Oyo LG Polls: Alága OYSIEC ní APC fẹ́ sọ òun lẹ́nu nípa ìṣúnsíwájú ìbò tó ń bèèrè fún

Awọn tọrọ kan nipa idibo ijọba ibilẹ to n bọ lọna nipinlẹ Oyo, ti n tako ara wọn nipa idibo naa ti yoo waye ni ọjọ Satide.

Eyi ko si ṣẹyin bi ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Oyo ṣe sọ pe ki ajọ eleto idibo OYSIEC, sun ọjọ idibo siwaju.

Alagba fẹgbẹ APC nipinlẹ Oyo, Oloye Akin Oke ti sọ fun awọn akọroyin ni Ọjọru pe, awọn fẹ isunsiwaju naa ki awọn ọmọ ẹgbẹ awọn le kopa ninu eto idibo naa.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Oke ni gbogbo eeyan lo mọ wi pe awọn n ṣe ẹjọ lọwọ lasiko to yẹ ki awọn gbaradi feto idibo naa, nitori naa, idibo abẹle ko le waye lasiko igbẹjọ.

Oke ni ọrọ ofin ati ilana ofin lọrọ to wa nilẹ yii tori naa, o yẹ ki ajọ OYSIEC fi igbalaye kalẹ fawọn lati gbaradi de idibo.

''Gẹgẹ bi ẹni to n fẹ alaafia, a kọ iwe si OYSIEC lori idi to fi yẹ ki wọn sun ọjọ ibo siwaju, alaafia ni awa n wa''

O ni amọ o ṣe ni laanu pe ajọ OYSIEC ti adari rẹ jẹ amofin, taku pe awọn yoo tẹsiwaju lati ṣeto idibo naa.

Amọ ṣa, o ni ẹgbẹ awọn yoo ''tẹle gbogbo ilana ofin lati le gba ẹtọ awọn bo ṣe yẹ''

Kini ajọ olominira eleto idibo OYSIEC sọ

Ninu ifọrọwerọ pẹlu alaga ajọ OYSIEC nipinlẹ Oyo, Isiaka Abiola Olagunju, o sọ fun BBC pe bi ẹni pe ẹgbẹ APC fẹ sọ awọn lẹnu ni pẹlu isunsiwaju eto idibo ti wọn n beere fun.

Olagunju ni ọjọ ti pẹ tawọn ti fi to APC leti wi pe idibo yoo waye, ṣugbọn wọn ko tete sọ pe awọn ko ni le kopa lọjọ ti wọn la kalẹ.

''Ni agbara Olorun, a ti se igbaradi, awọn to fẹ gba ohun eelo fun idibo naa ti wa ni ọfisi wa, a si ti gbe ilana jade saaju pe idibo yoo waye lọjọ Satide.''

Oke ni loore koore lawọn n ṣe ipade pẹlu APC ati awọn ẹgbẹ yoku lori eto idibo yii ati pe APC ko foju han pe awọn ko ni kopa ninu idibo.

O tẹsiwaju pe, bawọn tiẹ fẹ sun ọjọ siwaju fun APC, awọn ẹgbẹ oselu mẹtadinlogun to ku ti wọn fẹ kopa ninu idibo ti sọ pe awọn ko le faramọ.

''Ohun ti ofin sọ ko ruju nipa idibo. A ko le tori ẹgbẹ kan, wa maa da awọn ẹgbẹ yoku duro nitori pe wọn lawọn fẹ gbaradi.''

Ohun ti ko ba dun mọ wa ni ki APC kopa, ki ẹsin wọn baa le han si araalu - PDP

Ẹgbẹ Oṣelu PDP naa ti sọ si ọrọ eto idibo ijọba ibilẹ to n mu awuyewuye dani nipinlẹ Oyo.

Akọwe ipolongo fẹgbẹ oselu PDP, onimọ ẹrọ Akeem Olatunji ni ki baa dun mọ awọn, ki APC kopa ninu idibo yii lọjọ Satide.

O ni idi ni pe araalu yoo lanfaani lati ri ẹsin wọn bi wọn ba kopa, ti yoo si han si wọn pe ilu ko fẹ wọn.

''Erongba wọn ni pe wọn yoo ri idajọ ile ẹjọ ra ṣugbọn adajọ ja wọn kulẹ.

Ni bayi ti wọn si ti ri wi pe awọn ko ni le kọ esi idibo bi ti atẹyinwa, lo mu ki wọn ni awọn ko ni kopa''

Olatunji wa gboṣuba kare fun ajọ OYSIEC lori ipinnu rẹ lati tẹsiwaju pẹlu eto idibo naa, to si ni awọn ni igbagbọ pe idibo ti ko lẹja n bakan ninu ni wọn yoo seto lọjọ Satide.

Ìrọ́ lẹ pa, ìbò ìjọba ìbílẹ̀ kò ní wáyé l'Oyo ní Sátidé - APC fárígá

Ẹgbẹ oṣelu APC ti fi ẹsun kan Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde pe o fẹ doju eto oṣelu tiwantiwa bolẹ nipinlẹ Ọyọ.

Ẹgbẹ oṣelu APC tun fẹsun kan gomina Seyi Makinde wipe o lo owo ilu basubasu lati ṣe idibo ti ileẹjọ ti fagile ni awọn ijọba ibilẹ.

Alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọyọ, Oloye Akin Oke lo sọ bẹẹ nibi apero ẹgbẹ ati awọn akọroyin ti wọn se nilu Ibadan.

Oke ni Gomina Makinde pẹlu ajọṣepọ ajọ eleto idibo nipinlẹ Oyo, OYSIEC n ṣiṣẹ pọ lati doju eto oṣelu tiwantiwa bolẹ nipinlẹ naa.

O salaye pe eyi ri bẹẹ nitori bi wọn fẹ ṣe eto idibo ijọba ibilẹ ni lọjọ Satide ọtunla lai si ẹgbẹ oṣelu APC ninu awọn ti yoo dije dupo.

O ni o ṣe ni laanu wi pe ẹgbẹ oṣelu PDP ati OYSIEC yọ awọn kuro ninu awọn ẹgbẹ ti yoo kopa ninu eto idibo ijọ̣ba ipinlẹ naa.

''Ẹgbẹ oṣelu APC ni awọn alaga ijọba ibilẹ to bori ninu idibo ijọba ibilẹ to waye ni ọdun 2018 ti wa, ti ileẹjọ si paṣẹ wi pe yiyọ wọn nipo ko ba ofin mu.

Bakan naa ni iye owo ti Ajọ eleto idibo OYSIEC ni ki awọn oludije ma a san , to jẹ N250,000 ati N100,000 lati dije dupo alaga ati councilor ko ba ofin mu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Igbesẹ ijọba PDP labẹ aṣẹ Makinde yii ko ba ofin mu, nitori naa wọn gbọdọ fi aye silẹ fun awọn ẹgbẹ oṣelu to ku lati ṣe iforukọsilẹ.''

Alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọyọ naa ni awọn lero wi pe ijọba Makinde yoo tun ero rẹ pa lori idibo ijọba ibilẹ ti yoo waye ni Ọjọ Satide.

Amọ, Oloye Oke ni ti wọn ko ba da eto idibo ijọba ibilẹ naa duro, awọn n gba ileẹjọ lọ.

Wọn wa rọ Adajọ Agba nipinlẹ Ọyọ lati dasi ẹjọ ti wọn pe tako eto idibo ijọba ibilẹ naa, ki idajọ otitọ le jọba ni kiakia.