You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Omohtee Twitter: Ìrora púpọ̀ ni mo là kọjá lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ tí mo ṣe láti jẹ́ kí ìdí mi tóbi sii - Omotola Taiwo
Omotola Taiwo, ti ọpọ eeyan mọ si "Omohtee" ti ṣalaye ohun toju rẹ ri lẹyin iṣẹ abẹ to ṣe ni ọdọ Dokita Anu, lọna ati jẹ ibadi rẹ tobi sii.
Omohtee tu pẹrẹpẹrẹ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC pe oun kabamọ igbeṣẹ naa, koda, o ni diẹ lo ku ki oun gba ẹmi ara oun.
Ẹni ọdun mejidinlọgbọn ọhun to jẹ oniṣowo aṣọ sọ pe, oriṣirṣi eetu lo n jade ni idi oun ati irora ti ko ṣe fẹnusọ lẹyin iṣẹ abẹ naa.
Oṣu kinni ọdu 2020 ni Omohtee ṣe iṣẹ abẹ kanti wọn n pe ni 'Liposuction' ti yoo jẹ ki ikun rẹ pẹlẹbẹ, bẹ lo tun fa ọra ikun rẹ, to si jan mọ idi rẹ ki idi ọhun lee tobi si.
Omohtee ti fẹsun kan dokita to ṣe iṣẹ abẹ naa, dokia Anu fun iṣẹ ajabanku to ṣe si oun lara.
Ṣugbọn dokita Anu ti pee lẹjọ fun ibanilorukọjẹ, to si n bere fun owo itanran miliọnu marundinlọgbọn naira.
Nigba to n sọ tẹnu rẹ fun BBC, dokita Anu ni oun kọṣe mọṣẹ, ati pe oun gba iwe ẹri to dantọ.
Anu tun sọ pe iṣe Omohtee kọ ni akọja ewe oun, nitori oun ti ṣe awọn iṣe mii to lami laaka to bi ẹgbẹrun kan ṣaaju iṣẹ rẹ.
Dokita ọhun pari ọrọ rẹ pe awuyewuye iṣẹ Omohtee ti mu ki oun padanu iye owo to le ni ọgọrun un miliọnu naira, yatọ si pe ijọba ti gbe ile iwosan oun ti.
Dr Anu: Ìjọba àpapọ̀ ti mú obìnrin tí àwọn èèyàn fi ẹ̀sùn kàn pé ayédèrú ìdí ló n ṣe
Ijọba Naijiria ti fi ofin gbe dokita kan, Anu Fela (Medcontour), wọn si ti gbe e lọ si ile ẹjọ giga ijọba apapọ ni Ikoyi nilu Eko.
Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrin, oṣu Keje, ni ajọ to n daabo bo ẹtọ oníbàràá ni Naijiria, FCCPC, kede pe oun ti mu Anu, to ni ileewosan Medcontour.
Iṣẹ abẹ idi ati ọyàn ni Dokita naa ma n ṣe. Awọn onimọ iṣegun maa n pe iru iṣẹ naa ni Cosmetic Surgery.
Wọn ni kò fọwọsowọpọ pẹlu wọn lori iwadii ẹsun ti wọn fi kan an pe ọna ti ko tọ ọ lo n gba ṣiṣẹ abẹ.
Ọpọlọpọ igba ni awọn eeyan ti pariwo Dokita Anu, ati ileeṣẹ rẹ lori ayelujara lati bi ọdun meji sẹyin.
Ẹsun ti wọn fi n kan an ni pe, iṣẹkiṣẹ lo ṣe si ọyàn ati ìdí ti awọn ni ko ba wọn tun ṣe.
Wọn ni niṣe ni ìdí tabi ọyàn awọn burẹwa si, tabi ko di ọgbẹ adaajina.
Ọkan lara awọn oníbàràá rẹ, lo pariwo sita lori ayelujara l'oṣu Kẹrin pe, iṣẹ abẹ ti Anu ṣe si idi oun ti da aisan si oun lara.
Gbogbo igba si ni Dokita Anu ma n sẹ lori awọn ẹsun naa.
Lọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹrin, ni awọn alaṣẹ ti ọfiisi Medcontour pa nilu Eko, lori ẹsun pe oun ṣe iṣẹ ti ko ba ofin mu.
Ninu iroyin ti ajọ FCCPC fi sita lọjọ Ẹti, wọn ni awọn fi ofin mu Dokita Anu, nitori pe ko tẹle awọn ilana ti ajọ naa la kalẹ fun iwadii ẹsun naa.
Ọga ajọ FCCPC, Babatunde Irukera, ti oun fun'ra rẹ jẹ amofin, ni yoo jẹ olori igbimọ ti yoo rojọ tako.
Ojoojumọ ni iye eeyan to n ṣe iṣẹ abẹ ọyan ati idi n pọ si ni Naijiria.