Baba Ijesha: Ohun tí a mọ̀ rèé lórí ìròyìn tó jáde pé Iyabo Ojo ti bẹ Yomi Fabiyi padà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Iroyin to gbode kan nsiyi ni pe Iyabo Ojo, ti bẹ Yomi Fabiyi to n ja fun ẹtọ Baba Ijesha ni Panti.

Ṣaaju ni Iyabo Ojo ati Yomi Fabiyi ti n sọrọ sira wọn nitori ọrọ ẹsun ṣiṣe ọmọde jakujaku ti wọn fi kan Olarewaju Omiyinka ni agọ ọlọpaa ni Panti.

Lati bi ọjọ diẹ sẹyin, ni Fabiyi ti n fọnrere lori ayelujara pe Iyabo ati Princess ti leri lati pa Baba Ijẹsha, to ba fi kuro ni ahamọ ọlọpaa.

Ṣugbọn ninu ọrọ kan to kọ si ori Instagram rẹ ni owurọ Ọjọbọ, Ọgbẹni Fabiyi sọ pe Iyabọ ti bẹ oun lori ayelujara Whatsapp.

Botilẹ jẹ pe Fabiyi fi awọn aworan kan sita, to ni o jẹ akọsilẹ ọrọ laarin oun ati Iyabọ.

Ninu aworan naa lo ti han pe 'Iyabo' sọ pe oun ko darukọ Yọmi ninu fidio oun, gbogbo awọn akẹẹgbẹ oun ni oun n ba wi.Kí ló mú Yomi Fabiyi àti Iyabo Ojo máa sá aṣọ ìdọ̀tí ara wọn síta?

Ko pẹ ti eyi jade sita, ni Iyabọ naa fesi, to ni kii ṣe ọrọ̀ nipa ẹbẹ ti oun bẹ nikan lo yẹ ki Yomi fi sita faye ri.

Iyabo ba kuku lọ ya fọto gboogbo ọrọ wọn lori Whatssap si ori ayelujara rẹ to si ni oun ko ba Yomi ta eyin rara, ki gbogbo aye wo awọn ọrọ to jẹyọ laarin awọn mejeji ni kọkọ.

Labẹ awọn aworan naa lo tun kọ ọrọ si pe o ya oun l'ẹnu pe Fabiyi ṣi n sọ isọkusọ nipa ọmọ ti wọn ni Baba Ijẹsha ba lopọ, lẹyin to pari ija pẹlu oun.

Fabiyi sọ pe Iyabọ ti jẹwọ, to si tun bẹbẹ fun bo ṣe mu ki awọn eeyan o bú oun lori ayelujara.

Yoruba bọ wọn ni a n j'Ekuru ọrọ ko tan lawo, iwọ tun n gbọn ọwọ rẹ sii. lo difa fun ọrọ ẹsun ti wọn fi kan gbajugbaja oṣere apanilẹrin Olanrewaju Omiyinka ti ọpọ mọ si Baba Ijesha lori ifipabọmọde lo.

Amọ kaka ki ewe agbọn dẹ lori ọrọ yii niṣe lo n pele sii loju ati lọkan awọn eeyan torii bi awọn akẹgbẹ Baba Ijesha meji ṣe gbe ọrọ naa ka ori ti wọn si n gba a bi ẹni n gba igba ọti.

Bẹẹ gan-an ni ọrọ ri laarin oṣere Nollywood meji, Yomi Fabiyi ati Iyabọ Ojo.

Eyi ko ṣẹyin ija ori ayelujara to ti n waye laarin awọn mejeeji lati bi ọsẹ mẹta ti ọwọ titẹ akẹẹgbẹ wọn, Omiyinka James Baba Ijesha, fun ẹsun ifipabanilopọ.

Ọjọru ni Iyabo Ojo tun fi lẹta kan sita lori ayelujara, eyi to ṣafihan pe o ti pe Yọmi ni ẹjọ fun ẹsun ibanilorukọ jẹ.

Miliọnu lọna ọgọrun Naira si lo sọ pe oun yoo gba lọwọ Yọmi gẹgẹ bi owo itanran.

Kí ló mú Yomi Fabiyi àti Iyabo Ojo máa sá aṣọ ìdọ̀tí ara wọn síta?

Iyabo Ojo àti Yomi Fabiyi tú ara wọn fó lórí ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀

Fabiyi ni oun n tiraka lati ko ara oun ni ijanu, ki oun ma ba kọlu Iyabọ Ojo.

"Iyabọ, mo fẹran rẹ pupọ, mo si n tiraka lati ko ara mi ni ijanu, ki n ma kọlu ọ.

"Ti mo ba gba ẹ mu, wa a ri were."

Ọgbẹni Fabiyi ṣalaye pe ẹjẹ apapọ ọkunrin ati obinrin ni oun, eyi to sọ oun di akanda ẹda.

O ni ki Iyabọ o ma ṣe jẹ ki ẹnikẹni ti i, nitori pe to ba kọja aaye rẹ, oun yoo pa oju da si.

Yomi ti pe akọle sinima tuntun to fẹ gbe jade ni "Ọkọ Iyabọ" to si ni awọn to ba gbagbọ pe oun le ṣe e ki wọn o bẹrẹ si ni rọ owo wọle si asunwọn owo oun.

Iyabo Ojo pé Yomi Fabiyi lẹ́jọ́, ìdí abájọ rèé

Yoruba maa n gbadura pe ki Eledua maa jẹ ki wọn fi ọrọ lọrọ gba wa lẹnu.

Awuyewuye lori ọrọ osẹre tiata Yoruba, James Olanrewaju Omiyinka ti ọpọ mọ si Baba Ijesha ko ti tan sibẹ o.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ero awọn akẹgbẹ Baba Ijesha sọtọtọ lati ti ọrọ naa ti ṣẹlẹ.

Eyi lo mu ki Iyabo Ojo ati Yomi Fabiyi tako ara wọn lori ọrọ naa.

Bi Iyabo ṣe duro lori ẹsẹ rẹ pe idajọ ododo gbọdọ waye lori ọrọ naa ni Yomi naa n sọ pe ki awọn eeyan maa tii da Baba Ijesha lẹjọ.

Koda, Yomi tun ṣe iwọde pẹlu awọn eeyan kan l'Ọjọru lati tako bi awọn ọlọpaa ko ṣe ti gba ki wọn gba beeli Baba Ijesha ni ahamọ to wa.

Ṣugbọn tuntun lori ọrọ naa bayii ni pe Iyabo ti gbe Yomi lọ si ileẹjọ lori ẹsun ibanilorukọ jẹ.

Ninu iwe ipẹjọ ti agbẹjọro Iyabo fi ṣọwọ si Yomi, o ṣalaye nibẹ pe Yomi gbọdọ tọrọ aforijin.

Bakan naa ni agbẹjọro Iyabo sọ pe Yomi ni lati san owo itanran fun awọn ọrọ kobakungbe ti o sọ si Iyabo.

Agbẹjọro Iyabo tun sọ pe Yomi n gbe beba ti orukọ Iyabo wa nibẹ pẹlu oriṣiiriṣii ẹsun to fi kan Iyabo.

Agbẹjọro Iyabo ni gbogbo ẹsun ti Yomi fi kan Iyabo, ko si otitọ kankan ninu rẹ.

O ni arosọ, irọ ati eke ni gbogbo ohun ti Yomi n sọ lati le ba orukọ Iyabo jẹ ni gbogbo rẹ.

Yomi naa gbe soju opo Instagram rẹ pe Iyabo Ojo ati Princess ṣeleri pe awọn yoo pa Baba Ijesha ti wọn ba gba beeli rẹ

Baba Ijesha si wa ni atimọle awọn ọlọpaa niluu Eko lori ẹsun ifipabanilopọ pẹlu ọmọdebinrin adẹrinpoṣonu, Princess.