You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ló fa ìjà láàrín ìlú mẹ́ta tó ń jà sí odò Nile?
Ohun to n fa sababii gbọnmi si i omi o to o laarin awọn orilẹ-ede Afirika kan lorii odo Nile ni ẹni ti yoo maa ṣakoso lori odo yii to gun ju ni gbogbo ilẹ Afirika.
Orilẹ-ede mẹta ni Afirika, Ethiopia, Sudan ati Egypt ti fẹnuko bayii lati bẹrẹ ijiroro. lori rẹ lẹyin ti wọn ti baba ṣepade ori ayelujara.
Koko ija to n waye laarin Ethiopia ati Egypt da lori ọjọ iwaju ti odo yii to jẹ ibudo akanṣe iṣẹ ipese agbara eyi to bẹrẹ lọdun 2011.
- Lizzy Anjorin sun ẹkún ìyàwó, èèyàn kan fún un lẹ́bùn aṣọ funfun láti mọ ìbálé rẹ̀
- Pásítọ̀ ìjọ Sotitobire padà yọjú sílé ẹjọ́ lónìí, àbọ̀o rèé...
- Wo àwọn ọ̀nà míràn tí o leè gbà lẹ́yìn tí wọ́n bá ti afára Third Mainland
- Kí ló pa Bobrisky àti Olorì Aláàfin Oyo pọ̀?
- Wo àwọn òṣìṣẹ́ kólẹ̀-kódọ̀tí tó ń fi ẹ̀mí wọn wéwu kí Abuja leè mọ́ tónítóní
Ethiopia ni ireti pe odo naa yoo le pese ina fun miliọnu mẹwaa eeyan to n gbe lai ni anfani ina lorilẹ-ede wọn.
Sugbọn ni ti Egypt to jẹ pe ọpọ omi amọlolo ti wọn n o, odo Nile ni wọn ti n ri i, wọn n poruru ọkan pe igbesẹ naa yoo mu wahala ba ipese omi fun orilẹ-ede ti wọn.
Nigba ti wọn ba pari iṣẹ adagun odo nla eyi ti Ethiopia n kọ, ohun ni yoo jẹ ibudo amunawa to tobi ju ni Afirika.
Adagun odo nla yii ti fa ọbitibiti wahala laarin orilẹ-ede Egypt ati Ethiopia,
Yoruba si bọ wọn ni bi erin meji ba n ja, koriko abẹ wọn a jiya - orilẹ-ede Sudan wa laarin awọn mejeji yii
Bẹẹ si ni awọn kan n bẹru pe o lee yọri si ogun bakan naa lorilẹ-ede Amẹrika ti n kẹnu bọ ọrọ naa.
- Wọ́n fẹ̀sùn kan igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo lórí ayédèrú ìwé ìdìbò níbi ìdìbò abẹ́lé PDP tó ń lọ lọ́wọ́
- Ikú ti yọ́wọ́ òṣèré Nollywood Yorùbá, Yusuf Satia l'áwo
- Gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti, Kayode Fayemi nàá ti ni aàrùn Coronavirus
- Kí ló dé tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo kéde fífagilé Sáà ètò ẹ̀kọ́ kẹta fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́?
- Wo àwọn nkan tó yẹ́ kí o mọ̀ nípa 'Awawa Boys', ọ̀kan lára ẹgbẹ́ òkùnkùn tó n dá Eko rú
Ki lo fa ija gangan?
Lara ohun to n fa ija ni ọna ti wọn yoo gba lati di inu adagun odo naa ẹru si n ba orilẹ-ede Egypt pe akanṣe iṣẹ yii lee faaye gba ki Ethiopia maa dari odo yii to gun ju nilẹ Adulawọ.
Ọdun mẹfa ni orilẹ-ede Ethiopia fẹ fi ṣe iṣẹ naa.
"A ti ni alakalẹ ati aato lati bẹrẹ didi adagun odo yii tori asiko ojo to n bọ a o si bẹrẹ si ni loo lati pese ina ninu oṣu kejila ọdun 2020".
Minisita to n ri si ọrọ omi ni Ethiopia, Seleshi Bekele lo sọ eyi ninu oṣu kẹsan ọdun to kọja.
- Àwọn aṣekúpani tún ti pa ọmọ ọdún 16 ní Akinyele nípìnlẹ̀ Oyo
- 'Coronavirus ló mú mi fẹ́ ọkọ mi tí a sì ṣèyàwó lóríi ‘Zoom’
- A yìnbọn lu Precious láti dáa dúró ni, akò mọ̀ pé o máa kú- Ọlọ́pàá
- Èèyàn 576 míràn tún kún àwọn tó ní àrùn COVID-19 ní Nàìjíríà
- Adarí àjọ NDDC, Pondei ṣetán láti sọ ohun tó mọ̀ nípa ìwàdíì tó bá ti gbádùn- NDDC
Ẹwẹ, orilẹ-ede Egypt ti n gbero asiko ti yoo pẹ fun iṣẹ naa tori ki ipele omi naa ma sare wọlẹ paapaa ni ipele akọkọ ti wọn ba n di i.
Lati bii ọdun mẹrin bayii, ina ko tii wọ laarin Sudan ati Ethiopia lorii bi wọn yoo ṣe maa ṣakoso adagun odo naa.
Aarẹ Epypt, Abdul Fattah al-Sisi sọ ninu oṣu kẹsan ọdun to kọja pe bii kii ba ṣe wahala oṣelu to ṣẹlẹ lorilẹ-ede oun ni, Ethiopia ko ba ma lee bẹrẹ iṣẹ ọhun rara.
- Bí ẹgbẹ́ One Million Boys ṣe bẹ̀rẹ̀ rèé àti ọṣẹ́ tó ṣe n'Ibadan
- Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Laycon, akẹ́kọ̀ọ́jáde UNILAG tó ń kópa nínú BBNaija 2020
- Ohun tí o kò mọ̀ nípa Ebila "One Million Boys" àti Ekugbemi, olórí ẹgbẹ́ òkùnkùn méjì tó da ìlú Ibadan rú
- Ọkùnrin kan pa ara rẹ̀ sínú ọgbà àjọ TRACE tó n mójútọ ìrìnnà ọkọ̀ nípìnlẹ̀ Ogun
Ethiopia n fẹ ki wọn so odo naa pọ mọ adagun odo Aswam, Egypt ni lae lae.
Idi ti Ethiopia ṣaa fi fẹ adagun odo yii?
- O jẹ ọkan pataki ninu ala wọn.
- Iṣoro aisi ina pẹlu bi wọn ṣe pọ to
- Ina ti wọn yoo ri latara rẹ lee to gbogbo araalu wọn ti yoo tun ṣẹku lati ta fun awọn orilẹede agbegbe.
Njẹ awọn orilẹ-ede mii yo janfani nibẹ?
Bẹẹ ni. Awọn orilẹ-ede to sun mọ wọn bii Sudan, South Sudan, Kenya, Djibouthi ati Eritrea ṣeeṣe ki wọn jẹ anfani tori ọpọlọpọ wọn ni ko gbadun ina.
Pabanbari ni wi pe bi ọrọ yi ba lee fa ogun, yoo ba okun ajọṣepọ katakara jẹ laarin awọn orilẹ-ede agbaye eyi ti Afirika fi so wọn pọ gẹgẹ bi ileewe giga Washington Institute ṣe sọ ọ.
Wọn kò fẹnu ọ̀rọ̀ jóná lórí ohun tó ń kọ Egypt àti Sudan lóminú níbi ìpàdé ọjọ́ Ajé
Minisita fun ọrọ ohun alumọọni inu omi ati ohun amusagbara lorile-ede Ethiopia, Sileshi Bekele, ti kede lori redio ati tẹlifisan orilẹede naa, EBC pe awọn ti n fa omi sinu ibudo iṣe omi lọjọ si, ti wọn kọ si ẹba odo Nile.
Ikede Ọgbẹni Sileshi yii si lo fidi ootọ nipa awọn aworan to jade mulẹ, eyi to ṣe afihan pe odiwọn omi inu ibudo ìṣe omi lọjọ si naa n lọ soke, eyi to n pa lati inu adagun odo.Adagun odo ti wọn fi biliọnu marun-un dọla kọ naa lo n fa aawọ laarin orilẹ ede Ethiopia, Egypt ati Sudan.
Bẹẹ si ni gbogbo ijiroro to waye lọjọ Aje lati yanju aawọ naa lo ja si pabo, ti wọn ko si fẹnu ọrọ jona lori awọn koko ọrọ kan ti orilẹ-ede Egypt ati Sudan n kọminu le lori.Awọn aworan tuntun ti wọn ya lati ori itakun agbaye laarin ọjọ kẹtadinlọgbọn osu kẹfa si ọjọ Kejila osu keje ọdun 2020, lo ṣe afihan bi agbega ṣe n ba odiwọn omi ti adagun odo naa n fa ọwọ rẹ sẹyin.
- Ọmọ Ààrẹ lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ìgbéyàwó yálà àwọn ará ìlú fẹ́ràn ìjọba bàbá rẹ̀ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ - Aisha Buhari
- Ọkùnrin tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó jí ǹkan nílé ìjọsìn rí ẹ̀wọ̀n he!
- 'Mo mọ̀ọ́mọ̀ sin ọmọ-ọmọ mi, ìkókó jòjòló láàyè ni, nítorí wọ́n fipá bá ọmọbìnrin mi lòpọ̀ ló fi lóyún rẹ̀'!
- Obìnrin bíi Ruth Bader ni yóò gba ipò rẹ́ ní iléẹjọ́ tó gajùlọ nílẹ̀ Amerika- Donald Trump
- Ilé ìjọsìn lè bẹ̀rẹ̀ ìsìn àárín ọ̀sẹ̀ padà, Mọ́sáláṣí àti Ṣọ́ọ̀ṣì lé gba iye èèyàn tó wù wọ́n ṣùgbọ́n...