Eid al-fitr 2021: Àwọn míì ṣọdún ìtúnu àwẹ̀ lónìí Ọjọ́bọ̀ n'Ibadan lẹ́yìn táwọn kan kírun lánàá

Ọpọlọpọ awọn eekan ninu ọṣelu ati awọn Musulumi to gba awẹ di ọgbọn ọjọ lo pejupesẹ si awọn ọkanojọkan Yidi nilu Ibadan ati jakejado ipinlẹ Ọyọ lati ṣe ajọyọ ọdun itunu awẹ lonii.

Lara awọn eeyan pataki to kopa nibi irun ọdun itunu awẹ ni Mọṣalaṣi nla to n bẹ ninu ọgba fasiti ilẹ Ibadan ni Gomina tẹlẹri nipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Rasheed Ladoja, Sẹnetọ aarin gbungbun Ọyọ, Teslim Folarin.

Sẹnetọ agbegbe ariwa Ọyọ, Abdulfatai Buhari, Kọmisana tẹlẹri fun ọrọ ayika nipinlẹ Ọyọ, Oloye Lowo Obisesan ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Irun ọdun itunu awẹ waye lonii lẹyin ti Imam agba ilẹ Ibadan, Sheik Agbọtọmọkekere ko awọn Musulumi kan ṣodi n'Ibadan lati ṣe adua itunu awẹ l'Ọjọru.

Botilẹ jẹ wi pe irun naa waye ni Yidi to n bẹ ni agbegbe Agodi nilu Ibadan, awọn eeyan to kopa nibẹ ko pọ tọ iye awọn eeyan to kirun ọdun itunu.

Wọnyii ni aworan bi ọdun itunu awẹ ṣe lọ ni ilu Ibadan.