Ilé ẹjọ́ wọ́gilé ìgbẹ́jọ́ Olalekan 'Woodberry' Pọnle

Woodberry: Ile ẹjọ wogile igbẹjọ Olalekan 'Woodberry' Ponle.

Olalekan Jacob Ponle ti gbogbo eniyan mọ si Woodberry to jẹ ọkan lara awọn gbajuẹ ori ayelujara ti awọn ọlọpaa Dubai mu tẹlẹ pẹlu Ramoni Abass Hushpuppi.

Ile ẹjọ ilẹ Amẹrika ti da ẹjọ ti wọn pe lodi si ọmọ Naijiria naa, Olalekan Ponle ti gbogbo eniyan mọ si Woodberry ti awọn ọlọpaa Dubai mu fun iwa gbajuẹ ori ayélujára nu.

Gẹgẹ bi iwe iroyin abẹle Premium Times ṣe sọ, ile ẹjọ ilẹ Amẹrika ni awọn ko ni ẹsun kankan lodi si Woodberry

Ọlọpaa mu Ponle ati Ramon Abbas ti gbogbo eniyan mọ si Hushpuppi ni Dubai ni ọjọ kẹwaa, oṣu keje, ọdun 2020.

Lẹyin naa ni wọn ko wọn lọ si ilẹ Amẹrika fun igbẹjọ lori ẹsun iwa 419 ori ayelujara ti awọn Naijiria maa n pe ni Yahoo-Yahoo.

Awọn iwe iwadii kan to tẹ BBC lọwọ naa fidi rẹ mulẹ pe Adajọ Robert W. Gettleman lọjọ Iṣẹgun paṣẹ pe ki wọn wọgile igbẹjọ naa.

Nkan to waye yii kii ṣe ajoji ni ilẹ Amẹrika labẹ ofin iwa ọdaran, ilana 48 maa n faaye gba ijọba da ipẹjọ ti wọn ti kọkọ pe fun eniyan tẹlẹ nu.

Sugbọn, eyi ko tumọ si pe Woodberry ti bọ patapata nitori wọn le fi ẹsun miran kan an.

Kini ẹjọ Woodberry ti wọn danu yii tumọ sí?

Gẹgẹ bi alaye to wa ninu iwe to tẹ BBC lọwọ lati ọwọ agbẹjọrọ orile-ede Naijiria kan, Adetokunbọ Eribake Esq, ọrọ ile ẹjọ yii le tumọ si nkan meji:

O ni: 'O le tumọ si pe awọn iha mejeeji n sọrọ lori bi wọn o ṣe yanju ẹjọ naa lai lọ ile ẹjọ, ki ijọba si wọgile ṣiṣe ẹjọ pẹlu Woodberry.

Tabi

Ki o jẹ pe awọn aṣiri ọrọ miran ti tu sita, ti o si nilo ki wọn wọgile ẹjọ akọkọ lati pe ẹjọ tuntun lodi si Woodberry.

Ẹwẹ, koko to wa nibẹ ni pe ijọba wọgile ipẹjọ lodi si Woodberry lai ni ẹta inu, tumọ si pe, ijọba ni ẹsun tuntun ti wọn yoo fi kan an, eyi ni alaye Eribake.

Hushpuppi Ramoni Abass gangan n wa n kọ?

Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ Federal Bureau of Prison (BOP), Ramon 'Hushpuppi' Abbas ko si ni ọgba ẹwọn Chicago ti wọn fi si tẹlẹ mọ.

Ẹwẹ, agbẹjọro Hushpuppi, GalPisseyzky sọ fun awọn akọroyin abẹlẹ pe wọn kan gbe onibara oun kuro ni ọgba ẹwọn Chicago lọ si ti Califonia ni, kii ṣe pe o ti kuro lẹwọn.

Ṣé lóòtọ́ ni pé Hushpuppi ti kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n l'America? Ẹ wo àbájáde ìwádìí wa

Iléeṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n ìlú Chicago sọ pé Hushpuppi kò sí ní ẹ̀wọ̀n MCC ní Chicago mọ́.

Lootọ ni akọsilẹ wa lori itakun agbaye ajọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ilẹ America, FBI, pe wọn ti tu ọmọ orilẹ-ede Naijiria, Hushpuppi ti wọn mu fun ẹsun jibiti, silẹ.

Ṣugbọn akọsilẹ ti BBC ri arigbamu rẹ lori itakun agbaye ajọ ọgba ẹwọn nilẹ America, fihan pe Hushpuppi ko si ni ọgba ẹwọn ilu Chicago mọ, koda ogunjọ, oṣu Keje, ni wọn ti tu u silẹ.

Amọ o, agbẹjọro fun Hushpuppi, Gal Pissetzky, sọ fun awọn akọroyin nilẹ America pe ko ti i gba itusilẹ, wọn kan gbe e kuro ni ọgba ẹwọn Chicago, lọ si ti California.

Pissetzky, to jẹ agbẹjọro nilu Chicago, sọ fun awọn oniroyin pe, wọn ko ti i yọnda rẹ, ati pe oun ṣi ni agbẹjọro rẹ, tako iroyin kan to sọ pe Hushpuppi ti kọ ọ ni agbẹjọro.

"Pe wọn kọ ọ si ori iwe pe wọn ti tu u silẹ, ko tumọ si pe o ti di ominira. Gbogob nkan ti ẹ ba ri lori iwe ile ẹjọ kọ lo maa n jẹ 'otitọ' delẹ.

Ọsẹ diẹ sẹyin ni ọmọ Naijiria naa, ti ilẹ Amẹrika fi ẹsun ṣiṣe jibiti lori ayelujara kan, Ramon Igbalode, ti inagijẹ rẹ n jẹ Hushpuppi yọju sile ẹjọ lonii.

Amọ adajọ to n gbọ ẹjọ naa, Jeffrey Gilbert, ẹni to wo igbẹjọ naa lati ori ayelujara ni Chicago kọ lati gba oniduro Hushpuppi.

Alaye adajọ naa ni pe o lewu lati gba oniduru afurasi alujibiti ọhun nitori pe o le e fi ẹsẹ fẹ, ki wọn ma ri mọ.

Adajọ Gilbert wa paṣẹ pe ki Hushpuppi si maa naju lọ lọgba ẹwọn na, titi ti wọn yoo fi fi oju rẹ ba ile ẹjọ fun igbẹjọ to yẹ, eyi ti yoo bẹrẹ ni California, ki ọdun yii to pari.

Awijare agbẹjọro Hushpuppi, Pissetzky:

Bi o tilẹ jẹ pe agbẹjọro Hushpuppi, Gal Pissetzky si n tẹnumọ pe ki wọn gba oniduro Hushpuppi, sibẹ ẹbẹ rẹ ko wọle leti adajọ.

Pissetzky n rọ adajọ pe ko gba beeli onibara oun, ko si fun laaye lati maa gbe pẹlu ibatan rẹ kan to ni iyawo ati ọmọ, ti wọn yoo si maa tọpinpin rẹ.

Agbẹjọro naa ni "Ẹni ti gbogbo eeyan nifẹ si, ti wọn si n bọwọ fun ni onibara oun, gbajumọ eeyan ni."

Ṣugbọn ikọ olupejọ ni Amẹrika faake kọri lati gba ẹbẹ agbẹjọro naa pẹlu awijare pe Hushpuppi le salọ, ko si tun lọ lu jibiti miran lori ayelujara.

FBI jí Hushpuppi gbé ní Dubai ni- Agbẹ́jọ́rọ̀ Ramọni Igbalode

Gal Pissetzky to n ṣoju fun Ramoni Abass Igbalode ba BBC sọrọ lori ohun to n ṣelẹ bayii lori ọrọ Hushpuppi.

Loṣu kẹfa ni awọn agbofinro mu Ramoni Olorunwa Abbas lori ẹsun lilu jibiti lori ayelujara. ni orilẹ-ede Dubai.

Awọn ọlọpaa Dubai ni wọn ba ogoji miliọnu dọla, ọkọ bọginni mẹtala to to miliọnu meje dọla din ni igba, kọmputa mọkanlelogun, foonu mẹtadinlaadọta ati awọn nkan mii mọ Hushpuppi lọwọ.

Ile ẹjọ ni Chicago lo ti kọkọ foju han lọjọ kẹta, oṣu kejila lori ẹsun gabjuẹ.

Gal ni oun ko fi bẹẹ mọ nipa ayelujara asiko yii ṣugbọn oun mọ pe wọn n pa owo to pọ lori ayelujara nitori pe awọn ọmọ oun ni oun ti dagba.

O ni Hushpuppi ni awọn ero to le ni miliọnu to pọ to n tẹle lori ayleujara ni eyi to n pa owo wọle fun un.

Agbẹjọro Pissetzky ni awọn FBI ji Ramoni gbe ni Dubai ni lai tẹlẹ awọn ofin ati ilana to yẹ ni kikun ki wọn to maa gbee bọ ni America.

O ni awọn ọdọ pọ lori ayelujara ti wọn nifẹ Ramoni, ti wọn si bọwọ fun un.

Àlàyé rèé lórí bí agbẹjọ́rò tó ń ṣojú Hushpuppi nílé ẹjọ́ ṣe pegedé sí

Ẹ wo àwọn àmúyẹ ti gbajúmọ̀ agbẹjọ́rò tó fẹ́ ṣojú Hushpuppi nile ẹjọ ní

Onileeṣẹ adani ni Hushpuppi, ọmọ Naijriia ti wọn fi si ọgba ẹwọn nilẹ Amẹrika, nitori ẹsun jibiti.

Agbẹjọro Hush, Gal Pissetzky, lo sọ bẹẹ fun iwe iroyin Forbes, lasiko ifọrọwanilẹnuwo kan.

Ọgba ẹwọn ijọba apapọ nilu Chicago, ni Illinois, lorilẹ-ede Amẹrika ni Ramoni Igbalode, wa lọwọlọwọ.

Gbajugbaja ni agbẹjọro rẹ yii, nitori pe o ti ṣoju gbajugbaja akọrin to ti di oloogbe, Michael Jackson ri ninu igbẹjọ kan.

Awọn nkan ti a mọ nipa igbeaye Gal Pissetzky

Gal Pissetzky ti n ṣiṣẹ amofin fun ogun ọdun.

Lati ibẹrẹ pẹpẹ iṣẹ rẹ lo ti nifẹ lati maa gbẹjọro fun awọn ti ijọba apapọ tabi ipinlẹ ba fi ẹsun iwa ọdaran kan.

Ọgbẹni Pissetzky ti gbẹjọro bi igba ọgọrun, niwaju igbimọ igbẹjọ ati adajọ.

Ọpọlọpọ ẹjọ to ta koko ni Pissetzky ti gba ro nile ẹjọ to gaju lọ nipinlẹ Illinois, ati ile ẹjọ kotẹmilọrun ijọba apapọ.

Awọn ti agbẹjọro yii ṣaba maa n ṣoju ni awọn ti wọn ba fi ẹsun jibiti owo, jibiti ori ayelujara ati iwa ibajẹ nidi oṣelu.

Awọn ẹsun miran to tun maa n soju fun ni lilu jibiti l'ẹka eto ilera, iditẹ, ipaniyan, rira ati tita oogun oloro, ifipabanilopọ, ati awọn ẹsun miran to l'agbara.

Ilu Chicago ni ọfiisi Gal Pissetzky wa, ṣugbọn jakejado orilẹ-ede Amẹrika lo ti maa n ṣoju awọn onibaara rẹ.

Awọn ede ti Gal Pissetzky gbọ

Hebrew

Polish

Spanish

Awọn ibi ti Gal Pissetzky ti ṣiṣẹ ri

Pissetzky & Berliner, LLC (2006 si asiko yii)

Meczyk & Associates (2002 - 2006)

Cook County State's Attorney's Office (2000 - 2002)

Awọn ileewe ti Gal Pissetzky lọ

J.D., John Marshal Law School, Chicago (Law, 2000)

B.A., University of Illinois, Chicago (Criminal Law and Political Science, 1997)

Awọn ami ẹyẹ to ti gba

Rising Star Super Lawyer™, 2011

Top 100 Trial Lawyers Association of Trial Lawyers of America, 2010

Top 100 Trial Lawyers Association of Trial Lawyers of America, 2009

Top 100 Trial Lawyers American Trial Lawyers Association, 2007

Cum Laude John Marshall Law School, 2000

Honors University of Illinois, Chicago, 1997

"10 Best Client Satisfaction" attorneys by the American Institute of Criminal Law Attorneys

"Top 100 Trial Lawyers: Illinois" by The American Trial Lawyers Association

O si ṣeeṣe k Ramoni Abbas Olorunwa, ko ṣe to ogun ọdun l'ọgba ẹwọn, ti ile ẹjọ ba fi sọ pe o jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an.