London Mayor: Sadiq Khan, jáwé olúborí lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labor láti máa dári London

Lodun 2016 ni Sadiq Khan kọkọ jawe olubori gẹgẹ bii adari London ni United Kingdom.

Sadiq ni musulumi akọkọ to de ipo adari gẹgẹ bii 'Mayo' ni London ti yoo tun jade lati inu ẹgbẹ oṣelu alatako to jẹ Labour Party.

Igba keji to jawe olubori ninu idibo naa ni eyi ti yoo si tun wa nipo siwaju sii.

Khan foju alatako re ti won jọ dije dupo gbole nigba to ni iwọn idibo ida marunlelaadọta o le meji ninu ọgọ run un 55.2 %

Oun ati alatako rẹ, Shahun Bailey lati ẹgbẹ oselu Conservative Party ni wọn jọ dije dupo naa ni London.