Ajimobi Burial: Ẹbí Abiola Ajimobi kéde bí ètò ìsìnkú rẹ̀ yóò ṣe rí pé...

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Abiola Ajimobi Central Mosque ni Oke Ado ni ilu Ibadan ni ipinlẹ Oyo ni ile ijọsin kẹyin ti ara Abiola Ajimobi yoo wọ gbẹyin.

Ogbẹni Bolaji Tunji to jẹ oluranlọwọ pataki fun oloogbe Ajimọbi lori eto iroyin nigba aye rẹ lo ṣalaye bi eto isinku naa yoo ṣe waye lorukọ mọlẹbi Ajimọbi.

O ni lẹyin ifikunlukun pẹlu ijọba ipinlẹ Eko ati ti ipinlẹ Oyo lori ọna lati sin oloogbe Ajimọbi bi o ti tọ ati bi o ti yẹ ni wọn fẹnuko lori ọna ti wọn fẹ gba yii.

Aago mejila ọsan ọjọ Aiku, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹfa, ọdun 2020 ni eto isinku Sẹnetọ Abiola Ajimobi yoo waye.

Wọn yoo ṣeto ilana isinku naa pẹlu ilakalẹ to yẹ pẹlu bi gbogbo agbaye ṣe n koju ajakalẹ arun Coronavirus ni.

Ọgbẹni Bolaji tun ṣalaye pe ilana ẹsin Islam ni wọn yoo fi sin Ajimọbi ti wọn yoo si ki irun ikẹyin sii lara ni Mọṣalaṣi rẹ ni Oke Ado.

Bakn naa lo tun ni eto akanṣe miran fun ẹyẹ ikẹyin fun oloogbe Ajimọbi yoo waye lọjọ miran laipẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ajimobi kìí bá ọ̀lẹ, olè àti ọlọ́pọlọ kúkú ṣe ọ̀rẹ́ - Alaafin

Alaafin Oyo wa kan saara si awọn isẹ ati ipasẹ rere ti Ajimobi fi lelẹ, eyi to ni ko ni parẹ laelae.

Abiola Ajimobi: Ọba Adeyemi daro ikú gómìnà àná ní Oyo

Alaafin Oyo, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta ti kẹdun lori iku Gomina ana nipinlẹ Oyo, Abiola Ajimobi.

Ninu ọrọ ibanikẹdun ti agbẹnusọ fun Alaafin, Bode Durojaiye fi sita, Iku Baba Yeye sapejuwe Ajimobi gẹgẹ bi oloselu to ma n mu ileri to ba se fun araalu sẹ lasiko ipolongo ibo rẹ.

Oba Adeyemi fi kun ọrọ pe, Ajimobi jẹ ọlọkan akin ati olori daada ti kii bẹru lati gbe igbesẹ akinkanju, to si setan lati koju ohunkohun to ba tẹyin igbesẹ naa yọ.

Alaafin sọ pe '' Ajimobi mu ipo ogun laarin awọn Gomina ti mo ti ba sisẹ papọ nipinlẹ Oyo.

Mo si ba sisẹ papọ gẹgẹ bi Gomina ati bii baba si ọmọ. To ba jẹ eeyan ti ọpọlọ rẹ pe, ti o jẹ olootọ, ti ẹni naa ko si ya ọlẹ, yoo ba Ajimobi sisẹ pọ.''

Ọba Adeyemi ni ''Ijọba Ajimobi jẹ tolori tẹlẹmu sugbọn eeyan ko le ri nkan gba lọwọ ijọba rẹ bi ko ba dara pọ mọ afojusun eto atunto, imupadabọsipo ati gbigbe Oyo si ipo to ga, to ni lọkan''

Alaafin Oyo wa kan saara si awọn isẹ ati ipasẹ rere ti Ajimobi fi lelẹ, eyi to ni ko ni parẹ laelae.

Ọba Adeyemi wa ba Gomina Seyi Makinde ati ara ilu kẹdun iku Ajimobi, to si sadura pe ki Eledua dẹlẹ fun ẹni rere to lọ.

Lati igba ti wọn ti kede iku Sẹnẹtọ Abiola Ajimọbi lọjọbọ, ni awọn tolori tẹlẹmu ti n sọ ọrọ nipa iku rẹ.

Sẹnẹtọ Ajimọbi dagbere faye lẹni aadọrin ọdun nilu Eko l‘Ọjọbọ.

Kò sí àníàní, Coronavirus ló mú ẹ̀mí Ajimobi lọ - Ìjọba Eko

Saaju la ti kọkọ mu iroyin wa fun yin pe ijọba ipinlẹ Eko ti kede pe arun Coronavirus lo mu ẹmi gomina ana nipinlẹ Oyo, Abiola Ajimobi lọ.

Ikede yii lo si jẹ igba akọkọ ti ijọba yoo fi idi rẹ mulẹ pe oloogbe naa ni arun Covid-19, bi o tilẹ jẹ pe ẹnu ti n kun tẹlẹ.

Kọmisana fun eto ilera nipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Akin Abayomi lo sisọ loju ọrọ naa ninu atẹjade kan to fi sita.

Bakan naa lo kede pe ile iwosan First Cardiologist Consultant, to jẹ ileewosan aladani tijọba fọwọsi lati maa tọju arun Covid-19, ni Ajimobi dakẹ si nibi to ti n gba itọju.

Abayomi tun fikun pe "Gomina tẹlẹ ri ọhun ni ọpọlọpọ ẹya ara rẹ ti daṣẹ silẹ, nitori oró aarun Covid-19.

Bẹẹ ba gbagbe, ọpọ igba ni ẹnu kun Ajimobi tẹlẹ pe o ni arun Coronavirus amọ ti amugbalẹgbẹ rẹ, Tunji Bolaji n sẹ pe irọ ni ọrọ naa.

Wọ́n sún ìsìnkú Abiola Ajimobi di ọ̀la Satide

Iroyin to n tẹ wa lọwọ bayii ti fihan pe eto isinku oloogbe Sẹnatọ Abiola Ajimobi to yẹ ko waye loni ni wọn ti sun siwaju.

Ọla ọjọ Satide, ọjọ Kẹtadinlọgbọn osu Kẹfa ọdun 2020 ni eto isinku naa yoo waye .

Gẹgẹ bi mọlẹbi oloogbe Ajimobi kan to kọ lati darukọ rẹ ti fi to wa leti, wọn sun eto isinku naa siwaju nitori ki aaye lee wa fun ipalẹmọ isinku naa.

Bakan naa la tun gbọ pe, awọn ikọ to n se amojuto arun Coronavirus ni yoo gbe oku Ajimobi wa lati ilu Eko, lati wa sin.

Iroyin naa tun fikun pe iyawo ati awọn ọmọ oloogbe Ajimobi si wa pẹlu oku rẹ nilu Eko, ọjọ Satide si ni wọn yoo dijọ maa bọ wa silu Ibadan.

Akọroyin wa to lọ si mọsalasi Ansarudeen to yẹ ki eto isinku naa ti waye lonii tẹlẹ jabọ pe se ni ibẹ da paro paro.

O fikun pe ni aago mẹjọ si mẹsan owurọ oni to de ibẹ, ko si ẹnikẹni to yọju lati se ipalẹmọ fun eto isinku naa.

A o ranti pe Sẹnatọ Abiola Ajimobi dagbere faye ni ọsan Ọjọbọ nile iwosan kan nilu Eko lasiko to n se aisan ti wọn lo nii se pẹlu Coronavirus.

Òtútù ikú Ajimobi sì ń mú mi, ń kò le sọ̀rọ̀- Akala, Ayefele

Bi ọdẹ ba ku, ọdẹ ni soro lẹyin ọdẹ, bẹẹ si ni ba ba ku laa dere, eeyan ko sunwọn laaye.

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu iku gomina ana nipinlẹ Oyo, Sẹnatọ Abiola Ajimobi to dagbere faye lọjọru.

Pọ eeyan ni ara ta pe akikanju ọmọ ibadan naa ti dara ilẹ, ti onikaluku si n sọ ohun to mọ nipa rẹ.

BBC Yoruba kan si gomina tẹlẹ nipinlẹ Oyo, Otunba Adebayo Alao Akala lati mọ bi iku Ajimọbi se ri lara rẹ.

Akala, ẹni ti ohun rẹ rẹwẹsi lasiko to n ba wa sọrọ ni ohun ko tii le sọ ohunkohun nipa oloogbe naa.

"Iku rẹ ba mi lojiji, jinni-jinni n mu mi lọwọ lori iku Ajimobi, n ko le sọ ohunkohun."

Bakan naa, nigba ta kan si gbajugbaja olorin ẹmi kan nilu Ibadan, Yinka Ayefele, oun naa ni jinni jinni iku Ajimobi si wa lara oun, oun ko si tii setan lati sọrọ.

Amọ nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, agba oye kan nilẹ Ibadan, ti oun ati Ajimobi dijọ se ọmọde, Lekan Alabi ni iku oloogbe naa dun oun pupọ.

Oloye Alabi fikun pe ipa ribiribi ni oloogbe Ajimobi ko si idagbasoke ilu Ibadan ati ipinlẹ Oyo lapapọ.

"Ọdun mẹjọ ti Abiola Ajimobi lo gẹgẹ bii gomina nipinlẹ Oyo lo fi tun ilu se.

O fọ ilu Ibadan to kun fun ẹgbin mọ, Ajimobi fẹ ọpọ́ awọn oju popo to wa nipinlẹ Oyo loju, to si tun kọ afara abẹyẹfo silu Ibadan."

Oloye Alabi tẹsiwaju pe ibatan oun ni Ajimọbi, bẹẹ si ni lati kekere lo ti n fihan pe oun yoo de ibi giga nile aye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Ajimọbi ja fafa ninu iwe lati ewe, o jẹ ẹni to nimọ toto, o gbafẹ, to si ni iwa asaaju rere lati igba ta ti wa ni kekere, osu mẹwaa si lo fi ju mi lọ.

Oloye Lekan Alabi wa gbadura pe ki Ọlọrun tẹ akikanju ọmọ Ibadan naa si afẹfẹ rere.

Ariwo ẹkún sọ nílé Abiola Ajimobi ní Ibadan

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrinlọgbọn oṣu kẹfa ọdun 2020 ni Gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ, Abiola Ajimobi yoo wọ kaa ilẹ lọ.

L'Ọjọbọ ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kẹfa ni Ajimọbi jade laye lẹni aadọrin ọdun.

Ile iwosan First Cardiology to wa ni Ikoyi niluu Eko ni Ajimobi dakẹ si lẹyin ti o ti n gba itọju nile iwosan.

Nigba ti BBC Yoruba se abẹwo sile oloogbe naa nirọlẹ Ọjọbọ, awọn abanikẹdun ti kora jọpọ sibẹ lati daro ẹni rere to lọ.

Bẹẹ si ni igbe ẹkun ti sọ kikan kikan ni ile Ajimobi to n bẹ ni agbegbe 6th Avenue, Yemoja street, Oluyole Estate nilu Ibadan.

Awọn aṣoju ijọba tẹlẹri, alabaṣiṣẹpọ ati aladugbo ko gbẹyin lara awọn to karibọnu nile Ajimọbi bayii.

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ibẹrẹ ọṣẹ yii ni iroyin kan jade pe ayẹwo ti fihan pe Ajimobi ko ni aarun coronavirus.

Ẹwẹ, ẹbi Ajimobi ti sọ pe aago mẹwaa ọjọ Ẹti leto isinku Ajimobi yoo waye ni ilana ẹsin musulumi.

Abiola Ajimobi jáde láyé!

Lọwọlọwọ, iroyin ti a gbọ ni wi pe, gomina ana ni ipinlẹ Oyo, to tun ti jẹ sẹnetọ tẹlẹ nile igbimọ aṣofin agba Naijiria, Sẹnetọ Isiaka Abiola Ajimobi ti dagbere f'aye.

Ṣaaju iṣẹlẹ yii, ohun ta a mọ ni wi pe iroyin n tan kaakiri pe o n ṣaisan nitori pe o ti lugbadi ajakalẹ arun COVID-19.

Awọn iroyin mii tilẹ sọ wi pe, aisan inu ọkan lo n da a laamu nigba ti awọn kan tun ni itọ ṣuga.

Abiola Ajimobi ni gomina ipinlẹ Oyo laarin ọdun 2011 si ọdun 2019, ko to wa du ipo sẹnetọ lati ṣoju ipinlẹ Oyo nile aṣofin agba lọdun 2019 ṣugbọn ko wọle.

Ṣaaju ko to du ipo gomina to ṣẹṣẹ ṣe saa rẹ tan lọdun 2019, o ti ṣe sẹnetọ fun saa kan laarin ọdun 2004 si 2007.

Ẹni aadọrin ọdun ni sẹnetọ Ajimọbi ko to jade laye.