You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Toyin Abraham: Ó dára ká ní àròjinlẹ̀ pé ayé ni Ọlọ́run fi ju ẹ̀dá lọ
Yoruba ni lowe lowe ni a n lu ilu agidigbo, ọlọgbọn lo n jo, ọmọran si lo n mọ ọ.
Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu iwaasu ti gbajumọ oṣere tiata lobinrin, Toyin Abraham ṣe loju opo Instagram rẹ, eyi to fi n pa asamọ lowe lowe nipa awọn iṣẹlẹ agbọsọgbanu to n waye lawujọ wa lẹnu ọjọ mẹta yii.
Bi o tilẹ jẹ pe Toyin ko sọ pato ohun to n kọ ọ lominu to fi kọ awọn ikilọ yii sita.
Sugbon a mọ pe, ayan to mu kọngọ lọwọ, lo mọ ohun to n fi ilu sọ, amọ o ṣee ṣe ki awọn arojinlẹ ọrọ naa da lori iku Ibidunni Ighodalo to jade laye lọsẹ to kọja.
Toyin salaye ninu ọrọ rẹ naa pe awọn iṣẹlẹ ẹnu ọjọ mẹta yii n jẹ ki oun ronu jinlẹ, ki oun si fi oju ọtọ wo ohun ti wọn n pe ni aye taa wa yii.
Toyin ni "Mo wo ara mi, mo si ronu nipa aye yii ati ohun gbogbo to wa ninu rẹ,
O si han si mi pẹlu ẹdun ọkan pe asan ni aye, omulẹ mofo. Idi si ree to fi rọrun fun wa lati maa gbe aye wa lonii lai ranti ohun to sẹlẹ lanaa."
O ni "Lootọ gbogbo wa la mọ pe aye ko tọ lọ bii orere, binti laye sugbọn ṣe ojoojumọ la n ranti ọrọ yii, taa si n ṣíṣẹ tọ ọ?
Oye mi nipa aye yii ti yatọ ni akoko taa wa yii, haa, o ma dara ki eniyan ni arojinlẹ o."
Gbajugbaja oṣere tiata naa fikun un pe, ti eeyan ba mọ inu ro, oye aye yii yoo han si wa kedere pe igba diẹ ni aye
Amọ, a kan n sare le awọn ohun to wa lonii, ti ko ni si mọ ni ọla, pẹlu ireti pe yoo wa titi laelae.
Toyin, ti ọpọlọpọ eeyan tun n pe ni 'Mama Ire' tẹsiwaju pe aye yii kere ju ki eeyan maa fi ojoojumo ja lọ
Toyin ni: "A n gbero nipa ohun ti yoo sẹlẹ ni oṣu mẹfa si akoko yii bii ẹni pe ọla gan an daju fun wa,
Eyin ololufẹ mi, aye ni Adiitu ti Olodumare fi ju ẹda lọ, a n ṣe eto ohun gbogbo amọ, Ọlọrun nikan lo le jẹ ko wa si imusẹ.
Mo si n bi ara mi leere pe Oluwatoyin ki lo de to n le òjìji aye kiri nigba to jẹ pe Ọlọrun lo ni aye rẹ? ".
- Báwó ni òògùn dexamethasone ṣe ń ṣiṣẹ́ lára
- Àwọn tó ní Covid-19 ní Nàìjíríà tún ti pọ̀ si, ènìyàn 661 ló tún ṣẹ̀ṣẹ̀ ni i
- Ìséde ká mi mọ́ orí afára Kara ni mo ní kí n sùn, ki ọkọ̀ mi tó jóná
- Oníṣòwò kan wó ọ́fíìsì Nàìjíríà ní Ghana lulẹ̀, ìjọba Nàìjíríà faraya
- Ó di gbéré! Arẹwà Ibidunni Ighodalo wọ káà ilẹ̀ lọ nílùú Eko
O fikun un pe ohun kan lo ti ye oun bayii pe gbogbo ohun to n dan kọ ní wura,
Orọ̀ kankan ko si ni wa titi aye amọ ohun to daju ni pe ko si ẹni to le ra aye gbe, oun si ti ri alaafia nipa mimọ Ọlọrun.
Toyin ni ohunkohun ti Ọlọrun ba seto rẹ pe yoo jẹ ti oun, yoo wa sọdọ oun lọjọ-kọjọ, Ọlọrun nìkan si lo ni akoso ohun gbogbo.
Gbajumọ oṣere tiata naa wa gba awọn ololufẹ rẹ ni imọran pe aye yii fuyẹ, ofo ni, ọna ta ba si gba lati gbe inu rẹ ni yoo jẹ ko ṣe iyebiye fun wa, nitori naa, ẹ gbe igbe aye to ni itumọ.