Davido, Yomi Fabiyi and Baba Ijesha: Davido sí Yomi Fabiyi: Mùmú ni ẹ́

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajugbaja ọdọ olorin ọmọ Naijiria ti bu ẹnu atẹ lu bi oṣere Yomi Fabiyi ṣe farahan nibi Ifẹhonu han to ṣe lanaa.

Yomi Fabiyi ṣe iwọde naa nitori akẹgbẹ rẹ, Olarewaju Omiyinka ti ọpọ mọ si Baba Ijesha ti wọn ti mọ ahamọ ọlọpaa fun ẹsun ifipaba ọmọde lopọ atawọn ẹsun mii to rọ mọ ọ.

David Adeleke ti ọpọ mọ si Davido OBO fi fidio ifẹhonuhan Yomi Fabiyi sita to si kọ akọle eebu le e lori pe "mumu ni ẹ tori o ko wọ ibomu".

Davido n tọka si pe ninu gbogbo awọn ti wọn jọ n wọde, Yomi Fabiyi nikan ni ko wọ ibomu.

Wiwọ ibomu jẹ aṣẹ ijọba Naijiria paapaa lasiko yii ti wọn ṣẹ tun ni iṣi ati ẹda Coronavirus mii ti rapala wọ Naijiria.

Yomi Fabiyi n ja fun pe wọn ti jẹ ki Olanrewaju Omiyinka iyẹn Baba Ijesha pẹ latimọle ju lai tii gbe e lọ ile ijọ tori wọn wa ni iyanṣẹlodi, o ni o yẹ ki wọn da a silẹ pẹlu beeli.

Ẹwẹ loju opo Twitter olorin Davido, awọn to lu Davido lọgọ ẹnu tako pe o pe Yomi ni Mumu wa: