James Ibori loot, Abubakar Malami, Nigeria: Nàìjíríà ti rí €4.2m gbà padà nínú owó tí Ibori gbé- Malami

Adajo agba fun ile ede Naijiria, Abubakar Malami ti kede fun awon omo Naijiria pe owo tuntun ti wole fun itesiwaju Naijiria,

Owo yii lo ni o jẹ milionu merin owo poun ile okeere to le ni igba €4,214,017.66m.

Malami fidie mule pe owo yii je lara owo ti gomina ipinle Delta nigba kan ri, James Ibori ati awon ebi re ko ló sile okeere tẹlẹ.

Dokita Umar Jibrilu Gwandu to je olubadamoran lori eto iroyin ati ifitonileti si Adajo Malami lo fi ikede naa sita nilu Abuja loni ojo Isegun, ójó kejidinlogun, osu karun un, odun 2021.

Koda, Olubadamoran Umar fidie mule pe owo naa ti wó asunwon Naijiria ni odiwon iye to ye ko je ni owo pasipaaro Naira lodindin.

Malami ni o fowo si ikede naa ni eyi to fidie mule pe Naijiria ti ri owo naa gba pada.

Malami naa lo buwolu iwe adehun ti ti won fi da owo Ibori naa pada si asunwon Naijiria.