You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sunday Igboho: Ẹ gbọ́ ohun tí Sanwo-Olu sọ lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti sọrọ lori ohun tawọn gomina ilẹ Yoruba n ṣe lori bi wọn ju Oloye Sunday Adeyemo(Igboho) si atimọle ni ilu Cotonou, lorilẹede Benin.
Ọpọ eeyan lo ti n kọminu pe awọn gomina apa iwọ oorun guusu ko sọ ohun kan loi bi wọn ṣe mu Igboho lorilẹede Benin.
Gomina Sanwo-Olu sọ fawọn akọroyin nibi eto idibo ijọba ibilẹ Eko lọjọ Abamẹta pe iṣẹ n lọ labẹlẹ lori ọrọ Igboho.
- Ẹ̀mí mímọ́ ló ní kí n múra lài wọ bùbá láti ṣe ọjọ́ ìbí mi torí pé ... - Òṣèré Clarion Chukwura
- Ó nira fún Sunday Igboho láti jẹun ní àtìmọ́lé ọlọ́pàá torí wọ́n dè é lọ́wọ́- Agbejọ́rò
- Ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ lọ ní ìrọwọ́-rọsẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun- Kọmíṣọ́nnà
- "Ẹ̀yin àgbà amòfin nílẹ̀ Yoruba, ẹ kó lọ sí Cotonou láti gbèjà Sunday Igboho"
- Gbaga ọlọ́pàá ni Igboho ti ń lo òpin ọ̀sẹ̀, ilé ẹjọ́ ilẹ̀ Benin kò jókòó lọ́jọ́ Ẹtì
- Adájọ́ pàṣẹ pé kí DSS kó èèyàn méjìlá tó kó nílé Igboho wá sílé ẹjọ́
- Isó fààá leè jẹ́ kí ẹ kò Covid-19 níbi tí o ba fún pọ̀! Ẹ fura o!
''Awọn eeyan n ṣiṣẹ lọ labẹlẹ, ko digba tawọn gomina ba to n sọrọ ni gbangba ki araalu to mọ pe wọn o dakẹ lori ọrọ Igboho.
Asiko yii to le ni akoko yii fun gbogbo wa, ṣugbọn mo fẹ fi da yin loju pe iṣẹ n lọ labẹlẹ.
Nibi ti ọrọ de duro bayii, ko niṣe pẹlu iye awọn akọroyin ti eeyan ba ba sọrọ.
Ohun ti mo mọ ni pe ọpọ eeyan lo n ṣiṣẹ lẹgbẹ lẹgbẹ ati lọlọdanni, ko digba ti wọn ba to sọrọ ni gbangba,'' Sanwo-Olu ṣalaye.
Ọjọ Aje ọjọ kọkandinlogun oṣu keje lawọn agbofinro mu Igboho ni papakọ ofurufu Cadjèhoun niluu Cotonou, lorilẹede Benin.
Oun ati iyawo rẹ, Ropo ni wọn n jọ n rinrin ajo lọ si orilẹede Germany nibi ti wọn ti fẹ wọ baalu laago mẹjọ alẹ ki wọn to mu wọn.
Ṣugbọn awọn gomina ilẹ Yoruba ko ti sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun lati ọjọ Aje ti Igboho ti wa ni gbaga ọlọpaa.
Ohun ti ijọba orilẹede Naijiria sọ fun Benin ni pe Igboho ti lu ofin ni Naijiria wi pe ki wọn mu un nibẹ.
Awọn aṣoju ijọba Naijiria tun sọ fun ile ẹjọ ni Benin pe Igboho ko ibọn pamọ sile eleyii ti o fẹ lo lati pin orilẹede Naijiria.
Wọn tun sọ pe Igboho n lo awọn eeyan lati da ilu ru.
Ijọba Naijiria tun sọ pe Igboho n ṣe fayawọ ibọn.
Ṣugbọn ọkan lara awọn agbẹjọro Igboho, Ibrahim Salami to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe ko si otitọ kankan ninu awọn naa.