Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ afurasí ọlọ́pàá tó yìnbọn fún ọ̀dọ́kùnrin tó fún èèyàn lóyún s'átìmọ́lé

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers ti ju afurasi ọlọpaa kan to yinbọn fun ọdọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogun, Ledisi Kote lẹsẹ lori ẹsun pe o fun ọmọdebinrin kan loyun.

Ni ijọba ibilẹ Gokana nipinlẹ Rivers ni iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Nnamdi Omoni lo fidi ọrọ naa mulẹ fawọn akọroyin.

Omoni ṣalaye pe ileeṣẹ ọlọpaa ti gba ibọn lọwọ ọlọpaa naa, o si ti wa lahamọ ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ṣewadii awọn ọdaran.

O fi kun ọrọ rẹ pe ọdọkunrin to yinbọn fun lẹsẹ naa wa nile iwosan nibi to ti n gba itọju.

Omoni sọ pe ni bi aago meje aarọ ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹjọ ni ọlọpaa yii ṣadeedee lọ si ile awọn Kote nibi to ti sọ wi pe oun fẹ ri i.

Ọlọpaa yii wọ inu yara Ledisi lọ fun ra rẹ lẹyin ti awọn ẹbi rẹ ko fẹ fi oju rẹ han.

Lẹyin to wọ ọdọkunrin yii sita tan lo dabọn bo o lẹsẹ.