You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Baba Ijesha case: Yomi Fabiyi ní òun ṣetán láti pàdánù gbogbo dúkìá òun sórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn
Pẹlu bi awọn eeyan ti ṣe n reti itusilẹ gbajumọ oṣere, Baba Ijesha, lẹyin ti adajọ gba beeli rẹ, ọkan lara awọn akẹgbẹ rẹ to ja fitafita fun gbigba oniduro rẹ, Ọgbẹni Yọmi Fabiyi tun ti sọrọ soke.
Yomi Fabiyi lasiko yii, ti wa fi ohun ranṣẹ si gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu pe ko ri daju pe ibọwọ fofin ati ẹtọ ọmọniyan tubọ gbẹrẹgẹjigẹ nipinlẹ Eko.
Ninu ọrọ kan to kọ soju opo Instagram rẹ, Yọmi Fabiyi kan sara si Gomina Sanwo-Olu fun gbigbe ibọwọ fun ofin ati ẹtọ ọmọniyan soke ni ipinlẹ Eko.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìrọ́ lẹ pa, ìbò ìjọba ìbílẹ̀ kò ní wáyé l‘Oyo ní Sátidé - APC fárígá
- Èèmọ̀ wọ̀lú! Àwọn jàndùkú jí Adájọ́ gbé lọ nínú kóòtù lọ́sàn án gangan
- Ẹ̀yin tí ẹ sọ pé irọ ni mo ń pa bayii ni yoo ri fún yín
- Ahmed Isah, Ordinary President, ṣàlàyé ìdí tó fí dá ìgbájú-ìgbámú bó obìnrin lórí afẹfẹ
- Ìwà ọ̀daràn yóò dínkù tí ìjoba bá bẹ̀rẹ̀ sí ní pa àwọn ọ̀daràn tí wọ́n bá mú- Oluwo ti Iwo
- NLC fòpin sí ìyanṣẹ́lódì ní Kaduna lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rin
- Sanwó ìtúsílẹ̀ fún àjínígbé, kí ó lọ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ẹ̀dógún- Ilé ìgbìmọ̀ asòfin
- Wo ǹkan mẹ́jọ tí o kò ma nípa Abiidemi Rufai, amúgbálẹ́gbẹ̀ Gómìnà Dapo Abiodun tí wọ́n mú ní America
- Ọwọ́ tẹ àwọn afurasí afipábánilòpọ̀ 206 l'Eko
Fabiyi ni "ara awọn afihan iṣejọba awarawa tootọ ati itanna iṣejọba igbalode ti ipinlẹ tabi orilẹede to fẹ goke agba nilo ree."
Yọmi Fabiyi, to ni oun ko kabamọ pe oun dibo fun Sanwo-Olu, wa rọ gomina ipinlẹ Eko naa lati tẹẹ mọ awọn ileeṣẹ eto iroyin ati eto idajọ ni ipinlẹ Eko leti, nipa pataki idanilẹkọ nipa ẹtọ ọmọniyan lawọn ileewe gbogbo.
Bakan naa lo tun pe fun agbekalẹ abẹwo oloṣooṣu sawọn ahamọ ọlọpaa gbogbo, ki wọn si maa fi iya to ba tọ jẹ awọn ọga ọlọpaa gbogbo ati olori ẹka ọlọpaa, to ba tẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ.
O fi kun un pe, oun ṣetan lati padanu gbogbo ohun ti oun ni lori ibọwọ fun ẹtọ ọmọniyan lorilẹede Naijiria.
Wo bí ìwọ́de Yomi Fabiyi nítorí ọ̀rọ̀ Baba Ijẹsha to wa ni àhámọ̀ ọlapàá ṣe n lọ nílùú Eko
Yoruba ma n sọ pe ka sọrọ ka ba bẹ ẹ, ni iyi ọmọ eniyan.
Bẹẹ gan-an ni oṣerekunrin,Yomi Fabiyi ṣe ni owurọ Ọjọru, ọjọ kejila, oṣu Karun-un, pẹlu bo ṣe mu ipinnu rẹ lati ṣe iwọde nitori ọrọ Baba Ijẹsha ṣẹ.
Lati bi ọsẹ kan sẹyin ni Fabiyi ti n polongo lori ayelujara pe, oun yoo ṣe iwọde tako bi awọn ọlọpaa ko ṣe gba beeli akẹẹgbẹ rẹ.
Ẹsun fifi ipa ba majesin lopọ ni wọn fi kan Baba Ijẹsha.
Ninu awọn ikede ti Yomi Fabiyi ti n sẹ sẹyin lori iwọde naa lo ti n sọ pe o tako ofin Naijiria ati ẹtọ ọmọniyan, bi afurasi naa si ṣe wa ni ahamọ ọlọpaa.
O ni alakalẹ ofin ni pe afurasi ko gbọdọ kọja wakati mejidinlaadọta lọ ni atimọle, fun ẹsun ti wọn le gba beeli rẹ .
Botilẹ jẹ pe aago mẹwaa owurọ ni Ọgbẹni Fabiyi kede pe ki awọn to fẹ ẹ darapọ mọ iwọde naa pade oun ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n wadii ẹsun ọdaran, to wa ni Panti, Yaba, nilu Eko, ni nkan bi aago mẹjọ ni oun fun'ra rẹ ti bẹrẹ iwọde.
Ninu fidio kan to fi sori ayeluajara, ni a ti ri Yomi, ati gende ọkunrin bi i mẹrin, ti wọn jọ kọwọrin lọ sibẹ.
Yomi ti o n fun'ra rẹ wọ aṣọ dudu, ibori dudu lo sọ ọrọ apilẹsọ pe o yẹ ki awọn ọdọ Naijiria dide fun nkan to tọ.
O ni kii ṣe pe o n sọ pe ki wọn o tu Baba Ijẹsha silẹ, tabi ma gbe e lọ sile ẹjọ.
"Nkan ti mo n ja fun ni pe ki wọn o gba beeli rẹ, nitori pe wọn n fi akoko rẹ ṣofo ni ahamọ."
Oriṣiriṣi akọle si ni wọn gbe dani.
Ninu awọn akọle naa ni wọn kọ awọn ọrọ si lati fi ẹhonu wọn han pe 'iwa titẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ ni awọn ọlọpaa n hu'.
Awọn akọle miran n fi ẹsun kan pe awọn kan ti leri lati pa Baba Ijẹsha to ba fi kuro ni ahamọ.
Bi awọn ọmọ ẹyin Yomi ṣe n na awọn akọle naa soke ni kọọkan, l'oun naa n kà to si n ṣe alaye l'ẹkunrẹrẹ lori nkan ti awọn akọle naa duro fun.