Wole Soyinka and Buhari administration: Ìjọba Ààrẹ Buhari ti kùnà, kò le è so ẹ̀yà kankan papọ̀ ní Naijiria

Ọjọgbọn Wọle Soyinka ti ni oun ko gbagbọ wi pe ifimọṣọkan ko le e ṣeeṣe labẹ isakoso aarẹ Muhammadu Buhari lorilẹ-ede Naijiria.

Soyinka ni aarẹ Buhari ati ijọba ti kuna ni ọpọlọpọ ọna, eleyi to ti mu ki iṣẹlẹ ẹlẹyamẹya gbinlẹ si ni Naijiria .

Nibi iwe kika lara iwe meji ti Onkọwe Wole Soyinka kọ, ti o pe akọle rẹ ni 'Trumpism in Academe' ati 'Chronicles of the Happiest People on Earth', ni o ti sọrọ naa.

Gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Imo lo bere ni ọwọ Wole Soyinka, iwe ti wọn le kọ to le e mu ki iṣọkan ati ifọwọsowọpọ pada si orilẹede Naijiria, paapaa laaarin awọn ẹya ni Naijiria.

Soyinka ni ko si iwe arokọ tabi akọsilẹ kankan to le e tun itan Naijiria kọ lati mu iṣọkan gbinlẹ si ni Naijiria.

O ni awọn ogunlende to wa ni awọn ibudo kaakiri ko le e jẹri si pe iṣọkan wa ni orilẹede Naijiria.

''Ki iṣọkan ati igbọraẹniye to le waye ni Naijiria, idajọ otitọ gbọdọ jọba paapaa fun awọn ti wọn n pa lọna aitọ kaakiri ni Naijiria.''

''Nitori naa mi o ni igbagbọ pe aarẹ Buhari le e ṣe ohunkohun nipa iṣọkan lorilẹede Naijiria''

Ọjọgbọn Wole Soyinkas ni o ṣeeni laanu wi pe akoko ti aarẹ Buhari ni lati ṣe atunṣe ifọwọsọwọpọ ni Naijiria ti kọja nitori akoko naa ti kọja.

Amọ o fikun wi pe oun gbagbọ wi pe yoo dara kii Naijiria wa papọ gẹgẹbi ẹyọkan, amọ ijọba gbọdọ ṣe ojuṣe wọn lori eto aabo.