Baba Ijesha: Iyabo Ojo ní ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti tú àṣírí báwọn oníwàkòtọ́ ṣe pọ̀ sí ní Nàìjíríà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajumọ oṣere tiata, Iyabọ Ojo ti ṣalaye idi to fi lewaju iwọde lọ tako itusilẹ akẹgbẹ rẹ to wa lahamọ ọlọpaa ni Panti nilu Eko.

Iyabọ Ojo ṣalaye ọrọ yii ninu fidio kan tose lati ba awọn ololufẹ rẹ sọ loju opo Instagram rẹ.

Osere tiata lobinrin naa ni saaju asiko yii, ohun ti awọn kan gba lero ni lati gba ẹyinkule tu Baba Ijesha silẹ yala nitoripe o jẹ gbajumọ lawujọ ni tabi ọwọ awọn alagbara ati alẹnulọrọ kan wa lẹyin rẹ nigba naa.

O ni ko sẹni to ni ki Baba Ijẹsha maa wa sile o, ohun ti awọn fẹ ni pe wọn ko gbọdọ tu u silẹ lọna ẹburu, ti araye yoo wa maa beere pe nibo lo wa tabi ta lo gba beeli rẹ, lasiko ti ile ẹjọ ba pada sẹnu iṣẹ ni ipinlẹ Eko.

O jẹ ko di mimọ pe, oun ko lee wẹyin wo lori ọrọ naa nitori pe Baba Ijesha gbọdọ jẹjọ fun iwa aitọ to hu si ọmọdebinrin naa.

"Ohun to mu wa lọ si ọdọ awọn ọlọpaa lakọkọ lati gbe ohun wa soke tako beeli Baba Ijesha ni pe, wọn fẹ tu Baba Ijẹṣha silẹ, ki wọn si fi awuruju pa ina ọrọ naa mọ abẹ aṣọ.

Awọn ibeere ti a si bi ọlọpaa nigba naa ni pe, ta lo n paṣẹ yii, ki ni awọn ilana ti ofin n beere fun beeli rẹ nigba naa,'ta lo fẹ gba oniduro rẹ amọ ti a ko ri esi kankan."

Iyabo Ojo ni ohun ti awọn dide fun nigba naa ni pe, bi o ba tilẹ jẹ pe wọn yoo tu Baba Ijesha silẹ, o gbọdọ jẹ ọna to ba ofin mu ni, dipo ọna awuruju to ni wọn kọkọ fẹ fi ṣe nigba naa nitoripe ilumọọka lẹni ti ọrọ kan.

"Ohun to ja ju bayii ni pe wọn n tẹle ilana to yẹ dipo ti ọna irọ ti wọn fẹ lo tẹlẹ."

Iyabọ Ojo tun ṣekilọ fun awọn obi ati alagbatọ lati mojuto awọn ọmọ wọn daradara, lati daabo bo wọn lọwọ awọn agbaaya lọkunrin ati lobinrin ti wọn fi iwa ibajẹ fifi ibalopọ kotọ lọ awọn majesin lawujọ.

O ni ọrọ Baba Ijesha naa ti wa fihan bi awọn eeyan to to n hu iwa aṣemaṣe si ọmọde, awọn afipabanilopọ ati oniwa aitọ sawọn ewe, ṣe pọ si lorilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O wa salaye fun gbogbo awọn to n beere pe ṣe oun yoo ṣi ta ile oun, fi ṣe ẹjọ lori ọrọ Baba Ijesha pe, oun ṣetan lati ta ile oun.

Iyabo ni bi wọn ba fẹ ra ile naa nitori pe oniṣowo to fẹran owo loun, oun si setan ati ta ile naa to ba ti jẹ iye to tọna ni wọn ba fẹ raa.