Baba Ijesha: Iya Rainbow ní Princess ń sá ní iléẹjọ́ báyìí lẹ́yìn tọ́rọ̀ di ariwo tán

Ọpọ eeyan lo ti n kọminu nipa laasigbo to n waye lagbo osere tiata Yoruba, paapaa bi awọn agba ati ọjẹ wẹwẹ osere se n tako ara wọn lasiko yii.

Gbogbo ede aiyede naa ko si sẹyin ọrọ ẹsun ti wọn fi kan gbajumọ osere tiata kan, Olanrewaju Omiyinka, ti ọpọ mọ si Baba Ijesha pe o se asemase pẹlu ọmọde.

Ọpọ awọn osere tiata si lo ti n gbe oju agan sira wọn lori isẹlẹ yii, bi awọn kan se ni o yẹ kawọn agba osere sọrọ soke lori isẹlẹ naa, ni awọn miran ni ko yẹ bẹẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọpọ oṣere tiata bii Yomi Fabiyi lo tako Iyabo Ojo lori ọrọ naa, to si ti fa ede aiyede nla silẹ laarin wọn, to fi mọ Bukky Black, Legemiami ati awọn miran.

Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ Aiku ni ẹgbẹ awọn osere tiata TAMPAN kede pe oun ko ni faramọ iwa ọyaju si ẹgbẹ naa latọdọ awọn osere tiata.

Bakan naa lo ni ki gbajumọ oserebinrin meji, Iyabo Ojo ati Nkechi Blessing lọ rọkun nile na, tori bi wọn se n sọrọ tabuku ẹgbẹ naa.

Amọ Nkechi Blessing lo ti n sọrọ tako igbesẹ naa, to si n gboju agan si agba osere kan, Jide Kosoko, ẹni to jẹ ọkan lara igbimọ majẹobajẹ ẹgbẹ TAMPAN to kede ijiya ẹsẹ oserebinrin mejeeji naa.

Nkechi naa ṣalaye tiẹ pe ẹgbẹ TAMPAN ko lagbara lati da oun duro nitori oun kii ṣe ọmọ ẹgbẹ naa.

Bakan naa lo tun sọ fun agba oṣere Jide Kosoko pe awọn ọmọbinrin rẹ yoo dọwọ boju ti oun ba fi le tu aṣiri rẹ sita.

Amọ Iyabo ni oun ko korira Baba Ijesha bi ko ṣe ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan lori ọmọdebinrin adẹrinṣonu, Princess.

Awọn iwa yii lo ti wa n kọ ọpọ eeyan lominu, ti wọn si n beere pe igba wo ni alaafia yoo pada sagbo tiata, ẹka ti Yoruba?

Idi ree ti BBC Yoruba fi kan si ọkan lara awọn agba ọjẹ oṣere tiata lati mọ igbesẹ ti wọn n gbe, lati pe omi alaafia pada wa sagbo tiata Yoruba.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Idowu Philips tawọn eeyan mọ si Iya Rainbow ni ọrọ naa ti daru bi ẹsẹ telọ bayii.

Princess ń sá ní iléẹjọ́ báyìí lẹ́yìn tọ́rọ̀ di ariwo tán

''Ki ọrọ yii to delẹ rara, ọjọ mẹrin ni mo fi bẹ Princess wi pe ko maa jẹ ki ọrọ yii di ẹjọ.

Mo bẹ ẹ gan an wi pe ko maa jẹ ki ọrọ yii di ariwo, ẹ wa wo ohun to gbẹyin ọrọ yii bayii.

Baba Ijesha da nisin yii, wọn ṣi i silẹ, iyẹn ni a ṣe n sọ pe ki a tun nkan ṣe niyẹn.

Baba Ijesha jẹbi, o jare, ki awa kọkọ dide bi ẹgbẹ. Ni sin yii, Princess wa n sa ni ile ẹjọ wi pe ọna wo ni oun le gba lẹyin, ki wọn maa ri oun."

Iya Rainbow tẹ́siwaju pe ibẹrẹ ija kọ ni eeyan maa n ro, a n ji lati ro ibi ti ija maa pari si.

O wa gbadura pe ki Ọlọrun fun onikaluku ni omi suuru mu, nitori adura ni ọrọ naa gba bayii.

O ni ti Esu ba ti wọ ṣokoto, o maa n ko sinu awọn ọmọde yẹn ni, ko si si nnkan ti agbalagba maa se nipa rẹ.

"Ṣe a fẹ ṣepe fun wọn ni, ṣe a fẹ le wọn ni? Kin lo fẹ gbẹyin rẹ? Eeyan kii leyan nibi ijẹ rẹ. Ẹ maa binu naa ni wọn maa sọ fun wa, ti awa agba yoo si gba a mọra."

Agba osere tiata naa ni ohun to wa nibẹ ni pe Eleduwa naa ni awọn yoo maa bẹ, ko ba awọn yanju ọrọ to wa nilẹ yii.