You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
'Ó yẹ kí ẹnu mi wọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́, kí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ má dá, mi ò lè rìn dáadáa'! Ṣé o lè mọ̀ lára Anifa pé ó ní Hemiplegia Cerebral Palsy?
"Kò yẹ kí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dá. kò yẹ kó lè rìn, ó yẹ kí ẹnu rẹ̀ wọ́ koda "fẹgbẹ wọ ọ" ni wọn o ba maa pe e àmọ́ iyalẹnu ni ifọrọwanilẹwo waq pẹlu Anifat jẹ. Arun Hemiplegia Cerebral Palsy lo n baa finra leyi to jẹ pe lati kekere ni nkan ti yipada fun un ni gba to wa ni nkan bii ọmọ ọdun mẹta ti aisan iba yọju.
"Mama mi sare gbe mi digba digba lọ sileewosan, awọn nọọsi bẹrẹ iṣẹ amọ ṣaadede ni mi o le rin mọ. Iya mi tilẹ gbagbọ pe iru abẹrẹ ti nọọsi fun mi lo sọ mi di da bi mo ṣe da". Anifat Sadu ni Hemiplegia lo kọkọ bẹrẹ, igba to to bii ọmọ ọdun mẹsan, o ni ohun tun ni Scoliosis eyi to yẹ ko sọọ di ẹni ti egungun rẹ wọ, ki ara maa dun un ki iṣan maa dun o si ṣe apẹrẹ nkan ti gbajugbaja elere ori ọdan, Usaine Bolt n la kọja tori aisan Scoliosis yii.
"Ti wọn ba n ṣe ere idaraya, wọn a ni ki n lọ joko si ẹgbẹ kan, ti mo ba n rin loju titi, awọn eyan a maa doju bo mi, mo maa sunkun gidi pẹlu ibanujẹ ọkan". Anifat ní "àwọn ẹlẹ́gbẹ́ mi máa ń fi mi ṣe yẹ̀yẹ́ bí ọwọ mi bá ń gbọ̀n àti bí mo ṣe ń rìn ní School". Anifat sọ ipenija to tun koju gaan ni Fasiti to ti kawe gboye.