Sunday Ighoho in Court: Ìdájọ́ jáde! Ilé ẹjọ́ ti ní kí Sunday Igboho ṣì wà ní àhámọ́ ní Cotonou!

Ile ẹjọ to n gbọ ẹjọ Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ni orilẹ-ede Benin ti paṣẹ pe ki Sunday Igboho kuro ni ibi ti wọn tii mọ lati ọj ti wọn ti fi panpẹ ofin muu.

Idajọ naa jade loru ọganjọ ọjọ Aje ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu keje ti igbẹjọ rẹ bẹrẹ ni orilẹede Benin Republic.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ṣaju ni iroyin n tan kaakiri pe wọn de Igboho ni ọwọ ati ẹsẹ ni ahamọ ọlọpaa amọ ni wakati melo kan sẹyin, iyawo rẹ Ropo sọ fun BBC Yoruba pe wọn ti yọ ṣẹkẹ-ṣẹkẹ ọwọ rẹ kuro Wo àǹfàní tí wọ́n ṣẹ̀sẹ̀ fún ìyàwó Sunday Igboho ní Cotonou.

Ẹwẹ, ile ẹjọ ti dajọ wi pe ki eekan aṣiwaju ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba naa si wa ni ahamọ.

Ahamọ naa ko ni jẹ ibi ipamọ awọn ọlọpaa to wa tẹlẹ eyi ti wọn n pe ni brigade criminelle bikoṣe ibi ipamọ ọgba ẹwọn lati oni lọ.

Eyi tumọ si wipe wọn ṣii nipo kuro nibi to wa lati ibẹrẹ igbẹjọ yii si ibomiran.

Amoṣa titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, wọn ko tii sọ ẹkunrẹrẹ bi wiwa ni ahamọ rẹ yoo ṣe ri.

Ni ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu keje, ọdun 2021 ni iroyin kan jade sita pe ọwọ awọn agbofinro ti tẹ Sunday Igboho ni orilẹ-ede Benin Republic.

Ijọba orilẹ-ede Naijiria nipasẹ awọn ileeṣẹ agbofinro rẹ, paapaa julọ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti fi orukọ Igboho sita gẹgẹ bi ẹni ti wọn n wa.

Iroyin si sọ pe lasiko to n gbero lati lọ sorilẹede Germany nibi to ti n gbero lati ṣe atipo ni wọn mu ni papakọ ofurufu Cardinal Bernardin International ni ilu Cotonou.

Lati igba naa lo si ti wa ni ahamọ awọn ọlọpaa nibẹ ki wọn to fi iyawo rẹ, Rọpo silẹ lọjọbọ ọsẹ to kọja lẹyin igbẹjọ ile ẹjo kan lorilẹ-ede naa.

Nibayii, a ko tii lee sọ boya awọn agbẹjọro rẹ yoo pe ẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ naa.