You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Local Government Elections: Aṣíwájú Bola Tinubu kò dìbò nínú ìbò ìjọba ìbílẹ̀ tó wáyé l'Eko
Fun igba akọkọ ni nkan bi ọdun mẹwaa sẹyin, Aṣiwaju Bola Tinubu ko kopa ninu eto idibo ijọba ibilẹ to waye nipinlẹ Eko lọjọ Abamẹta,ọjọ kẹrinlelogun oṣu keje, ọdun 2021.
Awọn akọroyin rọ lọ si ibudo idibo 047 to wa ni agbegbe Sunday Adigun, Alausa, ni Ikeja nibi ti Tinubu ti maa n dibo.
Amọ, iyalẹnu lo jẹ fawọn akọroyin pe wọn ko ri Tinubu ni ibudo idibo lati wa dibo.
- Ẹ̀mí mímọ́ ló ní kí n múra lài wọ bùbá láti ṣe ọjọ́ ìbí mi torí pé ... - Òṣèré Clarion Chukwura
- Sanwo-Olu ṣàlàyé ohun táwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá ń ṣe lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho
- Ó nira fún Sunday Igboho láti jẹun ní àtìmọ́lé ọlọ́pàá torí wọ́n dè é lọ́wọ́- Agbejọ́rò
- Ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ lọ ní ìrọwọ́-rọsẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun- Kọmíṣọ́nnà
- "Ẹ̀yin àgbà amòfin nílẹ̀ Yoruba, ẹ kó lọ sí Cotonou láti gbèjà Sunday Igboho"
- Sunday Igboho ń bẹ iléẹjọ́ láti ṣe àtìpò òṣèlú nílẹ̀ Benin
- Igun kan PDP ìpínlẹ̀ Ogun kọ̀ lati kopa nínú ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ lónìí
- Gbaga ọlọ́pàá ni Igboho ti ń lo òpin ọ̀sẹ̀, ilé ẹjọ́ ilẹ̀ Benin kò jókòó lọ́jọ́ Ẹtì
Paro paro ni ibudo idibo naa da pẹlu ẹtaworo awọn oludibo nibẹ nigba ti BBC Yoruba ṣabẹwo sibẹ.
Ni kete tawọn akọroyin gbọ pe Tinubu ko ni jade wa dibo ni wọn kuro ni ibudo idibo naa.
Ko si ẹni to mọ idi ti Tinubu ko fi le kopa ninu eto idibo ijọba ibilẹ ipinlẹ Eko to waye, bo tilẹ jẹ pe awọn kan ni Aṣiwaju ko si ni Naijiria lọwọ yii.
Ohun ti a gbọ ni pe ẹgbẹ oṣelu APC lo jawe olubori ni ibudo idibo Tinubu bo tilẹ jẹ pe oun gan ko si nile lati dibo.
Ẹwẹ, iroyin kan tun sọ pe gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ ri meji, Babatunde Fashola ati Akinwunmi Ambode naa ko dibo ni ibudo idibo idibo wọn.
Ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ lọ ní ìrọwọ́-rọsẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun- Kọmíṣọ́nnà
Kọmiṣọnna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati ọrọ oye jijẹ nipinlẹ Ogun, Afolabi Afuape, ti ṣapejuwe eto idibio ibilẹ to waye nibẹ lọjọ Abamẹta gẹgẹ bi eto to lọ wọọrọ wọ.
Kọmiṣọnna Afuape ni bi o ti yẹ ki eto idibo ri naa ni eto ibo ijọba ibilẹ ipinlẹ Ogun ọjọ Abamẹta ṣe ri.
Kọmiṣọnna naa woye pe awọn oludibo to fi mọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu alatako lo huwa bi ọmọluabi ni ibudo idibo.
- Ó nira fún Sunday Igboho láti jẹun ní àtìmọ́lé ọlọ́pàá torí wọ́n dè é lọ́wọ́- Agbejọ́rò
- Sunday Igboho gbé DSS àti Abubakar Malami lọ sílé ẹjọ́ láti jà fún ẹ̀tọ́ rẹ̀
- Gbaga ọlọ́pàá ni Igboho ti ń lo òpin ọ̀sẹ̀, ilé ẹjọ́ ilẹ̀ Benin kò jókòó lọ́jọ́ Ẹtì
- "Ẹ̀yin àgbà amòfin nílẹ̀ Yoruba, ẹ kó lọ sí Cotonou láti gbèjà Sunday Igboho"
Onikaluku lo dibo lai si ija tabi fifi ada le awọn eeyan kaakiri lawọn ibudo idibo.
''Imọran mi fawọn ọmọ ipinlẹ Ogun ni lati maa tẹsiwaju ninu ṣiṣe ojuṣe wọn nipa ibo ibo didi.
Ti a ko ba dibo, a ko lẹtọọ lati maa bu ijọba to wa lode pe wọn ko ṣe daadaa.
Akiyesi ikọ BBC Yoruba nibi eto idibo naa fihan pe awọn oludibo ko tu yaya jade lati dibo kaakiriri ipinlẹ Ogun.
Àwọn olùdibò ko jáde dibo ni ipínlẹ̀ Eko, ení tere èjì tere lo n jáde
Bí àwọn ènìyàn ìpínlẹ Eko ṣe ń jade lónìí láti dibo yan alága ìjọba ibílẹ̀ tuntun sí ìjọba ìbílẹ̀ ogun àti LCDA métàdílógóijì, olùjábọ̀ ilé iṣẹ́ BBC Yoruba ni àwọn ènìyàn kà jáde láti wa dibo.
Ní nǹkan bi aago mẹwaa abọ ti akọròyìn BBC de àwọn Ibudo idibo 004 Opebi ni LCDA Onigbongbo, kò ti si ètò kan pàtó to n lọ.
- Ẹ má fún mí tabi àwọn olóòṣelú ni ẹ̀bùn kankan mọ́, ẹ lọ́ ran agbègbè yin lọ́wọ́- Buhari sọ fún ọmọ Naijria
- Adájọ́ pàṣẹ pé kí DSS kó èèyàn méjìlá tó kó nílé Igboho wá sílé ẹjọ́
- Ẹni tí inú bá ń bí lórí fíìmù Oko Iyabo, le gba iléẹjọ́ lọ - Yomi Fabiyi
- Àwọn olùdibò ko jáde dibo ni ipínlẹ̀ Eko, ení tere èjì tere lo n jáde
Ni àwọn ìhà ibòmíràn nibẹ̀, lẹ́yìn ìforúkọ sílẹ̀ wọ́n ni ki àwọn olùdi[bò pàda wá láti dibo bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ènìyàn kan péré náà ló ti jáde wá láti dibo
Díẹ̀ lára àwọn fótò tó ṣe àfihàn bí nǹkan ṣe n lọ níbi ìdìbò tó n wáyé nílùú Eko rèé.
Ko sí òlùdibo kankan ni Ibudo idibo Agege 009
Àwọn asoju ẹgbẹ́ òsèlú àti àwọn elétò ìdìbò ti wà ni ìkàlẹ̀ ni ibudo ìdìbò 011 ni agbègbè Ifako, sùgbọ́n ko si olùdibò
Ẹ̀wẹ̀, nǹkan yàtọ díẹ̀ ni ìpínlẹ̀ Ogun àwọn oludibò dílẹ̀ jáde fún ìdìbò yan alága sí ìjọba ìbílẹ̀ ogun tó wa níbẹ̀
Àbẹwò ilé iṣẹ́ BBC Yorùbá sí Wọ́ọ̀dù 7 ibudo idibo 003 & 004 nijọba ibílẹ̀ Abeokuta North fi han pé àwọn ètò ìdìbò tí n gbéra sọ níbẹ̀.
Igun kan PDP ìpínlẹ̀ Ogun kọ̀ lati kopa nínú ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ lónìí
Awọn apa kan ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) ni ipinlẹ Ogun ti ni àwọn ko ni kopa ninu eto idibo si ijọba ibilẹ ti yoo waye ni ipinlẹ naa lonii.
Ipinu yii ko ṣẹyin idajọ ile ẹjọ to ni ki awọn awọn oṣiṣẹ eleto idibo ti ipinlẹ Ogun (OGSIEC) tẹsiwaju lati maa ba eto idibo lọ.
Ile ẹjọ giga ni ilu Abeokuta lo pasẹ pe ki OGSIEC tẹsiwaju lati ṣeto idibo lẹyin ti ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ naa Oloye Sikirulai Ogundele pe lodi di OGSIEC.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho ń bẹ iléẹjọ́ láti ṣe àtìpò òṣèlú nílẹ̀ Benin
- Gbaga ọlọ́pàá ni Igboho ti ń lo òpin ọ̀sẹ̀, ilé ẹjọ́ ilẹ̀ Benin kò jókòó lọ́jọ́ Ẹtì
- Gbaga ọlọ́pàá ni Igboho ti ń lo òpin ọ̀sẹ̀, ilé ẹjọ́ ilẹ̀ Benin kò jókòó lọ́jọ́ Ẹtì
- Ẹgbẹ́ òṣèlú mọ́kànlá forí ṣánpọ̀n nílé ẹjọ́ láti wọ́gilé ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ l‘Eko
- Adájọ́ pàṣẹ pé kí DSS kó èèyàn méjìlá tó kó nílé Igboho wá sílé ẹjọ́
- N kò ṣe ẹlẹ́yà Sunday Igboho, irọ́ ni wọ́n pa mọ́ mi - Olayomi Koiki
- ‘Passport’ Nàíjíríà àti Germany ni wọ́n ká mọ́ Sunday Igboho lọ́wọ́ - Agbẹjọ́rò
- "Ẹni tó bá gba 'Passport Benin Republic' láì ṣe ọmọ onílùú, yóò fi ẹ̀wọ̀n jura"
- Mo kìlọ̀ fún Igboho kó má wá sí ilé mi ní Benin Republic, lẹ́yìn táwọn ọlọ́pàá ń ṣọ́ mi - Alábàṣiṣẹ́pọ̀
- Benin Republic ló bẹ́gi dínà aáyan ìjọba àpapọ̀ láti kù gììrì gbé Igboho wá Naijiria - Amòfin
Sugbọn, nigba ti ile ẹjọ ka igbẹjọ rẹ, Ogundele ni lootọ ni ile ẹjọ ko jiyan pe oun kọ ni olori ẹgbẹ naa ni ipinlẹ Ogun sugbọn o kọ lati da eto idibo duro.
Oloye Ogundele wa pe awọn ọmọ ẹgbé lati ma kopa ninu eto idibo naa.
Ninu atéjade to fi sita, lo ti sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ko ni kopa ninu eto idibo naa.
"Atẹjade naa ka bayii: Gbogbo awọn akopa ninu eto idibo to jẹ ọmọ ẹgbẹ, ti wọn ti se ayẹwo fun lati kopa gẹgẹ bi oludije ninu idibo ijoba ibilẹ labẹ ẹgbẹ PDP.
Gbogbo ololufẹ ẹgbẹ ati awọn ti ọrọ kan lati farabalẹ ki wọn si ni igbagbọ ninu idara oun"
Sugbọn oloye miiran ninu ẹgbẹ naa ọmọọba Leke Shittu ṣalayhe pe ẹgbẹ oṣeelu PDP yoo kopa ninu idibo naa nitolri pe awọn to ni ikunsinu laarin ọmọ ẹgbẹ ko le maa paṣẹ nnkan ti gbogbo ọmọ ẹgbẹ yoo ṣe.
O ni OGSIEC ti ṣe nnkan ti o yẹ ki wọn se nipa ṣiṣe atunto awon ẹgbẹ to yẹ, ti o si rọ awọn ti ko dun mọ lati fọwọwọnu ki wọn si dibo fun ẹgbẹ wọn.
Alaga OGSIEC Babatunde Osibodu, to fidi ẹjọ ti wọn da si igbo naa mulẹ sọ pe gbogbo aaye ti o yẹ ki awọn ẹgbẹ PDP wa, ni wọn wa fun idibo ti yoo waye lonii.