You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
2021 Round up News: Ìròyìn BBC Yorùbá Marun-un ti o mígboro tìtì lọdún 2021
Ṣebi gbogbo ibi ni wọn ti n dana alẹ, eyi si ni ko jẹ ki ti ile iṣẹ BBC News Yoruba yatọ gẹgẹ bi ile isẹ iroyin yi kii jẹ ki eti yin di si awọn nnkan ti o n lọ lawujọ wa.
Idi ree ti a ni k a ran yin leti awọn iroyin gbankọgbi ti a ti muwa si eti igbọ yin ti ẹ si ti ri loju iworan yin yala lori atagba wa tabi lori atẹ ikansirẹni Facebook/Instagram wa.
Kẹrẹkẹrẹ ọjọ diẹ naa lo ku ti a ma dagbere fun ọdun 2021, ti a si maa wipe, o tun di arina ko, o tun di oju ala.
Asiko yii ni olukuluku yoo maa boju wo ẹyin lati woye nnkan ti wọn ti fi odidi oṣu mejila ṣe, bawo si ni wọn ṣe lo o?
Ṣe awọn se aṣeyori ni abi bawo ni awọn se bori awọn ijakulẹ to waye laarin ọdun ati bi wọn se ṣe ajọyọ awọn oriIre ti wọn le naka si.
- BBC Africa Eye tú aṣírí ẹgbẹ òkùnkùn Black Axe ní Nàìjìríà, ìpànìyàn àti àwọn olóṣèlú tó wà lẹ́yìn wọn
- Wàhálà bẹ́ sílẹ̀ níbi ayẹyẹ ọlọ́dọọdún ní ìpínlẹ̀ Osun
- Ìdí ti Ààrẹ Buhari ṣe kọ̀ láti buwọ́lu àtúnṣe ìwé àbádòfin òṣèlú ọdún 2021 rèé
- Kéére o! Wọ́n ti ṣíṣọ lójú Okú Ọbá Pharaoh ti ilẹ̀ Egypti lórí ayélujára
Awọn Iroyin wa ti o milẹ titi fun ọdun 2021
Lara awọn oniruuru iroyin wa ti o migboro ni a ti ni ki a mu diẹ yii wa si iranti yin
Baba Ijesha
Ní inu osu kẹrin ọdun 2021 ni ariwo bẹrẹ si ni lọ soke sodo loju opo awọn gbajugbaja osere kan nipa akẹgbẹ wọn ti o se aṣemase pẹlu ọmọ kekere kan lara ọmọ ẹgbẹ wọn
Sugbọn laipẹ ni ọrọ yii di rant, lo di eyi ti a n gba bi ẹ ni gba igba ọti laarin awọn oseere ti o si fé pin awọn ọmọ ẹgbẹ iha kan si Ikeji
Iroyin naa ni pe James Omiyinka ti gbogbo eniyan mọ si Baba Ijesha lo lọ si ile ọrẹ rẹ Oluwadamilola Adekoya ti ọpọ mọ si Princess Comedia ti o si ṣe Aṣe maṣe nibẹ.
Ki a to wi ki a to fọ wọn fa Baba Ijesha le ọlọpaa lọwọ ti wan si fi ẹsun sisẹ ọmọde ti ko ti balaga basubasu
Lẹyin osu diẹ ti ọpọ awọn ajafẹstọ dide lori ọrọ naa ni wọ́n gba lati fi silẹ lahamọ ọlọpaa ti wọn si ti bẹrẹ si ni ṣe ẹjọ lati asiko naa lọ
Gbogbo bi ọ̀rọ̀ yii ṣe n lọ titi de ibi ti o de duro lasiko yii ni BBC News Yoruba mojuto
Diẹ lara awọn ila yii lo tọka si gbigbo iṣẹ ti a ṣe lori rẹ:
- Wọ́n lù mí bíi ẹní máa kú, wọ́n ya aṣọ mọ́ mi lọ́rùn nílé Princess kí n tó dé àgọ́ ọlọ́pàá - Baba Ijesha
- Ìwádìí fihàn pé Baba Ijesha ṣe aṣemáṣe pẹ̀lú ọmọdé, a kò gba béèlì rẹ̀ - Ọ̀gá Ọlọ́pàá Eko
- Ọjọ́ mẹ́rin ni mo fi bẹ Princess pé kí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha má di ẹjọ́ - Iya Rainbow
- Baba Ijesha yóò jẹ́jọ́ ìwà tó hù, ohun tó bá gbà, ni màá fun - Iyabo Ojo
- Princess tún sọ òkò ọ̀rọ̀ sí Iya Rainbow lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha
Bi Awọn ajọ DSS se lọ kọlu ile Sunday Igboho ni Ibadan
Ni ọjọ kini osu keje ọdun 2021, iroyin pe ikọ ọtẹlẹmuye ni Naijiria (DSS) ti lọ yabo ile ẹni ti o pe rẹ ni ajijagbarafun awọn ọmọ Yoruba Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho.
Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, Sunday Igboho moribọ lọ awọn ikọ DSS sugbọn wọn ko awọn alabaṣiṣẹ pọ rẹ mejila lasiko naa ti wọpn si ko wọn da si ahamọ awọn DSS.
Ile Iṣẹ BBC News Yoruba moju to iṣẹlẹ yii pẹlu lẹsẹlẹsẹ.
Lẹyin eyi ni Sunday Igboho gbiyan lati rinrin ajo lọ si orilede Germanyu sugbọn to pinu lati gba orilede Benin lọ, Awọn ọlọpaa Benin mu ti ọrọ naa di ariwo lorilede Naijiria pẹlu Ibeere bi
Kilo se? kii ṣe ọdaran? Ẹ tu Sunday Igboho silẹ, sugbọ titi di asiko yii Sunday Igboho si wa ni ahamọ ẹwọn orilede Benin.
Diẹ lara awọn nnkan ti a se nipa rẹ ni a mu wa si iranti yin
- Ilé mi kọ́ ni àwọn DSS ti kó àwon ìbọ́n tí wọ́n pàtẹ- Sunday Igboho
- Àwọn DSS àti ṣọ́jà ló kọlu ilé mi, mo fojú mi kòrókòró rí wọn - Sunday Igboho
- Àwọn jàǹdùkú yìnbọn sókè lọ́pọ̀ ìgbà kí wọn tó jó ilé Sunday Igboho - Ọlọ́pàá Oyo
- Ilé ẹjọ́ ti gba béèlì àwọn èèyàn méjìlá tí DSS mú nílé Sunday Igboho
- Ó tó gẹ́, Sunday Igboho fẹ́ gbé ìjọba lọ ilé ẹjọ́ bí wọn kò bá tú àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀
- Sanwo-Olu ṣàlàyé ohun táwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá ń ṣe lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho
Iwode Yorùbá Nation ni Ojota
Bí a se n run ti Suday Igboho lẹnu lọwọ ti ko tii kuna ni ti iwọde Yoruba Nation tun ti gbera sọ.
Asiko yii ni kọmisọna ọlọpaa nipinlẹ Eko sọ pe ko si ẹnikẹni ti o gbọdọ gbiyanju lati ṣe iwọde ifẹhonuhan kankan ni ipinlẹ Eko ati pe ẹni ti o ba dan iru rẹ wo yoo fi oju wina ofin.
Saaju ọjọ yii ni Sunday Igboho ati awọn ọmọ Yoruba miiran jakejado Naijiria ti da ọjọ kẹta osu keje ọdun lati se iwọde yii.
Sugbọn ọjọ kini odun keje ni awọn ikọ ajọ DSS yabo ile Sunday Igboho, sugbọn awọn ọmọ lẹyin rẹ ti o ku ni awọn yoo tẹsiwaju ninu iwọde naa.
Iwọde yii waye lootọ sugbọn, o mu ẹmi ọmọbinrin kan to n jẹ Jumoke lọ bi ibọn ọlọpaa se lo ba ni sọọbu ti o ti n taja ni agbegbe Ojota.
Lasiko yii bakan naa ni ọ\lopaa mu awọn eniyan mẹtadinlaadọta to wa lara awọn ti o kopa nibi iwọde naa.
Lara awọn nnkan ti BBC kojọ ni asiko naa ree
- Ta a ló yìnbọn pa Jumoke, ọmọ ọdún 14 nítòsí ibi ìwọ́de Yoruba Nation ní Ojota?
- Wo ohun tó yẹ ko mọ̀ nípa Saheed Adigun (Adogan) tó kú nílé Sunday Igboho
- Ìwádìí wa fihàn pé kìí ṣe òkú tùtù ni ọmọ tí wọ́n sọ pé a pa ní Ojota, àwa sì kọ́ ló pa á - Ọlọ́pàá Eko
- Olùwọ́de 47 nínú àwọn tí ọlọ́pàá kó ní ìwọ́de Yoruba Nation ti gba ìtúsílẹ̀ láhámọ́ ọlọ́pàá
- Ilé ẹjọ Májísírèètì Yaba nípinlẹ Eko ti gba béèlì àwọn olùwọde Yoruba Nations 49 tí wọn wa ní àhámọ
- Kò jọ́ọ́! Àṣìṣe kọ́, Ọlọ́pàá mọ̀ọ́mọ̀ pa ọmọ ọdún mẹ́rínlà lásìkò ìwọ́de Yoruba Nation ní Ojota - Femi Falana
Iyabo Oko Se Aisan
Iroyin aisan Kudirat Odukanmi ti gbogbo eniyan mọ si Iyabo Oko naa jẹ ọkan lara awọn iroyin to ta kale ta ka oko ninu ọdun 2021 lati ile isẹ BBC News Yoruba.
Foluke daramola lo kọkọ ke gbajare sita pe awọn agabaagba osere ninu Nollywood n ṣe aisan ti ọpọ ko si kọbi ara si wọn
O ni Iyabo Oko wa lori idubulẹ aisan ti ko le gbe apa tabi gbe ẹsẹ.
Ko pẹ si asiko yii naa ni ọmọ rẹ jade sita lati tọrọ fun iranwọ ara ilu nitori pe ipo tri iya naa wa ni agbara gidi.
- Ìròyìn ayọ̀, Iyabo Oko kúrò nílé ìwòsàn, ó ń sọ̀rọ̀ fatafata àmọ́...
- Báyìí ni ìrìnàjò àìsàn Iyabo Oko ṣe bẹ̀rẹ̀ láti ọdún márùn ún ṣẹ́yìn
- "Àìsàn tó ń ṣe Iyabo Oko ti ṣàkóbá fún ọmọ ìka ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀"
- A ti gbálé ati gbáta, kò sí ǹkankan lọ́wọ́ wa mọ́ ni a ṣe kígbe síta- Adebisi Aisha, Ọmọ Iyabo Oko
- Mo ta ọkọ̀ ayọkẹ́lẹ́ méjì lórí àìsàn yìí, mo nílò ìrànwọ́ ẹ̀yin olólùfẹ́ mi - Iyabo Oko
Iku Baba Suwe
Bi osu kọkanla ọdun se n poju de lọ ni ariwo tun ta pe irawọ kan tun ti ja, iyẹn gbajugbaja ninu osere tiata Yoruba Babatunde Omidina ti gbogbo eniyan mọ si Baba Suwe ti gbekuru jẹ lọwọ ẹbọra.
Baba suwe ku ni ọjọ kejilelogun, osu kọkanla ọdun 2022 lẹyin aisan ranp, ti wọn si ṣe isinku rẹ lẹyin ọjọ mẹjọ gẹgẹ bi ilana musulumi ti gbogbo eniyan mọ ni ẹsin oloogbe.
Lasiko isinku baba Suwe ọpọ awọn gbajugbaja osere lo peju sibi ayẹyẹ naa ti wọn si sọ iriri wọn lasiko ti wọn jẹ alabaṣiṣẹpọ fun oloogbe ọhun
eyi ni akojọpọ gbogbo awọn iroyin BBC lori isinku baba Suwe