You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
US Supreme Court: Donald Trump ní obìnrin bíi Ruth Bader ni yóò gba ipò rẹ́ ní iléẹjọ́ tó gajùlọ nílẹ̀ Amerika
Aarẹ orilẹede Amerika, Donald Trump ti ni oun yoo fi orukọ obinrin silẹ gẹgẹ bi ẹni ti yoo rọpọ adajọ agba, Ruth Bader Ginsburg ni ileẹjọ to gajulọ ni ilẹ Amerika.
Ọjọ Kọkandinlogun, Oṣu Kẹsan an, ọdun 2020 ni Ginsburg papoda ni ẹni ọdun mẹtadinlaadọrun lẹyin ti aisan jẹjẹrẹ ba a fin ra.
Aarẹ Trump kede ọrọ yii lasiko to n ba ẹbi ati ara kẹdun iku akọni obinrin naa.
Amọ ọrọ aarẹ Trump yii ti da yanpọn-yanrin silẹ nitori Ile Igbimọ Asofin lorilẹede naa ni yoo dibo yan ẹni ti yoo rọpọ rẹ lẹyin ti aarẹ ba ti fi orukọ silẹ.
Aarẹ orilẹede Amẹrika naa ni ọsẹ to n bọ ni oun yoo kede orukọ eni naa lai fa ọrọ gun rara.
Amọ awọn ẹgbẹ Democrats ti yari pe igbesẹ ti aarẹ Trump n gbe naa n jẹ ọna lati mu ki awọn adajọ ọmọ ẹgbẹ Republican pọjulọ ni ileẹjọ to gajulọ ni orilẹede Amerika.
Labẹ ofin ilẹ Amẹrika awọn adajọ ileẹjọ to gajulọ lorilẹede naa gbọdọ pe mẹsan an lati dajọ lori abadofin to ba pọn dandan ni orilẹede naa.
Amọ, ọmọ-ọmọ Ginsburg ni ifẹ iya oun ki o to papoda ni ki aarẹ miran jẹ lorilẹede Amerika ki wọn to yan adajọ miran ti yoo rọpọ oun.