You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Covid-19 spreads through farting: Bí isó ṣe leè jẹ́ kí ẹ kò Covid-19
Awọn minisita ilẹ United Kingdom ti n gba ọrọ kan bi ẹni n gba igba ọti bayii lorii iwadii tuntun kan to tun jade pe iso yiya tun ti n tan arun Covid-19 ka bayii.
Oniruuru ileeṣẹ iroyin nilẹ UK n kọ iroyin pe awọn minisita n tọka si aridaju ti wọn ri pe ajakalẹ arun naa lee safẹrẹ bọ si ara ẹlomiran to ba wa laarin ibi ti eeyan kan ti fẹ iso jade bii ni ile igbọnsẹ.
Ọkan ninu wọn ni awọn ti ka oniruuru iroyin iya o ba baba tan lati awọn orilẹede mii amọ ṣa, awọn oṣiṣẹ ijọba onimọ sayẹnsi o tii ṣe iwe jade lori rẹ gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe iroyin The Telegraph.
Iroyin naa sọ pe awọn aridaju abuda ara kan wa to so pọ mọ ọna ti nkan ti ko daa lara n gba jade to lee fi nkan ranṣẹ laarin eeyan meji ti wọn ba jọ wa nile iyagbẹ. Eyi jade ni orilẹede Australia.
Bakan naa, wọn ri akọsilẹ awọn oniruuru iṣẹlẹ aarun yii to n tan ka lati ipasẹ ọpa to n gbe igbọnsẹ danu lasiko isede Covid-19 ni ilu Hong Kong.
Bo tilẹ jẹ pe imọ sayẹnsi ko lọ taara lori ọrọ yii minisita mii si tun ni pẹlu bi aarun Covid-19 ṣe jẹ arun kan to n gba inu eemi ran kiri, aranka rẹ ṣaba maa n wa lati ẹnu tabi paapaa julọ imu.
Agbẹnusọ olootu ijọba ilẹ naa, Boris Johson sọ pe ko mọ nipa gbogbo eyi to tun jade yii atipe iso siso lee jẹ ki arun Covid-19 ran ka.
Agbẹnusọ rẹ fi kun un pe "a maa n ṣe ayẹwo gbogbo abajade imọ sayẹnsi daadaa".
Eeyan to ba wa ni ilera pipe ni lati ya iso ni iye igba iṣẹju marun si mẹẹdọgbọn loojọ, ayẹwo kan fihan pe arun SARS-CoV-2 lee farahan ninu igbẹ.
Erongba nipe ewu to wa ninu pinpin arun Covid lọna yii kere jọjọ amọṣa, nitori wiwọ awọtẹlẹ atawọn aṣọ abẹ, o lee ṣeranwọ ki gbogbo iso naa paapaa eyi to lewu to ni aisan ninu ma jade sita lọna ti lilo ibomu naa maa n ṣe lati ẹnu tabi imu ẹnikan si ẹlomiran.
Aba pe Covid lee ran latara iso kọkọ jẹ jade ni orilẹede Australia lọdun to kọja nigba ti Norman Swan onimọ iṣegun Sayẹnsi kan gba imọran lori itakun iroyin ABC Podcast pe: "Ẹ ma ṣe yaso pẹlu idi ofifo mọ!".
Ni ilẹ UK, awọn onimọ Sayẹnsi kasẹ eto nilẹ nibi ti wọn ti ṣe agbeyẹwo omi ile igbẹ lati mọ moya apẹr ibẹrẹ arun Covid-19 wa ninu rẹ ninu oṣu karun, nibayii wọn ti n wo eto naa ni ọpọlọpọ agbegbe England.
O ti ṣeranwọ lati mọ aranka arun naa lawọn ibi igberiko eyi ti wọn ri lawọn ilu kereje kereje nipa ṣiṣe ayẹwo ọpa ile igbẹ. eleyi si ni Dokita Jenny Harries to jẹ oludari agba ẹka ilera ilẹ UK ṣapejuwe gẹgẹ bi "afikun ọna lati mọ ẹni to ba ni arun Covid-19".