National Grid collapse: Òpó iná ẹ̀lẹ́ńtíríkì daṣẹ́rú, ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà wà lókùnkùn

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Opo apapọ ina ẹlẹntiriki lorilẹ-ede Naijiria ti a mọ si National grids ti dẹnukọlẹ eti si ti sọ awọn apakan orilẹ-ede Naijiria sinu okunkun birimi.

Ileeṣẹ to n pin ina ẹlẹntiriki lorilẹede Naijiria, TCN ṣalaye irinṣẹ ipinna lorilẹ-ede Naijiria lo ṣa dede dẹnukọlẹ ni nnkan bii agogo mọkanla kọja iṣẹju kan owurọ Ọjọru.

Awọn ilẹsẹ ina bii EkoWlectric, Ikeja Electric ati Kaduna Electric ni tiwọn ti jẹwọ pe kini naa ti ba awọn ati pe awọn ko ri ina fun araalu bayii.

Ajọ TCN ni lọgan lawọn bẹrẹ atunṣe ati irapada awọn irinṣẹ ipinna to dẹnu kọlẹ naa ni nnkan bii agogo mọkanla kọja iṣẹju mọkandinlọgbọn owurọ.

Ajọ naa ni bi a ṣe n sọrọ yii, ina ọba ti n pada sawọn agbegbe kan kaakiri ni Naijiria.

Ninu iforowerọ pẹlu BBC, ajọ amunawa ilu Ikeja, Ikeja Electric ni ọda ina lati pin fun araalu da awọn ni nnkan bii agogomọkanla aarọ ki wọn to rii gba pada ni nnkan bii agogo kan ọsan ku iṣẹ kẹrindinlogun.

Loju opo Twitter rẹ, ajọ amunawa ilu Kaduna kọọ wi pe:

O ni" "Ẹyin onibara wa, o ba wa lọkan jẹ pupọ lati sọ fun yin pe aisi ina ọba to n waye lọwọ yii l'awọnipinlẹ to wa labẹ isakoso wa bii Sokoto,kaduna, Kebbi, Zamfara.

Ko ṣẹyin bi oju opo ipese ina apapọ orile-ede Naijiria.

Laipẹ laijinna ti iṣẹ ba ti pari lori atunṣe naa ni ina ọba yoo maa de ni awọn agbegbe bi o ti yẹ.