"Mo ní àìsàn Lupus, n kò le bá ọkọ mi lòpọ̀ fún ọdún márùn-ún àkọ́kọ́ lẹ́yìn ìgbeyàwó"

"Mo ní àìsàn Lupus, n kò le bá ọkọ mi lòpọ̀ fún ọdún márùn-ún àkọ́kọ́ lẹ́yìn ìgbeyàwó"

Adura gbogbo ẹda ni pe ka ma se aisan amọ nigba to ba de adura ki ọlọjọ mase de lo ku ta maa gba.

Obinrin kan ree, ti a ko fẹ darukọ tabi fi oju rẹ han to ni aisan to maa n mu ki awọn eroja ara maa ba ara wọn ja, eyi ti wọn n pe ni Lupus.

Bẹẹ ba gbagbe, gbajumọ osere kan, Kemi Afolabi Adedipe naa kede losu diẹ sẹyin pe oun ni aisan naa, eyi to n ba agọ ara oun ja.

Nigba ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ lori aisan naa, obinrin alaisan ọhun ati dokita kan to ni imọ nipa arun ọhun, Hakeem Olaosebikan salaye itu ti aisan naa le fi ẹni to ba mu pa.

Iba ati ikọ ni mo fi bẹrẹ laimọ pe aisan Lupus lo mu mi:

Ninu alaye obinrin naa, o sọ pe ọdun ti oun se igbeyawo gan ni aisan Lupus yii bẹrẹ, bii iba ati ikọ wiwu si lo ba wọle.

O ni oun ko tiẹ tete mọ lara afi igba ti ikọ naa le laleju, ti ayẹwo si fi fidi rẹ mulẹ lẹyin ọdun meji ti oun ti n jẹ irora pe aisan Lupus lo n ba oun finra.

O salaye pe oun ko tiẹ kọkọ gbagbọ, ti oun si morile oke okun, ki wn wa sọ pe lootọ ni Lupus wa ni agọ ara oun.

Ẹdọ fooro ati awọ ara mi ni Lupus kọkọ ba ja:

Ninu ọrọ rẹ, obinrin alaisan Lupus naa ni orisirisi ẹya ara ni Lupus maa n kọju ija si nitori o le ba oju ati awọ ara jẹ.

Amọ o ni niti oun, ẹdọ fooro oun lo kọkọ nawọ gan, ti oun yoo si wukọ awule tọntọ, ti awọ ara oun gan ko si bọ lọwọ rẹ.

O fikun pe aisan naa ni irora pupọ to si dabi ki oun lọ pokunso lati bọ lọwọ rẹ, ti oun si nilo lati fi isẹ oojọ oun silẹ nitori aisan naa.

Dokita ni emi ati ọkọ mi ko gbọdọ lopọ fun ọdun marun lẹyin igbeyawo:

Arabinrin naa ni ọpẹlọpẹ adura ni oun fi bimọ kan soso ti oun bi nitori pe aisan Lupus maa n jo oyun mu ni.

Idi si ree, to fi ni awọn dokita gba oun ati ọkọ oun nimọran lati mase sun mọ ara awọn, titi di ẹyin ọdun marun.

Asiko naa si ni oun bi ọmọ kan soso ti oun bi naa pẹlu ẹbẹadura ati atilẹyin ọkọ oun, to si n mọ riri awn obi ati ọkọ rẹ fun atilyin wọn.

Arabinrin naa gba gba awọn to ni aisan naa nimọran pe Lupus see wo amọ ko le san patapata ninu agọ ara ni, ti wn si nilo ifẹ ati iranwọ ẹbi wn lati gbe ile aye.

Obinrin ni Lupus maa n mu ju ọkunrin lọ, paapaa ọmọge – Dokita Olaosebikan

Nigba to n ba wa sọrọ, dokita Olaosebikan to nimọ nipa arun Lupus salaye pe obinrin ni arun naa maa n ba finra julọ ju awọn ọkunrin lọ.

Dokita ni awọn mọge ti wọn wa ni ọjọ ori ọdun mejidinlogun siwaju si lo saba maa n ni arun Lupus julọ.

O salaye pe lara awọn ohun ta fi le mọ Lupus ni ara gbigbona, keeyan maa laagun pupọ ati ikọ hihu.

O wa gba awọn ẹbi awọn to ba ni arun naa nimọran lati sugba wọn nitori wn nilo ifẹ ati iranwọ lati ọdọ ẹbi wọn.