You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Biola Fowosere sàlàyé ìdí tó fi n domilójú pòròpòrò ni ìtà gbangba
Biola Fowosere ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Ewatomilola Asake ti ke gbàjare sí gbogbo ọmọ Nàìjíríà láti gbà òun lọ́wọ́ àwọn tó n já sọ́sbù rẹ̀ lójoojúmọ.
Ojú òpó Instagram rẹ̀ ló tí ń dòmí lójú pòròpò láti sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀.
Lásìkò tó n bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ ló ti sàlàyé pé ìgbà kẹta rèé tí wọ́n já sọ́ọ̀bù òun, àti pé níwòyí ọdún tó kọjá ni wọ́n já sọ́ọ̀bù tí òun tún gbà.
Fowosere ni: "Osù mẹ́ta sẹ̀yin ni mo sí sọ́ọ̀bù yìí tí wọ́n tún wa ji kó yìí"
Gbogbo bí wọ́n ṣe n ko, tí mo bá ti lọ sọ fún ọlọ́paàá, wọ́n a wá wòó lẹ́yìn náà mí kò ni gba nǹkan kan"
" Ní ọdún tó kọjá, wọ́n ji aṣọ tó tó Mílíọ̀nù kan àbọ̀ náírà sùgbọ́n títí dí òní mí o rí nǹkan kan"
Ó ní àwọn ènìyànn mííràn ní irọ́ ni mò n pa, sùgbọ́n mí o gbàdúrà kí ó ṣẹlẹ̀ sí ẹnikkẹni
Gbájugbajà òṣèrè náà fi kun pé gbogbo ènìyàn tó bá n gbé àgbègbè Iwó ló mọ̀ pé a má n ran àwọn opó lọ́wọ́ ti a wọ́n sì tun máa n rọgunun sápa wọn.
Obìnrin náà ni oùn kò rí irú ǹkàn tó ṣẹlẹ̀ ni sọ̀bù òun rí, " Wọ́n já sọ́ọ̀bù, wọ́n kọ gbogbo ọjà páta, won gbé ẹrọ amúnáwá rl wọ́n sì tún gbe ẹrọ a mú omi tutu tó ń lò.
" Fridzer ti wọ́n gbé ga to mi lórí ìdúró, #110,000 ni mo ra ni "olówónfowósàànú" èèmèjì ni mo sanwó rẹ̀."
Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó n pè, àti àwọn tó n fi àdúrà ran òun lọ́wọ́ àti àwọn tó fi owó ránṣẹ́.