ ori wọn ṣi wa ni abẹ aadọta ọdun, o ṣe e ṣe ki iwọ naa ni .
Yatọ si awọn nkan wọnyii, awọn to ba ni aisan bi ulcerative colitis fun bii ọdun mẹwa, naa le ni jẹjẹrẹ yii.
Oru ọjọ Satide ni ẹbi gbajugbaja oṣere sinima ni orilẹede Amẹrika, Chadwick Boseman ti ọpọ mọ fun ipa Black Panther to ko ninu ere sinima Black Panther, kede pe o ti jade laye.
Aarun jẹjẹrẹ lo ṣokunfa iku Boseman to dagbere faye lẹni ọdun mẹtalelogoji.
- Ọmọ Nàìjíríà ní ọjọ́ tirẹ̀ l'Ámẹ́ríkà
- Tunde Idiagbon, ọ̀gágun kògbagbẹ̀rẹ́ tó ní ẹ̀ẹ̀kan lóṣù ló yẹ kí ológun máa rẹ́rìín
- Awọn afurasí Babaláwo pa ìyáwó Ìmáàmù àgbà ìlú Ayere ní Kogi, Alayere dá sọ́rọ̀
- Wo àṣẹ tuntun tí Buhari gbé síta nípa owó iná ọba
- Bí ó ṣe lọ lágbo àwọn òṣèré Yollywood lọ́sẹ̀ yìí rèé
Iroyin sọ pe ni ilu Los Angeles lo ku si, iyawo ati awọn mọlẹbi rẹ gbogbo lo si wa lẹba rẹ nigba to mi eemi igbẹyin.
Atẹjade kan loju opo ayelujara rẹ fi sita pe ọdun mẹrin sẹyin ni o ti mọ pe oun laarun naa ṣugbọn o mọọmọ maa fi han sita faraye.
Iroyin iku Boseman ti domi tutu si agbo ere sinima ti ọpọlọpọ awọn oṣere ati eekan lagbo ere sinima lagbaye si ti n kẹdun iku rẹ.
- Ìdí tí mo fi gbàdúrà ìyàwó bíi Chanel Chin fáwọn tó d'ẹ̀bi ìkọ̀sílẹ̀ rẹ̀ rù mí rèé - Oluwo
- Ẹlikọ́pítà Quarom aviation já lulẹ̀ ní Ikeja, gbogbo èrò inú rẹ̀ ló ti tẹ́rí gbaṣọ!
- Oral Sex: Bóo bá ń gba ẹnu ní ìbálòpọ̀, wo àìsàn tóo lè kó lójú ara rẹ
- Wo bí o ṣe le fi ẹjọ́ sun àjọ FCCPC tí o bá ra ọjà tó ti 'expire'