You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Expired goods in Nigeria: Jíjẹ tàbí lílo nkan tí ọjọ́ ti lọ lórí rẹ̀ le fa àìsàn tàbí ikú
Ọjọbọ ni ajọ to n daabo bo ẹtọ awọn onibaara ni Naijiria, FCCPC, ti ẹka ileeṣẹ Apples and Pears Limited pa nilu Abuja.
Ileeṣẹ naa n ṣe awọn nkan ti ẹnu n jẹ bi i Laziz salad cream, Laziz mayonnaise, Laziz vegetable oil, ati awọn nakn miran.
Gẹgẹ bi ajọ FCCPC ṣe sọ ninu atẹjade kan to fi sita lori ayelujara Twitter rẹ, ajọ naa sọ pe awọn awọn eeyan kan to ra ororo ileeṣẹ naa ti ọjọ ti lọ lori wọn nilu Abuja lo fi ọrọ to ajọ naa l'eti.
Eyi si lo mu ki ajọ na wá olu ileeṣẹ na kan ni opopona Ibadan si Eko, ṣugbọn, ilẹkun ibẹ wa ni titi pa.
Ajọ FCCPc sọ pe ninu iwadii oun lo ti han pe ọna ti ko tọ ọ ni ileeṣẹ naa n gba ṣe ororo naa, to fi mọ bo ṣe n rọ oro naa sinu ọra, ni ẹka ileeṣẹ rẹ ni Abuja.
"Ẹka ileeṣẹ naa ti wa ni titi pa , bẹẹ ni yoo si wa tiit ti ajọ FCCPC ati NAFDAC yoo fi gbẹsẹ le awọn ọja ti ọjọ ti lọ lori wọn. Ati ti o ba to o tẹwa lọrun pe ileeṣẹ Apples and Pearsyoo ma ṣe iṣẹ rẹ lọna to ba ofin mu."
Sham T Kolo, Oludari ẹka iwadii ati ninu ajọ naa sọ fun BBC pe o ṣeni laanu pe awọn onibaara ọja ni Naijiria kii bikita lati yẹ deeti ọjọ ti nkan ti wọn fẹ ẹ ra yoo ti ẹnu bodo.
Wo igbesẹ to yẹ ki o gbe ṣaaju rira ọja kankan:
- Yẹ deeti ti wọn kọ si ara rẹ lati mọ ọjọ ti ko ni i ṣiṣẹ mọ
- Ti o ba wa ṣeeṣi ra iru ọja bẹ, o ni anfaani labẹ ofin lati da ọja naa pada si ile itaja ti o ti ra a pẹlu ẹri pe ibẹ lo ti ra
- Ofin sọ pe onile itaja naa gbọdọ gba a pada lọwọ rẹ, ko si fun ọ ni omira, tabi da owo rẹ pada.
- O ni ofin orilẹ-ede Naijira sọ pe awọn ile itaja ko gbọdọ to iru ọja ti ọjọ ba ti n lọ lori wọn si ori atẹ fun tita.
- Eyi gan-an lo ma n mu ki ọpọ wọn o ta ọja gbanjo, ki o ma ba bajẹ mọ wọn lọwọ.
- Ti o ba ti wa da a pada ti iru ẹni naa kọ lati gba tabi lati fi ẹjọ sun ajọ to n daabo bo ẹtọ onibara, FCCPC, o le pe sori nọmba 08056002020.
- Yatọ si eyi, o le le App ajọ naa, tabi lọ si ẹka ọfiisi wọn to ba sunmọ ọ lati fi ẹjọ sun lori iru ọja naa.
- Bakan naa lo le fi ẹjọ sun lori ayelujara Twitter, Facebook tabi imeeli.
O ṣalaye pe ohun to ṣe koko ni pe ki onibara la oju rẹ silẹ daadaa, ki o si fi iye si nkan ti o ba n ra nipa ọjọ ti iwulo rẹ yoo d'opin.
Ewu to wa ninu lilo tabi jijẹ ọja ti ọjọ ti lọ lori rẹ
Onimọ nipa eto ilera, Dokita Habibat Alimọ sọ pe bi ọjọ ba ti lọ lori nkan jijẹ tabi lilo tumọ si pe, anfaani ati iwulo rẹ ti n dinku tabi bajẹ.
O fi kun ọrọ rẹ pe inu rirun, eebi, igbẹ gbuuru, pipọ ẹjẹ, aisan jẹjẹrẹ, tabi iku ni lilo nkan bẹ ṣaba ma n yọri si.
Eyi si le mu ki ẹni naa di eero ileewosan.
"Bi ọjọ ba ṣe n lọ si lori rẹ, ni ewu to rọ mọ lilo iru nkan bẹ n pọ si. Ko ti ẹ tẹ lati jẹ iru nakn bẹ lẹyin ọjọ kan ti ọjọ ori rẹ ba ti kọja."
O sọ pe ko tọ ọ lati jẹ tabi lo ohunkohun ti ọjọ ba ti lọ lori rẹ nitori pe awọn kokoro aifojuri to lewu fun ara ni yoo ti farahan ninu iru nkan bẹ.
"Jijẹ iru nkan bẹ ko yatọ si jijẹ majele, ile iwosan si ni wọn gbọdọ gbe ẹni naa lọ ni kiakia."
O wa ṣeeṣe ki nkankan ma ṣẹlẹ ni kiakia lẹyin jijẹ tabi lilo nkan ti ọjọ ori rẹ ti kọja. Iru nkan bẹ ma n fi oró silẹ sinu agọ ara ni, to si le fa akoba lọjọ iwaju.
- Ilé ẹjọ́ ju ọmọ ìjọ tó fi ìpá bá ọmọ pásítọ̀ rẹ̀ sùn ní ìpínlẹ̀ Ondo sí ẹ̀wọ̀n gbére
- Ooni Ifẹ bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lú ètò BBNaija nítorí ó tàbùkù àsà Yoruba
- Ogun Àgbẹ́kọ̀yà, ẹ̀kọ́ wo ló yẹ́ kí àwá ọ̀dọ́ kọ́ níbẹ̀?
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun tí búwọlù ìlànà àyẹyẹ Ọṣun-Oṣogboo ọdún 2020
- Wo ọ̀nà márùn ún tí o lè gbà dáàbò bò ara rẹ lọ́wọ́ ìjàmbá láì gbé ìbọn!