You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
APC: Mí ò tíí ní ìpinnu lóri ìdíje ààrẹ ọdún 2023-Tinubu
Asáájú ẹgbẹ́ òṣelú ẹgbẹ́ APC, Sẹnatọ Bola Ahmed Tinubu ní òun kò ti ṣe ìpinnu láti díje dupò ààrẹ orílẹ̀-èdè Naijiria lọ́dun 2023
Èyí lòdì sí àwọn oníruuru ọ̀rọ̀ tó ti n lọ nígboro tẹ́lẹ̀, yálà Asiwáju ní ǹkan to jẹ òun lógun jùlọ ni bi ọrọ ajé tó n dẹnu kọle yìí yóò ṣe gbéra sọ pada àti bi eto iléra yóò ṣe pada bọ̀ sípò ní Naijiria.
Tinubu sọ eyi di mímọ nínú àtẹ̀jáde kan tó fọwọ́ sí lọ́sàn òní sátide, èyí sì ni ìgbà àkọ́kọ́ tí yóò fọhùn láti ìgbà tí wọ́n ti yọ ọwọ́ Adams Oshiomhole láwọ gẹ́gẹ́ bi alága ẹgbẹ́ náà tí wan sì tú ìgbìmọ amúṣẹ́ṣe ká lọ́jọ́rú ọ̀ṣẹ̀ yìí.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó ní : Sí gbogbo ẹyin ti ẹ ti n kù pé ìgbésẹ̀ ààrẹ Buhari àti ìpáde àwọn ìgbìmọ tuntun nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC ṣe ṣe fi òpin sí ìpínnu mí láti di ààrẹ lọ́dún 2023, ó ṣe mi láànú fún yín"
"Ènìyan ẹlẹ́ràn ara lásán ni mí tí kò sì ni oye ọjọ́ iwájú tàbí ọgbọ́n òṣèlú tí ẹ ń fi ẹnu jẹ́ pé ní, ẹ tí n yọ ayọ lórí ikú ìpínnu ìjákulẹ oyé ààrẹ tí kò ti wáye rárá.
"Tinubu ní kìí ṣe irú àsìkò ti ààrun Covid-19 ń da ètò ọrọ ajé láàmú yìí, mí ò rí ọjọ́ ìwájú tó bi éyin 'se rii" Mí ò sì tíì ṣe ìpinnu kankan láti dupò ààrẹ lọ́dún 2023 nítori pé àwọn ǹkan to n kojú wa ní àsìkò yìí tí lágbára tó.
Ní àsìkò tí a wà yìí, mí ò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ òṣèlú nípa ọdún 2023 jẹ mí lógún, mó rí eyi bi ǹkan ti kò bójú mu rárá, ó sì jẹ́ ìwà àìní ìmọ̀lára lásìkò ti ọ̀pọ̀ ń koju ìṣòro oníhà méjì, ètò ọ̀rs ajé tó nira àti ààrùn tó n kó ìpaya bá gbogbo ayé.
Láti bi oṣù díẹ̀ sẹyìn ni mo ti n ro àwọn ìlànà ìjọba ti a lè gbé silẹ̀ tí yóò ràn ìjọba lọ́wọ́ níhìn àti lọ́hùn.
Ààrẹ tí sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ tó sì sọ ní náà ni abẹ́ gé
Nítori idí èyí mo rọ gbogbo àwọn ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá tí wọ́n túka àti gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ tókù láti fíyedénu kí wọ́n sì máá wo ọjọ́ iwáju rere tó wà níwájú
Mó ti fara ṣiṣẹ́ fún ẹgbẹ́ bí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó kù tàbi jù ẹlòmíràn lọ, sùgbọ́n síbẹ̀ kò nimi lára láti túbọ̀ faraji gẹ́gẹ́ bi ọlọ́dani, kò sì si ẹni to yẹ ko ní ìṣoro kankan lòdì si eyi.
Tinubu, ojú tì ẹ́, o ta Yorùbá fún ọ̀tá torí àdánìkànjẹ - Fani-Kayode
Minisita tẹlẹ ni Naijiria Femi Fani Kayode, ti kọ lẹta ranṣẹ si asaaju ẹgbẹ oselu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, lẹyin ti Aarẹ Muhammadu Buhari yan Alaga fidiẹ tuntun fun ẹgbẹ oṣelu APC.
Fani Kayode ninu lẹta naa ni, bi oun ṣe fẹran Tinubu to amọ iwa rẹ lo mu ki oun sa fun un, nitori imọtara ẹni nikan n ba ja.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
O ni Aarẹ Buhari to fi ṣe ọrẹ ti sọ di ọta, ti gbogbo ero rẹ lori ẹgbẹ oṣelu APC si ti jasi pabo.
Femi Fani Kayode ni bi o tilẹ jẹ pe Asiwaju ti gbekele ara rẹ wi pe oun ko le e ṣi ṣe, ọrọ yii ti ba ẹyin yọ pẹlu bu Aarẹ Buhari ṣe pada lẹyin rẹ, ti wọn si ri pe ko ni ipo kankan mọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC.
'Tinubu ta ẹmi rẹ, ta ọkan rẹ, to si ta gbogbo ilẹ Yoruba, to fi mọ Guusu ati Ariwa orilẹede Naijiria lati le ri wi pe oun mu gbogbo ero ọkan rẹ to kun fun ibi ṣẹ.
O fikun wi pe gbogbo ilakaka rẹ lati jẹ aarẹ orilẹede Naijiria ni ọdun 2015, 2019 ati 2023 lo ti ja si pabo bayii.
Bakan naa lo ni kaka ki Tinubu o ba aarẹ Buhari sọrọ lati wuwa rẹrẹ si awọn ọmọ Naijiria, ki iya ma ba jẹ wọn, niṣe ni Asiwaju n gbe lẹyin Buhari, ẹni to wa jakulẹ bayii.
Ọrọ ipari rẹ ninu lẹta naa ni wi pe o ti tan fun Tinubu ninu oṣelu orilẹede Naijiria, oun ti o ku ni ki o lọ rọkun nile, ki o si ma a sinmi.
O gba ni adura pe lasiko ifẹyinti Tinubu, ohun gbogbo to ti bajẹ lorilẹede Naijiria yoo gba atunṣe.
Oyè adelé alága APC kúrò ní gúúṣù Nàíjíríà, ó bọ́ sẹ́kùn àríwá
Gomina ipinlẹ Yobe, Mai Mala Buni ti di Alaga ẹgbẹ oṣelu APC tuntun ni Naijiria.
Eyi ko ṣẹyin bi Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe tu igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ oselu APC ka, ti o si fi igbimọ fidiẹ sibẹ.
Alága afúnṣọ́ dé fún APC, níbo ni ìbò abẹ́lé l'Ondo yóò já sí?
Ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Ondo ti ni lootọ ni pe, ajọ INEC da lẹta ifitonileti nipa eto idibo abẹle ẹgbẹ naa nipinlẹ Ondo nu.
Akọwe ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Ondo, Alex Kalejaiye lo fi idi ọrọ naa mulẹ fun BBC Yoruba.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Kalejaiye ni abajade ipade awọn igbimọ alaṣẹ, NWC lori yiyan alaga ẹgbẹ oṣelu APC tuntun ni yio sọ ibi ti ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Ondo n lọ.
O fikun pe awọn adari wọn ni Abuja lo ni ọrọ ikẹyin lori bi idibo abẹlẹ APC yoo ṣe ri.
Nibayii, Aarẹ Buhari ti tu Igbimọ Amuṣẹya ẹgbẹ oselu APC ka ni bi ipade to waye ni ile Aarẹ ni Abuja.
Wọn si ti yan gomina ipinlẹ Yobe, Mai Mala Buni gẹgẹ bi Alaga ẹ́gbẹ́ oṣelu APC fidiẹ ni Naijiria.
APC kò ní olórí tí yòó tọwọ́ bọ̀wé, INEC yarí fún ìbò abẹ́nú l'Ondo
Bí wàhálà tó n rú nínú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress ṣe n fi ojoojúmọ́ gbóná janjan ní ìpińlẹ̀ Edo, bakan naa ló jọ bi ẹni pé ẹgbẹ́ náà kò tún rójúùtú ètò ìdìbò abẹ́nú láti yàn oludíje gómìnà lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ náà nípìnlẹ̀ Ondo náà.
Lọ́sàn yìí ni àjọ tó rí sí ètò ìdìbò ní Naijiria (INEC) fi àtẹjáde kan síta pé, ìwé ìfitóniléti tí ẹgbẹ́ APC nípìnlẹ̀ Ondo kọ sí olú ilé iṣẹ́ ẹgbẹ́ náà l'Abuja láti pè òun fún ìdìbò àbẹ́nu wọ́n, kò kójú òṣùwọ̀n tó nítorí pé adelé akọwé àpapọ̀ ẹgbẹ́ APC ní Nìgeria níkan ló buwọ́ lu lẹ́tà náà.
Gẹ́gẹ́ bí àtẹjáde náà ṣe sọ, ìwé ìfitónilétí ti ó tẹ ilé ẹgbẹ́ lọ́wọ́ ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹfà ọdún yìí kò ni àbuwọ́lù àlága àpapọ̀ ẹgbẹ́ náà.
Àtẹjáde tí Rose Oriaran-Anthony, tó jẹ́ akọwé àjọ tó n rí sí ètò ìdìbò ní Naijiria (INEC) buwọlù sàlàyé pé, ìdìbò abẹ́nú tó yẹ kó wáyé ní ogúnjọ́ oṣù kèje ọdún yìí, le ma ṣee ṣe nítori pé àlága apapọ ẹgbẹ́ àwọn akọ̀wé apapọ̀ ẹgbẹ́ ló yẹ kí wọ́n jọ buwọ́lùú.
APC: Àlààyé rèé lórí ìdí ta fi gbé ìlẹ̀kùn olú iléeṣẹ́ APC tì pa l'Abuja
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá tí gbé olú ilé ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress (APC) tì pa nílùú Abuja nibamu pẹlu àṣẹ ọgá àgbá ọlọ́pàá ní Naijiria, Mohammed Adamu.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ wá lọ́wọ́, agádágodo ló wà ni gbogbo ẹnu ọ̀nà ilé ẹgbẹ́ náà l'Abuja.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọkúnrin kan gún àfẹ́sọ́nà rẹ̀ pa tán ló bá tún pa ara rẹ̀ náà
- Ohun tí a mọ̀ nìyí nípa àwọn tí yóò láǹfàní àti lọ sí Hajj lọ́dún yìí
- Àìmọ̀kan ló ń ṣe ìjọba Oyo tó fẹ́ ṣí iléèwé, gbogbo ìpínlẹ̀ ló ní àrùn COVID 19- Ijọba àpapọ̀
- Lórí bóyá igbákejì gómìnà Ondo yóò fipò sílẹ̀ tàbí rárá, ohun tó lu sí wa lọ́wọ́ nìyí
- Ènìyàn 675 ni èsì àyẹ̀wò sọ pé ó tún ṣẹ̀ṣẹ̀ ní Covid-19 ní Nàìjíríà
Iroyin naa ni wọn kò fààyè gba àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe fún ẹgbẹ́ náà láti wọlé sùgbọ́n wọ́n gba àwọn òṣìṣẹ́ àti awọn akọ̀ròyìn láti wọlẹ́ láì gbé mótò wọ́n wọlé.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí súyọ lẹ́yìn tí gbogbo àwọn olórí ẹgbẹ́ òṣèlú APC kò le fẹnu kò lórí ẹni ti yóò dí àdelé alága ẹgbk òṣèlú APC lẹ́ypin ti ilé ẹjọ́ fún Adams Oshiomhole ni ìeé lọ rọ́kún nílé.
Ize-Iyamu borí ìbò abẹ́nú fún idíje gómìnà l'Edo
Iroyin to n tẹ wa lọwọ n fiyeni pe Ize-Iyamu ti jawe olubori gẹgẹ bii oludije ti yoo gbe aṣia ẹgbẹ oṣelu APC ni idibo sipo gomina ni ipinlẹ Edo.
Ẹkunrẹrẹ iroyin n bọ laipẹ.
APC primary election in Edo state 2020: Wo bí nǹkan ṣe ń lọ sí níbi ìbò abẹ́nú fún olùdíje gómìnà lẹ́gbẹ́ òṣèlú APC ní Edo
Awọn aṣoju ti bẹrẹ idibo lati yan awọn Oludije ti yoo gbe aṣia ẹgbẹ oṣelu naa nibi idibo gomina ti yoo waye ni ipinlẹ Edo laipẹ.
Bi ẹ ko ba gbagbe, lọsẹ to kọja ni gomina ipinlẹ naa, Godwin Obaseki kọwe fi ẹgbẹ oṣelu naa silẹ lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.
Ni ọjọ kẹkandinlogun oṣu kẹsan ni idibo sipo gomina yoo waye ni ipinlẹ Edo gẹgẹ bi ajọ eleto idibo, INEC ṣe ti laa kalẹ.
Oniruuru awuyewuye ati edeaiyede lo ti n wọ ts idibo abẹnu ọhun lẹyin lẹgbẹ oṣelu APC eyi to ti mu ki wọn paṣẹ ki alaga ẹgbẹ oṣelu, Adams Oshiomhole naa lọ rọọkun nile pẹlu.
Akọwe igbimọ to n ṣe aayan idibo abẹnu naa, Ajibọla Bashiru ṣalaye fun ileeṣẹ mohunmaworan abẹle kan lọjọ Aiku pe yẹkini kan ko ni yẹ eto naa.
O ni gbogbo wọọdu mejilelaadọwa to wa kaakiri ijọba ibilẹ mejidinlogun ni ipinlẹ Edo ni eto naa yoo ti waye.
Ni ibi eto idibo naa to ṣi n lọ lọwọ lasiko ti a n ko iroyin yii jọ, gbogbo awọn aṣoju to wa dibo nibẹ ni wọn lo ibomu wọn ni ibamu pẹlu ilana ofin COVID-19 ni ipinlẹ Edo.lawọn wọọdu miran, eeyan marundinlogun lo n wa lori ila lẹẹkanṣoṣo ti awọn ọmọ ẹgbẹ si n ṣe afihan kaadi ọmọ ẹgbẹ wọn lasiko ti wọn fi n reti ati dibo.
Idibo yii n waye lẹyin ti ẹgbẹ oselu APC ti ys ọwọ gomina Godwin Obaseki atawọn oludije meji miran, Chris Ogiemwonyi ati Mathew Iduoriyekenwen lawo idije naa.
Edo State: Ẹ̀kọ́ márùn ún tí a rí kọ́ nípa eré tíátà tó ń wáyé l'ágbo òṣèlú ìpínlẹ̀ Edo
Bi eeyan ba ti n fi ọkan ba awuyewuye to n waye lagbo oselu nipinlẹ Edo lorilee-de Naijiria lẹnu ọjọ mẹta yi, yoo ri pe ara ọtọ ni oselu Naijiria,
Ati pe ọrọ oṣelu yii ti gba ọgbọn ati suuru lasiko yii.
Eyi ko ṣẹyin igba ti aawọ laarin Gomina Godwin Obaseki ati alaga ẹgbẹ oṣelu APC, iyẹn Adams Oshiomole bẹrẹ yi,
A ti ri itu orisirisi lati ọwọ awọn to n kopa ninu ohun to fẹ jọ ere ori itage yii, sugbọn to se pe awọn oloselu ni oṣere to wa ninu rẹ.
Ki wa lawọn ẹkọ ta le ri dimu ninu ere agbelewo ti gbogbo ọmọ Naijiria n reti ibi ti yoo kangun si yi?
A o gbiyanju lati se atupalẹ diẹ ninu wọn ni meni meji:
- Ibi a ba ti ki wọn pẹ o daarọ,a tun le sọ pe ekaalẹ níbẹ
Awọn agba Yoruba lo maa n pa lowe pe ibi ti a ba ti sọ pe o daarọ, a kii pada sibẹ lati ki wọn pe ẹ kaalẹ sugbọn lagbo oselu Naijiria ọrọ yi ko fẹẹ ri bẹẹ.
Gomina Obaseki ti o jẹ Gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC la ti ri pe o pada si ẹgbẹ oselu PDP, eyi to ti bẹnu atẹ lu tẹlẹ ri.
Bakan naa la ri ninu ere ori itage Edo yi pe Adams Oshiomole to ti kọkọ kẹyin si Ize Iyamu to ko ipa ribi ribi nigba ti Oshiomole fi dupo Gomina ti wa pada wa fontẹ lu Iyamu gẹgẹ bi ayanfẹ rẹ bayi.
Ọrọ yi ko jẹ tuntun sawọn to ba mọ isesi awọn oloselu Naijiria.
Ṣugbọn ti o ba se pe o n se ẹyin ni kayeefi, ẹkọ nla kan re fun yin lati kọ - oloselu ko ni ọrẹ tabi ọta titi lailai.
Wọn le ba o se ọrẹ loni, bo si di lọla, wọn a ṣe ipolongo lati tako ọ.
2.Aarẹ Buhari ko ṣe é gbọkanle pe o ni baba ni igbẹjọ tabi pe o máa ṣe iṣe baba isalẹ fun ọ:
Ẹkọ pataki yii la ri kọ lati ara aawọ to waye laarin Adams Oshiomole ati Godwin Obaseki.
Bi eeyan ba jẹ oloselu lode toni tabi to n gbero lati darapọ mọ oselu, o ti wa foju han gbangba bayi pe ko le mu aarẹ Naijiria gẹgẹ bi baba isalẹ ti yoo gba a la lọjọ iṣoro.
Gbogbo igbiyanju Gomina Obaseki lọ si ile Aarẹ ni Aso Rock lọdọ Aarẹ Buhari nigba ti ẹgbẹ APC fẹ yọwọ rẹ lawo lati dupo Gomina lo ja si pabo.
Bi o se pe Obaseki woye ohun to sẹlẹ s'ara waju bii Ambọde àti Kwakwanso ninu ẹgbẹ naa ni, ko ni wulẹ daamu ara rẹ.
Gẹgẹ bi awọn onwoye oselu Naijiria ti se sọ, Aarẹ Buhari kii da si ọrọ aawọ to ba n waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ APC.
Ko sẹsẹ bẹrẹ , eyi si kọ ni yoo jẹ opin. Nitori naa, ẹkọ nla re e f'ẹnikẹni to ba fẹ sa lọ ba aarẹ lati gbeja rẹ.
3. Paṣan ti a fi na iyale...
Gbogbo nkan ti a n ri ninu awuyewuye oselu ipinlẹ Edo n jẹki ọrọ yi rinlẹ si lọkan gbogbo ẹni to ba n fi ọgbọn ati oye ba a bọ wi pe awọn oloselu kii ba ara wọn se ọrẹ timọtimọ.
Ki se igba akọkọ re e ta o ri ti baba isalẹ ati ọmọ lẹyin to fa si ipo yoo ma doju ija kọ ara wọn.
Ni ipinlẹ Eko, Gomina Akinwumi Ambode ati agbaọjẹ oloselu ipinlẹ naa Ahmed Bola Tinubu to fa a kalẹ gẹgẹ bi Gomina, pada gbena woju ara wọn.
Ni Kano, iru nkan bayi naa lo sẹlẹ laarin Gomina Abdullahi Ganduje ati ẹni to gbe ipo le lọwọ, Rabiu Kwankwaso.
Ni ipinlẹ Kwara naa ati ri iru rẹ to sẹlẹ ti Abubakar Olusola Saraki to fa Gomina Muhammed Alabi Lawal silẹ wa pada wa doju ija kọ.
Koda, Bukola Saraki to jẹ ọmọ bibi Dokita Olusola Saraki sebi ẹni tako baba rẹ pẹlu bi ko se gbaruku ti aburo rẹ, Sẹnẹtọ Gbemi Saraki ti baba rẹ fẹ ki o jẹ Gomina lẹyin rẹ.
4. Ipo ti a fẹ du ṣe pataki ju ilana ẹgbẹ lọ
Lawọn orile-ede kan, eeyan a maa da ẹgbẹ oselu mọ pẹlu ilana wọn ati ohun to jẹ afojusun to mu wọn da ẹgbẹ silẹ.
Bi oloselu ba gbe igba ibo, abẹ ilana yiii ni yoo fi gbe eto ati erongba isejọba rẹ kalẹ fun awon ara ilu.
Sugbọn ni agbo oselu Naijiria nilẹ toni to mọ yi, awọn oloselu ko fi tẹgbẹ se. Ibi ti wọn yoo ti ribi du ipo lọkan wọn a maa wa.
Apẹrẹ ti a ri lati fi kin ọrọ yi lẹyin ni bi Gomina Godwin Obaseki ko ti se jẹ ki ọjọ pẹ rara ki o to sare lọ darapọ mọ ẹgbẹ oselu PDP lẹyin ti APC ni pe awọn ko fun un ni tikẹẹti ẹgbẹ mọ.
Labẹ pe awọn oloselu ko bikita fun erongba tabi ilana yi naa la ti ri pe awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP naa gba Obaseki tọwọ tẹsẹ,
Koda, wọn si tun fi aaye awọn nkankan gba a, ki o ba le jẹ ẹni ti ẹgbẹ fẹ gbe asia le lọwọ lati du ipo.
Sinima to gun ni ọrọ oṣelu Naijiria, ko fẹ ẹ ni opin:
Nibi ti ọrọ de e duro yii, ko si ẹni to le sọ pe ibi kan ni yoo ja si nigbẹyin.
Nigba ti awuyewuye yii bẹrẹ, Adams Oshiomole lo dipo alaga ẹgbẹ APC mu.
Ni ba ti se n sọrọ yi, ile ẹjọ giga ti yẹ aga nidi Oshiomole ti awọn miran si ti n ja witiwiti lati wa ni ipo alaga.
Labẹ pe ibẹrẹ kọ l'onisẹ, afi ẹni ba laa ja, awọn ti o fi ẹgbẹ oselu APC silẹ fun Oshiomole bi Aarẹ ile asofin agba tẹlẹ ri Bukola Saraki ni wọn wa n gba Godwin Obaseki lalejo ninu ẹgbẹ oselu PDP bayi.
Njẹ ajọsepọ awọn to kora jọ lati doju ija kọ ara wọn wọnyi, yoo jẹ ọlọjọ pipẹ tabi awọn naa yoo pada wa tutọ si ara wọn loju?
Oju re e, iran ree lọrọ to wa nilẹ yi.
E jẹ ki a jijọ maa fọkan ba ọrọ yi bọ.
Godwin Obaseki ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party
Gómìnà ìpínlẹ̀ Edo Godwin Obaseki ti kúrò ní ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Party lọ si ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party.
Akọwé gómìnà Crusoe Osagie lo fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ fún BBC
Sáájú ni Obaseki ti kéde lọ́jọ́ ìsẹ́gun ọjọ́ kẹrindinlógún, oṣù kẹfa ọdún 2020 pé òún yóò kòwé fi ẹgbẹ́ òṣèlú APC silẹ̀ tẹ́lẹ̀.
Lósàn òní ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Edo Godwin Obaseki tìkara rẹ̀ kéde nílé ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party (PDP) nílùú Benin pé òun ti di ọmọ ẹgbẹ́ náà.
Fọ́nran tó jẹyọ lójú òpó twitter ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ni gómínà tí sọ pé "O ní ni ìpínlẹ̀ Edo àti jákèjádò orílẹ̀ -èdè Naijiria ní òún ti dí ọmọ ẹgbẹ́ náà"
Osagie fi kun pé Gómìnà ń pinu láti dupò gómìnà lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.
Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sún ìdìbò abẹ́nú Edo síwájú síi
Obaseki: Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sún ìdìbò abẹ́nú Edo síwájú síi
Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party PDP nipinlẹ Edo to sun ọjọ idibo abẹnu fun awọn to fẹ dipo Gomina ni ipinlẹ naa siwaju.
Idibo ọhun yo yẹ ki o waye lọjọ kokandinlogun ati ogunjọ oṣu Kẹfa yoo ma waye ni ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹfa bayi.
Gẹgẹ bi ohun ti a ri ka ninu iwe iroyin Naijiria The Punch,akọwe ipolongo ẹgbẹ naa Kola Ologbondiyan fidi ọrọ yi múlẹ pe" awọn ti sunjọ idibo naa titi di ọjọ Kẹtalelogun oṣu Kẹfa."
Ṣaaju ni iwe iroyin naa ti jabọ pe Gomina Obaseki ti ṣe ìpàdé kan pẹlu alaga igbimọ awọn Gomina labẹ ẹgbẹ naa Aminu Tambuwal ati alaga ẹgbẹ Uche Secondus l'#Ojọru.
Bayi ti isunsiwaju yi ti waye, o ṣeeṣe ki ẹgbẹ naa ma palẹmọ gbogbo eto lori gbigbe asia ẹgbẹ fun Obaseki lati dupo Gomina naa labẹ orukọ ẹgbẹ wọn.
Gómìnà Godwin Obaseki yóò d'ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP lọ́sẹ̀ yìí
O daju pe ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ni Gomina Godwin Obaseki nlọ,
Yoo si darapọ mọ ẹgbẹ naa ki eto idibo abẹle lati yan oludije ipo gomina ipinlẹ Edo lọjọ kọkandinlogun ati ogunjọ oṣu yii.
Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Edo, Tony Aziegbemi lo fi to BBC News leti bẹẹ.
O ni lootọ ko si idaniloju taarata pe oun ni yoo gbe aṣia ẹgbẹ oṣelu naa nitori iwe ofin rẹ ko faaye gba bẹẹ ṣugbọn o daju pe Obaseki yoo darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu naa.
Ọgbẹni Aziegbem ni bayii ohun to mumu lọkan oun gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Edo ni "lati rii daju pe gomina Ọbaseki darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu naa."
Ni tirẹ, Kọla Ologbondiyan to jẹ agbẹnusọ fun ẹgbẹ oṣelu PDP lapapọ ṣalaye fun BBC pe "ki gomina Obaseki to lee di ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni ṣan an, igbesẹ naa yoo bẹrẹ pẹlu ẹka ẹgbẹ oṣelu naa ni ipinlẹ Edo ki o to kan apapọ ẹgbẹ oṣelu ọhun."
Bakan naa, igbakeji gomina ipinlẹ Edo, Phillip Shaibu pẹlu ti kọwe fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ.
Koda awọn aworan kan to n jade lori ayelujara ṣe afihan Shaibu nibi to ti n yọ aṣia ẹgbẹ oṣelu naa danu ti o si n pariwo 'o digba fun ẹgbẹ oṣelu APC ni ileejọba ipinlẹ Edo'
Ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹfa ni gomina Obaseki kọwe fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ lẹyin ti wọn yọ ọwọ rẹ kuro lawo idije fun aṣia ẹgbẹ oṣelu naa gẹgẹ bi oludije ipo gomina nibẹ.