Coronavirus update in Nigeria: Ènìyàn 49 ló tún ṣẹ̀ṣẹ̀ lùgbàdí ààrùn Coronavirus ní Naijiria

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Eniyan mọkandinlaadọta lo tun ṣẹṣẹ lugbadi aarun Coronavirus ni Naijiria ni Ọjọ Aje, Ọjọ Kẹwaa, Oṣu Karun, ọdun 2021.

Ipinlẹ mẹrin bii Abuja, Eko, Enugu ati Oyo ni awọn ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si ti wa.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ to n risi ajakalẹ aarun Coronavirus ni Naijiria, NCDC fi lede ni wọn ti sọ.

Eniyan mẹtadinlọgbọn lo lugbadi aarun naa ni ilu Abuja nigbati eniyan mọkanla ko aarun naa ni ilu Eko.

Bakan naa ni ilu Enugu, eniyan mẹjọ lo ko aarun naa nigba ti eniyan mẹta kagbako rẹ ni ipinlẹ Oyo.

Ni apapọ bayii ni Naijiria, eniyan to le ni ẹgbẹrun lọna marundinlaadọsan, 165,468 lo ti lugbadi aarun naa lorilẹede Naijiria.

Iye eniyan to ti jajabọ lọwọ arun naa ti le ni ẹgbẹrun lọna mẹrindinlọgọjọ.

Amọ, iye eniyan ti aarun Coronavirus ti mu ẹmi wọn lọ ni Naijiria ti le ni ẹgbẹrun meji, 2,065.