You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Uganda Condom Case: Ilééṣẹ́ ìjọba àti aládáni wọ gàù nítórí Kọ́ńdọ̀mù tó fa HIV, gonorrhoea àti òyun
Ọmọ orilẹ-ede Uganda mẹta ti gbe ajọ to n mojuto ipese oogun lorilẹ-ede naa, ati ajọ aladani kan, Marie Stoppes, lọ sile ẹjọ, nitori pe wọn fi wọn sinu ewu aarun ati oyun airotẹlẹ.
Ọkan lara awọn ọkunrin naa sọ pe, oun lo kọndọmu ileeṣẹ Life Guard, ṣugbọn o ja lasiko ti oun n ni ibalopọ.
Oni iṣẹlẹ yii mu ki oun ko aarun HIV.
- Ṣé irúfẹ́ oúnjẹ tí ò ń jẹ́ lè jẹ́ kí o gbádùn ìbálòpọ̀ rẹ síi?
- Wò ó ọ̀nà láti mú ara rẹ dé ibi tó ga jùlọ nínú ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìlànà Tantra
- Àwọn àmì tó fi mọ̀ pé wọn ń fipá bá ọmọdébìnrin rẹ lòpọ̀
- Njẹ́ ẹ mọ̀ pé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ló n wo 'Blue film' jù
- Fásitì Ghana lé olùkọ́ méjì tí àṣírí wọ́n tú lórí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ lọlé
Ọkunrin keji ni tiẹ sọ pe, kọndọọmu ti oun naa ja, ti oun si ko aarun gonorrhoea.
Ni ti obinrin to wa laarin wọn, oun sọ pe kọndọmu naa ti ko ṣiṣẹ daada mu ki oun ni oyun airotẹlẹ.
Ajọ aladani naa lo n ṣe alagbata kọndọmu ọhun, ko to o di pe ijọba fi opin si tita rẹ lọdun 2019.
Awọn eeyan mẹtẹẹta kọ iwe ẹsun si ile ẹjọ nitori pe "ijọba ko ṣe ayẹwo lati mọ boya kọndọmu naa poju owo, ki wọn o to bẹrẹ si ni ta fun ara ilu".
Wọn si n fẹ ki ijọba fi ofin de kiko kọndọmu naa wọ Uganda, tabi ta a.
Ajọ Marie Stoppes ma n ta to miliọnu meji kọndọmu l'oṣooṣu ni orilẹ-ede naa.
Ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2019, kọndọmu to to miliọnu kan niye, ni ijọba gbẹsẹ le, lẹyin ti awuyewuye bẹrẹ si waye lori rẹ lati ọdọ awọn ara ilu.
Ṣugbọn, ẹpa ko boro mọ, nitori pe awọn eeyan kan ti n lo o.