You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kemi Afolabi Battles Lupus: Wo ọmọ Yorùbá mẹ́ta àti àwọn gbajúmọ̀ tó ní Lupus, àrùn tó n bá Kemi Afolabi fínra
Laipẹ yii ni gbajugbaja osẹrebinrin, Kemi Afolabi, sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pe oun ni aasun Lupus, ti dokita si sọ pe oun pe ọdun marun-un pere lo ku fun oun lati lo laye.
Ninu ọdun marun-un naa, o ti lo ẹyọkan.
Botilẹ jẹ pe lootọ ni ko si iwosan fun aarun Lupus yii, ọpọ eeyan lo ni i, ti wọn si n gbe igbeaye alaafia.
Ko ni iwosan, ṣugbọn oogun, ounjẹ, ati awọn ayipada igbe aye ma n din agbara rẹ ku.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Dókítà ní ọdún márùn-ún ló kù fún mi láyé, mo sì ti lò lára rẹ̀ - Òṣèré Kemi Afolabi
- Wo àwọn nǹkan tó le fa lupus - àìsàn tó ń bá Kemi Afolabi fínra
- Portable Zazzu pariwo pe wọ́n ti dá ọjọ́ méje pé òun yóò kú
- Èèdì àti ogun ayé ni awọn èèyàn n rò pé ó mú mi bí ìbejì ní ìgbà mẹ́fà
- Tẹ̀gbọ́n tàbúrò jí ọmọ ará àdúgbò gbé láti gbowó, àmọ́ wọn fún ní òògùn eku jẹ
- Ìjàmbá ọkọ̀ tún gbẹ̀mí ènìyàn mẹ́tàlá ní òpópónà márosẹ̀ Ilorin sí Ogbomoso
- Ọjọ́ Ajé la bẹ̀rẹ̀ ìpè fún ìdásílẹ̀ Yoruba Nation padà - Akintoye
Koda, ajọ to n ṣeranwọ lori aarun naa sọ pe eeyan bi miliọnu marun-un lo ni aarun Lupus ni agbaye.
Arabinrin A
Abala kan ori rẹ lo kọkọ pá.
Amọ lọdun 2010, o ṣakiyesi pe ara rẹ bẹrẹ si ni ṣú bii igba ti eeyan ni kokoro. Gbogbo itọju to fun, ko mu ara ṣiṣu naa kuro.
Kẹrẹkẹrẹ, o bẹrẹ si ni di egbò.
O ṣalaye fun BBC ninu ifọrọwanilẹnuwo lọdun pe, o to ọdun marun-un ki awọn dokita to ri aridaju pe aarun Lupus ni oun ni.
Arabinrin naa sọ pe itiju kii jẹ ki oun le sọ iru aarun to n ṣe oun. O ni ina ni oun ma n sọ fun awọn eeyan pe o jo oun lara.
O sọ pe aarun naa nipa lara kindinrin oun, ọkan ati ọpọlọ.
O ṣi wa laaye bayii.
Arabinrin B
Ẹlomiran to tun ni aisan naa lara ni orilẹ-ede Naijiria ni Arabinrin yii to jẹ alase.
Ni tiẹ, niṣe ni nkan ṣu si oun naa lara. Eyi to sọ pe o jẹ ki ara oun yi bi pọnmọ ti wọn fi n se ọbẹ.
Ko pẹ to ṣe igbeyawo ni aarun naa bẹrẹ si, to si jẹ ibanujẹ fun awọn ẹbi rẹ.
Ẹlomiran sọ fun BBC pe oun deede ji ni ọjọ kan, ni oun ri pe oju oun wú, ti ara rẹ si n bo awọ.
O ni laipẹ ni oun bẹrẹ si ni ri ẹjẹ ninu ìtọ̀ ati ìgbẹ́ ti oun ba yà.
Awọn gbajumọ mii to tun ni aarun Lupus, ti wọn ṣi wa laye:
Selena Gomez:
Gbajugbaja olorin ni Selena Gomez, ọmọ ilẹ America.
O sọ lọdun 2015 pe ọpọlọpọ asiko ni oun fi pa iṣẹ orin kikọ ti lẹyin ti wọn sọ fun nileewosan pe o ni Lupus.
Ọdun 2013 ni iroyin ti kọkọ jade nipa ilera rẹ, nigba to wọgile awọn irinajo kan to yẹ ko lọ ni Asia ati Australia fun orin kikọ.
Ọpọ iroyin lo sọ nigba naa pe oogun oloro lo n yọ ọ lẹnu.
Koda, aarun naa ba kindinrin rẹ jẹ, debi i pe wọn paarọ rẹ lọdun 2019.
Nick Cannon:
Gbajugbaja olorin, oṣere, ati apanilrin ni Nick Cannon nilẹ America.
Ọdun 2012 ni wọn sọ fun pr o ni Lupus. Aarun naa ba kindinrin rẹ jẹ. Bakan naa ni ẹjẹ dì sinu ẹdọfooro rẹ.
O ṣi wa laye titi di oni lẹni ọdun mọkanlelogoji.
Toni Braxton:
Akọrin mii, Toni Braxton naa kede pe oun ni Lupus lọdun 2011. Lati igba naa lo si ti n ṣe ilanilọyẹ lori aarun naa.
Ẹni ọdun mẹrinlelaadọta ni lọwọlọwọ.