You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Baba Ijesha: Ọ̀rọ̀ àti ìwà Yomi Fabiyi lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kù díẹ̀ káàtó
Damilola Adekoya tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Princess Comedian, tí tún ké sí gbogbo ènìyàn láti ma wá ìdí ohun gbogbo dájú láti di òkodoro inú rẹ̀ mú.
Ninu fidio mii to tun se jade, ni Princess ti sàlàyé bí ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́ gan láti ibẹ̀rẹ̀ wá, paapaa nitori àwọn eeyan tó n sọ̀rọ̀ pé "Báwo ni ènìyàn yóò ṣe má bá ọmọ sùn lábẹ́ òrúlẹ̀ òun fún ọdún méje, tí òun kò mọ̀?"
Adekoya ni, kò sí òtítọ́ kankan nínú ọ̀rọ̀ yìí nítorí kò sí ìgbà kankan tí òun sọ pé Baba Ijesha ń bá ọmọ náà sùn fún ọdún méjè.
- Àlàyée Fídíò bí Baba Ijesha ṣe ṣe aṣamaṣe pẹ̀lú ọmọ Princess rèé
- Ìwọ́de alágbára ń bọ̀ l‘Eko láàrọ́ òní láti tako béèlì Baba Ijesha
- Ẹ̀yin tẹ tako béèlì Baba Ijesha, ẹ̀ ń palá sẹ́nu ni - Yomi Fabiyi
- Iyabo Ojo gbé fídíò jáde nípa bí ọwọ́ ṣe tẹ Baba Ijesha
- Ẹgbẹ́ òṣèré tíátà TAMPAN sọ̀rọ̀ sókè lórí ẹ̀ṣùn bíbá ọmọdé lòpọ̀ tí wọn fi kan Baba Ijesha
- Gbogbo abiyamọ aye ẹ gba wá, wọ́n ti fẹ́ tú Baba Ijesha silẹ - Iyabo Ojo figbe ta
- Ipa tí Fathia Balogun kó nínú bí mo ṣe dèèyàn lágbo òṣèré fíìmù Yorùba rèé - Baba Ijesha
- Orí yọ ẹ́ o Baba Ijesha tí mi ò rí fídíò èpè tí wọ́n ní ò ń ṣẹ́, ǹkan tí mi ò bá ṣe fún ẹ... - Iyabo Ojo
Àwọn tó n sọ pé "báwo ni òun ko ṣe mọ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ láti odidi ọdún méje ṣẹ́yìn, mó fẹ́ fi àsìkò yìí sọ fún yín pé, ọjọ́ tí ọ̀rọ̀ yìí ti ṣẹlẹ̀ ni mo ti mọ̀, sùgbọ́n kò sí ẹ̀rí."
Ó wa rọ gbogbo ènìyàn pe kí wọ́n ye tan irọ́ ká lórí ọ̀rọ̀ yìí nítori aburú tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣe fún ọmọ kekere náà ti pọ jù.
O ni àimọye àkọsílẹ̀ ni àwọn ọlọ́pàá ti ni ki ọmọ náà maa kọ, to si ni láti ọjọ́ àkọ́kọ́ lo ti sọ pe Baba Ijesha ba òun sùn.
Bákan náà ni Princess tun sọ pé ọ̀pọ̀ lo n bèèrè fún ẹri bíi fọ́nran tó fihàn pé Baba Ijesha bá ọmọ náà sùn lóòtọ́.
"Ibèérè mi ni pé, gẹ́gẹ́ bi àgbàlagba, ṣe ẹ le gbe fótò ibi ti ẹyin àti olólùfẹ́ yín ti n ní nǹkan pọ̀ sita, báwo ni ẹ se wá n réti ki ń gbe ti ọmọde jáde"
Gbajúgbajà adẹ́rìnpòṣónú náà tun bẹnu àtẹ́ lu bí ọ̀kan nínú akẹgbẹ́ rẹ̀, Yomi Fabiyi ṣe n ṣe lórí ọ̀rọ̀ náà, ó ni ìwà to n hu àti àwọn ọ̀rọ̀ tó n sọ, jọ tí ẹni ti ko ronú jinlẹ̀ kí o tó máa sọ̀rọ̀.
Baba Ijesha sọ fun mi pe nigba akọkọ ti isẹlẹ naa waye, atọ oun ko le di ọmọ
Adekoya ni baba Ijesha tún ń sọ fún òun láìpẹ́ yìí pé, ńigbà tí òun 'se lákọ̀kọ́ tí ọmọ náà wà ni ọdún méje, ààtọ òun kò le dọmọ, "ọ̀rọ̀ yìí kò ṣe máá gbọ́ sétí."
Ó ni kò tọ̀nà kí àwọn ènìyàn máa wá àwáwí fún ǹkan tí kò dára, nǹkan ti kò dára, kò dára ni.
"Báwo ni mó ṣe fẹ́ gbé fọ́nran ibi ti àgbàlàgbà tí n bá ọmọ kékeré sùn fún odidi ọgbọ̀n ìṣẹ́jú"
Nínú ọ̀rọ̀ tírẹ̀, Iyabo Ojo ní ìdí tí àwọn fi ju fọ́nran ibi ti Baba Ijesha ti jẹwọ pé òun ṣe ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan oun ni pé, Yomi Fabiyi sọ fún òun pé, òun bẹ Baba Ijebu wò, ó sí sọ fún òun pé òun kò ṣe.
Nítorí rẹ̀ ni mo ṣe sọ fún Princess ko gbe fọ́nran náà síta.
Àwọn òṣèré méjèèjì rọ àwón òbí láti jí gìrì sí ojúṣe wọ́n nítorí ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n fọkan tan lábẹ́ òrùlé wọ́n, gan ló má n ṣe aburu pẹ̀lú àwọn ọmọbinrin àti ọkùnrin wọn.