Sarah Dosekun, Obìnrin ẹni ọdún 67 di àwátì lásìkò tó ń lọ sí ìṣọ́ òru ní ìpínlẹ̀ Ogun

Obìnrin ẹni ọdún 67 di àwátì ní ìpínlẹ Ogun lẹ́yìn tó dágbére ìṣọ́ òru nílé.

Awọn ẹbi obinrin oniṣowo kan, Sarah Dosekun, ti ko sinu hilahilo bayii ni bi obinrin naa ṣe dede di awati lẹyin to dagbere nile pe oun n lọ si iṣọ oru.

Iroyin ni obinrin ọhun wọ ọkọ lati agbegbe Mowe, ni opopna marosẹ Eko si Ibadan to si dagbere pe oun n lọ si ijọ alaṣọ funfun kan to wa ni agbegbe Ogba, nipinlẹ Eko.

Ọmọ obinrin naa, Janet ṣalaye fun awọn akọroyin pe igba ti oun gburo iya kẹyin ni asiko to de ibudokọ Asese, eyii to sun mọ ala ipinlẹ Ogun ati Eko.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, "O kuro nile ni nnkan bii aago meje kọja iṣẹju mẹẹdogun aṣalẹ lọ si iṣọ oru, nigba to di aago mẹjọ ku iṣẹju diẹ ni wọn pe wa pe awọn ti de Asese, lẹyin naa ni ẹrọ ibaraẹnisọrọ wọn ko lọ mọ ti a ko si gburo wọn mọ titi di akoko yii."

Janet ni: "Auntie mi kan to ti wa nile ijọsin naa ṣaaju wọn tilẹ pe aago wọn titi, bẹẹ si ni ko lọ."

O ni awọn ti lọ fi ọrọ naa to ileeṣẹ ọlọpaa ẹka ti Mowe leti.

Janet ni "A lọ si agọ ọlọpaa to wa ni Mowe, wọn ni ka pada wa lẹyin wakati mẹrinlelogun.

Lẹyin naa ni a tun lọ si agọ ọlọpaa ti Warewa boya wọn wa lara awọn ti wọn faragba ninu ijamba ọkọ to waye lori afara Long Bridge ṣugbọn pabo ni gbogbo akitiyan wa jasi."

Ọmọ obinrin naa fikun pe igbagbọn awọn ẹbi ni pe ko ba ijamba ọkọ lọ, ko si si ẹni kankan to tii kan si awọn pe boya awọn ti ji obinrin ọhun gbe.

Nigba ti awọn akọroyin kan si agbenusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi, o sọ pe awọn ti gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun awọn si ti bẹrẹ iwadii.

Oyeyemi ni gbogbo ẹka ileeṣẹ awọn ni awọn ti ta lolobo to fi mọ olu ileeṣẹ naa ni Abeokuta, o fi kun pe o ṣeeṣe ki obinrin ọhun ti kuro ni ala ipinlẹ Ogun ko to di pe o poora.