Kemi Afolabi Adesipe: Oṣù kan ni mo fi gba "Oxygen" àmọ́ síbẹ̀ Olúwa dára!

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja oṣerebinrin, Kemi Afolabi Adesipe ti sọrọ lori aisan ti ko gboogun to kọlu lọdun 2021.

Ninu ọrọ idupẹ to kọ si ori ayelujara Instagram rẹ lo ti sọ pe koda, aisan naa mu ki oun kọ iwe ipin ogun, ti wọn n pe ni 'Will' ni ede Gẹẹsi, ti oun si ta awọn dukia oun.

Adesipẹ sọ pe oun ti gbagbọ pe aisan naa ni yoo gba ẹmi oun, o ni ṣugbọn Ọlọrun jẹri ara rẹ ninu aye oun.

Àìsàn tó ń ṣe mí kò gbóògùn, àmọ́ mo dúpẹ́ pé ẹ̀mí mi wà

Mo ta gbogbo dúkìá mí nítorí àìsàn tí kò gbóògùn tó ń sé mí - Kemi Afolabi

Ninu alaye to ṣe, o ni ọjọ mẹta-mẹta ni oun n ṣe ayẹwo aarun Covid-19, ni ibudo itọju pajawiri to wa ni ileewosan ikọṣẹ iṣegun oyinbo Fasiti ipinlẹ Eko, LASUTH.

Ayẹwo naa n waye nitori bi ko ṣe le mi daadaa, to si n gba afẹfẹ oxygen fun oṣu kan gbako.

Arabinrin Kemi Afolabi sọ pe gbogbo ayẹwo ti wọn ṣe fun nilewosan ko fi koko aisan to n sẹ oun han, ti wọn si n gbe oun kaakiri ileewosan mẹta ọtọọtọ ki oun to lo oṣu mẹta ni Lagos University Teaching Hospital, LUTH.

"Aṣiwere eniyan nikan ni yoo sọ pe Ọlọrun ko si.

"Mo ta awọn dukia mi, nigba ti mo na gbogbo owo ti mo mi ni ipamọ tan.

Idi si ni pe mo mọ pe gbigbe iṣoro mi jade fun araye tabi titọrọ owo fun itọju yoo tete pami ju aisan fun'ra rẹ lọ."

Kemi ṣalaye pe nigbẹyin, wọn pada ri orukọ fun aisan to n ṣe oun.

Orukọ aisan naa si ni SLE.

Afolabi sọ pe lootọ ni aisan naa ko gboogun, ṣugbọn o ṣe e mojuto nipa oogun lilo ati pe ki oun ma a lọ si ileewosan ni oorekoore.

Aisan SLE ọhun si lo sọ pe o mu ki nkan di ọna ti eemi n gba jade tabi wọle. Iṣẹ abẹ si ni wọn fi jo gbogbo nkan to di .

Arabinrin Kemi Afolabi adesipe sọ pe lootọ ni aisan naa ti yi igbaye oun pada patapata, ṣugbọn oun dupẹ pe oun ṣi wa laye.

O fikun ọrọ rẹ pe o nira ni ọpọ igba lati lo awọn oogun to n din irora aisan naa ku, amọ to tun mu ki oun ma a sanra si.

Bakan naa lo sọ pe ọpọ eeyan ti ko mọ nkan ti oun n la kọja maa n sọrọ pe oun ti n sanra ju bi o ṣe yẹ lọ.

Ọdun 2019 ni iroyin kan jade pe oṣerebinrin yii n ṣe aisan, lẹyin to deede ṣubu, to si daku lasiko irinajo Hajj to ṣe ni Mecca lọdun 2019.

Nkan to yẹ ki o mọ nipa aisan SLE

Systemic Lupus Erythematosus (SLE) ni wọn n pe.

O jẹ aisan to ma n jẹyọ̀ nigba ti awọn eroja idaabobo 'immune system' ba bẹrẹ si ni kọju ija si ara wọn, eyi to ma n fa ki awọn tiṣu to wa ninu ẹya ara to ba kọlu, ma a wu u.

O le kọlu orikerike ara, ọpọlọ, awọ ara, kidinrin ati awọn ọpa to n gbe ẹjẹ.

Ko ti si aridaju nipa nkan to maa n fa aisan yii, ṣugbọn awọn onimọ iṣegun oyinbo gbagbọ pe o nii ṣe pẹlu ayika, ajogunba tabi nipasẹ awọn omoonu to wa ninu ara.

Awọn apẹẹrẹ aisan SLE

Lara awọn apẹẹrẹ ti ẹni to ba ni aisan yii yoo ma a ri ni pe yoo ma rẹ ni gbogbo igba, ara rẹ yoo ṣú, ara gbigbona, irora tabi ki orikerike ara rẹ ko wu u.

Awọn apẹẹrẹ miran ni ọgbẹ ẹnu, awọka, aisan ẹdọ fooro, aisan ọkan, aisan kindinrin, gìrì ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Lootọ ni aisan yii ko gboogun, ṣugbọn pẹlu itọju ati amojuto to peye lati ọdọ awọn dokita to mọ nipa rẹ, to fi mọ gbigbe awọn igbe aye kan, ẹnikẹni to ba ni le gbe lai si ewu.