You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sunday Igboho: Wọ́n ti yọ ṣẹ́kẹ́-ṣẹkẹ̀ lọ́wọ́ Igboho, àǹfàní tí wọ́n ṣẹ̀sẹ̀ fún ìyàwó rẹ̀ ní Cotonou rèé
Ẹgbẹ Ilana Omo Oodua ti ṣalaye bi nkan ṣe n lọ lori igbẹjọ Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho.
Ninu atẹjade kan ti alukoro ẹgbẹ naa, Maxwell Adeleye fi sita ni o ti ṣalaye pe awọn ẹṣọ eleto abo ti yọ ṣẹkẹ-ṣẹkẹ kuro lọwọ Igboho bayii.
Wọn ni alẹ ọjọ Abamẹta ni awọn ẹṣọ yọ ma mun gaari kuro lọwọ Igboho.
- Wọ́n tí lọ́ ẹ̀sùn míì mọ́ Sunday Igboho lẹ́sẹ̀ ní ìlú Benin! - Agbẹ́jọ́rò Igboho
- Òní lònìí ń jẹ́! Ìjọba àti Sunday Igboho yóò kójú ára wọn nílé ẹjọ́ lórílẹ̀èdè Cotonou
- Ìgbẹ́jọ́ aṣáájú ẹgbẹ́ tó ń pè fún Biafra Nnamdi Kanu tẹ̀síwájú nílùú Abuja
- Oríire ló jẹ́ fún Sunday Igboho bí ọwọ́ òfin kò ṣe bàá ní Nàìjíríà - Femi Falana
- Pẹ̀lú omijé lójú làwọn òbí akẹ́kọ̀ọ́ 28 Bethel Baptist táwọn ajínigbé tú sílẹ̀ fi pàdé ọmọ wọn
- 'Bàbá tó gbé owó ''ransom'' lọ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jígbé, àwọn jàndùkù ajínigbé bá mú òun náà mọ́lẹ̀
- Sanwo-Olu ṣàlàyé ohun táwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá ń ṣe lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho
- Ilé ẹjọ́ nílùú Eko ti sún ìgbẹ́jọ́ Baba Ijesha sí ọ̀la Ọjọ́rú, wo ohun tó ṣẹlẹ̀
Ni bayii, wọn ti fun iyawo Igboho, Ropo ni anfaani lati ri ọkọ rẹ ni igba mẹta lojumọ.
Bakan naa, awọn oṣiṣẹ eleto ilera ti ẹgbẹ Ilana Omo Oodua fi ranṣẹ si orilẹede Benin ti ṣe ayẹwo ilera rẹ.
Ilana Omo Oodua tun sọ pe Igboho ko ṣẹ si ofin irina lati orilẹede kan si omiran rara lorilẹede Benin.
Oni ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu keje ni igbẹjọ Igboho yoo tẹsiwaju, o si ṣeeṣe ki ileẹjọ ṣe agbeyẹwo bo ya ki ijọba Benin da a pada si Naijiria.
Ilana Omo Oodua tun rọ awọn ololufẹ Igboho lati ma ṣe lọ si ile ẹjọ ni Benin.
Wọn rọ wọn wi pe ki wọn duro ni Naijiria ki wọn si maa gbadura fun Igboho.
Ẹgbẹ Ilana Omo Oodua ni o dawọn loju pe Igboho yoo gba ominira lonii nile ẹjọ.