Babajide Sanwo-Olu: Ìjọba ní Gómìnà Eko kò ní ṣ'àyẹ̀wò covid-19 míì

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Kọmiṣọnna eto iroyin nipinlẹ Eko, Gbenga Omotosho ti sọ pe iti ọgẹdẹ ti ko to ohun ti aa yọ ada si ni ọrọ kọmiṣọnna eto ilera, Ọjọgbọn Akin Abayomi to lugbadi coronavirus jẹ fun Gomina Babajide Sanwo-Olu.

Ọgbẹni Omotosho ni oun ko ro pe Gomina Sanwo-Olu yoo lọ fun ayẹwo coronavirus miiran nitori Ọjọgbọn Abayomi ṣẹṣẹ lugbadi aarun ọhun.

Omotosho ni "ọrọ naa ko kọ Sanwo-Olu lominu, nitori kii ṣee igba akọkọ ree ti alabaṣiṣẹpọ pẹlu rẹ yoo kaarun coronavirus."

"Kọmiṣọnna eto ilera to ni coronavirus kii ṣe tuntun, ni kopẹ kopẹ yii lawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ìjọba ipinlẹ Eko mẹwaa ko coronavirus," Ọgbẹni Omotosho lo woye bẹẹ

Lọjọ Aje ni kọmiṣọnna eto iroyin kede ninu atẹjade kan to fi sita pe Ọjọgbọn Abayomi ti lugbadi aarun covid-19.

O sọ ninu atẹjade naa pe Ọjọgbọn Abayomi lugbadi aarun naa lẹyin ifarakinra pẹlu awọn to ti laarun ọhun.

Ẹwẹ, kọmiṣọnna eto ilera fun ra rẹ sọ loju opo Twitter rẹ pe o da oun loju pe oun yoo jajabọ lọwọ coronavirus laipẹ.

Kọmísọ́nà ètò ìlera ìpińlẹ̀ Eko ọjọ̀gbọ́n Akin Abayomilùgbàdì ààrùn Covid-19

Kọmísọ́nà ètò ìlera ní ìpińlẹ̀ Eko, ọ̀jọ̀gbọ́n Akin Abayomi ti lugbàdì ààrún.

Kọmísọ́nà ètò ìròyìn àti ọ̀rọ̀ tó n lọ ní ìpínlẹ̀ Eko Gbenga Omotoso lo fi ọ̀rọ̀ náà léde nínú àtẹ̀jáde kan lójú òpó twitter rẹ̀.

Ó ni lẹ́yín ti ọ̀jọ̀gbọ́n Abayomi ni ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ẹni kan ti ara rẹ̀ kò yá, to si ṣe àyẹ̀wò ààrùn Covid-19 lo ri pé, òun pẹ̀lú ti lùgbàdì ààrùn náà.

"Kọmísọ̀nà mọ ìpò Covid-19 rẹ̀ lẹ́yìn àyẹ̀wò olóòrèkóòrè ti wọ́n máa ń ṣe, ní báyiì, o ti n gba ìtọ́jú, kò si fi àmì hàn"

Lagos Coronavirus :Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ní àwọn ń ná tó N1million lórí aláàrùn Coronavirus kọ̀ọ̀kan

Ijọba ipinlẹ Eko ti ni o kere tan miliọnu kan naira ni awọn n na lojumọ lori ẹni kọọkan ti arun Coronavirus pa peleke lara wọn.

Kọmisọnna fun eto ilera nipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Akin Abayomi lo sọ ọrọ yii lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ nipinlẹ Eko.

Abayomi ni o ti lẹ ni ẹgbẹrun mẹrinla eniyan to ti lugbadi arun Coronavirus ni ipinlẹ Eko nikan.

O fikun un pe o kere tan awọn n na N100,000 to jẹ ẹgbẹrun lọna ọgọrun un naira lori awọn ti arun naa ko ba peleke ni ara wọn, amọ ti wọn ṣi n gba itọju.

Bayii, Gbenga Omotoṣo to jẹ kọmiṣọnna fun ifitonileti ti jade wa ṣalaye ohun ti ijọba ipinlẹ Eko n sọ lori bi wọn ṣe n na miliọnu kan lojumọ fun ẹni to ni Covid 19.

O ni iṣẹlẹ Coronavirus kọọkan yatọ sira wọn ati pe eto inawo itọju wọn yatọ si ara wọn.

O sọ iye ti ijọba ipinlẹ Eko n na lori ọkọọkan iṣẹlẹ coronavirus ti wọn ti tọju niyara iyasọtọ ati nile iwosan.

O ni awọn a maa na ẹgbẹrun lọna ọgọrun un kan si ẹẹdẹgbeta ẹgbẹrun si miliọnu kan naira lori alaisan kọọkan ni eyi to ni i ṣe pẹlu bi Covid 19 ba ti ṣe ṣọṣẹ to lara alaisan bẹẹ.

Kọmiṣọnna eto ifitonileti fun Sanwo Olu tun ṣalaye pe: '' Awọn ti wọn ba ni arun Coronavirus, amọ ti ko gboro lara wọn, ijọba n na o kere tan N100,000 lori wọn lojumọ,

Amọ fun awọn ti arun Coronavirus ti peleke ni ara wọn, o kere tan ijọba n na miliọnu kan naira lori wọn ni ojumọ.

Bi a ṣe n tọju alaisan kọọkan yatọ si ara wọn, bẹẹ si ni iye owo ti a n na lori wọn yatọ si ara wọn.''

Kọmisọnna fun eto ilera nipinlẹ Eko naa fikun un pe awọn n ṣiṣẹ pọ lati ri pe awọn mọ iye oju owo ti awọn n na lori awọn alaisan Coronavirus, ti awọn a si fi n ṣọwọ si awọn akọroyin.

Nibayii, O ti le ni eniyan ọgọsan to ti ku nitori aarun Coronavirus ni ipinlẹ Eko nikan ṣoṣo.

O ni ki awọn eeyan maa fi ara balẹ gbe ọrọ kalẹ nitori gbogbo bi awọn ṣe n nawo ni akọsilẹ wa fun.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti, Kayode Fayemi nàá ti ni aàrùn Coronavirus

Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi ti kede pe oun ti ni aarun coronavirus.

Gomina fi sita loju opo Twitter rẹ lowurọ Ọjọbọ.

Fayemi sọ pe ọjọ Iṣẹgun ni oun ṣe ayẹwo ilera kẹta, ti esi rẹ fihan pe oun ti ni coronavirus.

Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe oun ti n gba itọju to peye, nibi ti oun ti ya ara oun sọtọ.

Ko tan sibẹ, gomina Fayemi sọ pe oun ti gbe gbe agbara wọ igbakeji oun lati ma a ba iṣakoso lọ lori awọn igbesẹ to ṣe koko, ti oun yoo si maa ṣe iṣẹ diẹdiẹ lati ile.

Fayemi kọ ni alaṣẹ ijọba ti yoo kọkọ ni Covid-19 ni Naijiria.

Awọn bi gomina ipinlẹ Oyo, Delta, Ondo, Bauchi, Kaduna, naa ti ni aarun naa.

Koda, o ti ṣe ku pa awọn kan gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ, Abiola Ajimobi, ati olori awọn oṣiṣẹ fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Abba Kyari.