End of Ramadan, Id-el-fitr: Ajọ NSCIA ní ààwẹ̀ Ramadan ṣì tẹ̀síwájú dí Ọjọ́ọ̀rú, a kọ̀ tíì rí òṣùpá

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Sultan ti ilu Sokoto ti sọrọ labẹ asia ajọ ẹgbẹ Musulumi ni Naijiria, Alhaji Muhammad Sa'ad Abubakar wi pe aawẹ Ramadan ṣi tẹsiwaju di Ọjọ Kẹtala, Oṣu Karun un, ọdun 2021.

Eyi ko ṣẹyin bi Ajọ Supreme Council for Islamic Affairs (NSCIA) ṣe ni awọn ko i tii ri oṣupa ti yoo fi ipari aawẹ Ramadan han.

Ninu Atẹjade ti wọn fi sita naa ni Ọjọọru naa ni aawẹ yoo di ọgbọn ọjọ ti wọn ti bẹrẹ.

Nitori naa, itunu aawẹ yoo waye ni Ọjọ kẹtala, Oṣu Karun un, ọdun 2021, eyi to jẹ Ọjọ Kini, Oṣu Shawaal, 1442 ninu Calender awọn Musulumi.

Ajọ awọn Musulumi naa gbadura fun awọn Musulumi pe wọn ṣe fi alaafia ati ayọ ṣe ọdun itunu aawẹ naa.

Saaju ni Ajọ NSCIA ṣalaye pe ti wọn ba ri oṣu tuntun lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Ọjọru ni Sultan yoo bawọn akọroyin sọrọ tii ṣe ọjọ kinni oṣu Shawwal.

Bakan naa ni ijọba apapọ kede ọjọ meji gẹgẹ bi ọjọ isinmi fun awọn oṣiṣẹ lati ṣe ayẹyẹ ọdun itunu aawẹ.

Ìjọba àpapọ̀ kéde Òjọ́rú àti Ọjọ́bọ gẹ́gẹ́ bi ísinmi lẹ́nu iṣẹ́

Ijọba apapọ ti kede Ọjọru ọjọ kejila ati Ọjọbọ, ọjọ kẹtala ọjọ kẹtala gẹgẹbi ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ ni Naijiria.

Minisita f'ọrọ abẹrẹ, Raif Arẹgbẹṣọla kede eyi nigba to n ki awọn Musulumi ku oriire ipari awẹ osu Ramadan.

Bakan naa lo ke sawọn ileeṣẹ agbofinro ati ikọ alaabo gbogbo lati jẹ akinkanju ki wọn si dẹkun wahala abo to n koju Naijiria.

O fi kun un pe ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari ṣetan lat dẹkun iwa ipa ati ọdaran gbogbo lati lee mu alaafia to jọju wọ Naijiria.

Sultan Sokoto ní káwọn mùsùlùmí wojú ọ̀run fún oṣù tuntun láti parí àwẹ̀

Sultan ilu Sokoto, Amir-ul Mu'mineen Naijiria, Alhaji Muhammad Sa'ad Abubakar ti sọ fawọn musulumi kaakiri orilẹede Naijiria lati wo oju ọrun lọju Iṣẹgun fun ipari awẹ.

Ọjọ Iṣẹgun yii tii ṣe ọjọ kọkanla oṣu karun un ọdun 2021 lo jẹ oṣu kẹwaa ninu ilana kalẹnda ẹsin islam.

Ti o ba ṣẹlẹ pe oṣu tuntun ko jade lọjẹ Iṣẹgun, awẹ ṣi maa pari lọjọ naa ti ọdun Sallah yoo si tẹlee l'Ọjọru tii ṣe ọjọ kejila oṣu karun un.

Ninu atẹjade ti ajọ NSCIA to n ri si ọrọ ẹsin islam ni Naijiria fi sita, igbakeji akọwe agba ajọ naa, Ọjọgbọn Salisu Shehu kepe awọn musulumi lati feti si awọn ilana lori ipari awẹ.

O ṣalaye ninu atẹjade naa pe ajọ to n ri si wiwa oṣu tuntun ti rọ Sultan pe ọjọ Iṣẹgun ni kawọn musulumi wa lojufo fun oṣu Shawwal to tumọ si ipari awẹ.

Ajọ NSCIA ṣalaye pe ti wọn ba ri oṣu tuntun lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Ọjọru ni Sultan yoo bawọn akọroyin sọrọ tii ṣe ọjọ kinni oṣu Shawwal.

Ọjọgbọn Shehu ni ''ṣugbọn ti wọn ko ba fi le ri oṣu tuntun lọjọ Iṣẹgun, ajẹ wi pe Ọjọ lo maa jẹ ọjọ kinni, oṣu Shawwal niyẹn.'

O ni fun idi eyi, gbogbvo musulumi ni lati maa wo oju ọrun fun oṣu tuntun gẹgẹ bi Amir-ul Mu'mineen Naijiria ṣe sọ.

Bakan naa ni atẹjade ọhun sọ pe ajọ NSCIA labẹ alaṣẹ aarẹ ẹgbẹ naa, Alh. Muhammad Sa'ad Abubakar, CFR, n ki gbogbo mumuni ati mumina ododo ku ọdun itunu awẹ ṣaaju akoko naa.

Ẹgbẹ naa gbadura pe Allah yoo san onikaluku ni ẹsan rere.