You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kemi Afolabi: Ọdún márùn-ún ló kù fún mi láyé - Òṣèré Kemi Afolabi sọ ọ̀rọ̀ tó já ni láyà nípa ìlérà rẹ̀
Gbajugbaja oṣerebinrin Kemi Afolabi ti pada ṣi aṣọ loju pabanbari aisan to n ṣe e gangan eyi to ti de mọra lati ọjọ yii.
Lori eto ori ayelujara kan pẹlu gbajumọ sọrọsọrọ Chude Jideonwo eyi to fi sita lọjọ Ẹti ni ọrọ naa ti jade lẹnu oṣere yii.
Pẹlu omije loju, Kemi Afolabi kẹnu bọ ọrọ lori ohun to n la kọja ti ko sọ faraye tẹlẹ.
Nibo ati nigba wo ni ọrọ yii ti bọ si Kemi Afolabi lọwọ?
Gẹgẹ bo ṣe sọ, Afolabi sọ pe ọkan lara awọn dokita rẹ ti sọ fun oun pe ọdun marun lo ku fun oun lati lo loke eepẹ.
Koda o fi kun un pe dokita ọhun ṣee lalaye pe "gbiyanju lati "rii daju pe o n wa pẹlu awọn eeyan rẹ, awọn too fẹran, waa ṣi le gbe o kere tan ọdun marun laye".
Ẹwẹ, o ni oun ti baba lo ọdun kan ninu gbogbo ọdun ti wọn ni o ku fun oun laye bayii to si sọ tẹkun tẹkun loju wipe oun ko mọ iye ọdun to ku fun oun bayii.
Kemi Afolabi jẹ ọkan lara awọn irawọ oṣerebinrin ninu fiimu Yoruba to si jẹ ọmọ orilẹede Naijiria.
Nigba to n sọrọ nipa arun to n baa finra yii, o ni "aisan to n ṣe mi ni aisan to maan n mu ki idahun ag ara eeyan gbogun ti awọn tiiṣu ara iwọ gan funraarẹ eyi ti oloyinbo n pe ni "Lupus".
Aisan yii ko gboogun gẹgẹ bo ṣe sọ ọ. O ni "oogun nikan ṣa ni o le maa lo fun iyoku aye rẹ".
O jẹ ko di mimọ pe oun ti na miliọnu kan o le diẹ lori itọju kan ṣoṣo sibẹ gbogbo oogun naa ko ṣiṣẹ tori o tẹsiwaju lati maa ke irora.
Bakan naa ni Kemi Afolabi sọ pe oun ti kọ iwe dukia oun ati pe oun ti sanwo aye ibi ti wọn yoo sin oku oun si lẹyin ti dokita kede iru aisan to n ṣe e fun un.
Atọkun eto naa Chude sọ pe awọn akẹgbẹ Kemi Afolabi lo kan si oun pe "wa, Kemi ni lati sọ itan aye rẹ faye, o nilo iranwọ".
O tun ṣipaya sii pe o le ni miliọnu kan ti o n na lọsọọsẹ lati jẹ ko ṣi maa gbe aye.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ni ibẹrẹ ọdun yii ni oṣere naa ri ikọlu to ni awọn adigunjale kọlu oun ninu ọkọ rẹ. Ko pẹ sirawọn naa lo fi fidio bi o ṣe n la kan lara awọn asiko itọju ilera rẹ kọja.
Lori eto naa ni Kemi ati Chude ti pada bu sẹrin ti wọn sọrọ lori awọn nkan to n mu inu rẹ dun laye.