You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Katsina mosque kidnap:30 nínú 40 àwọn tí wọ́n jígbé nínú mọ́ṣáláṣí ní Katsina ti gba ìtúsílẹ̀, àráàlú ní irọ́ lọlọ́pàá pa lórí ìtúsílẹ̀ wọn
Ninu mọṣalaṣi ni wọn ti ji awọn eeyan naa gbe lasiko ti wọn n gbadura.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Katsina ri gba ọgbọn ninu ogoji awọn ewyan t'awọn agbebọn ji gbe ninu mosalasi kan ni ijọba ibilẹ Jibiya.
Lasiko tawọn wwyan naa n ṣe adura Tahajjud l'awọn agbebọn naa ji wọn gbe.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa n'ipinle Katsina, Gambo Isah ṣalaye fun BBC pe laarin oru ni iṣẹlẹ naa waye lọjọ Aje nigba tawọn agbebọn naa ṣigun lu mọsalaṣi runt ni Unfuwa Kwata.
- Ìnú ìpayà, ìbẹ̀rú ní a wà nítorí a kò tíì gburò Pásítọ̀ Ìjọ Deeper Life tí wọ́n jígbẹ lọ ni ìlú Akure- Ẹbí
- Àwọn àwòrán láti ibi ètò ìsìnkú olóògbé Dare Adeboye ni Redemption Camp
- Bó ṣe nípasẹ̀ ọkada ni tàbí ọkọ̀ ojú omi tàbí láti inú ihò ilẹ̀, ẹ wá ọ̀nà láti fi Naijiria sílẹ̀- Pasitọ Paul Adefarasin
- Àwọn adigunjalè gbìyànjú àti fọ́ ile olórí àwọn òṣìṣẹ́ lọ́fíìsì ààrẹ.
- Ìjọba dá òfin kónlé-ó-gbélé lórí àjàkálẹ̀ àrùn covid-19 padà
O ni awọn ọlọpaa, awọn ikọ fijilante atawọn araalu bẹrẹ iṣẹ ni kete iroyin nipa iṣẹlẹ naa lo ti kan lu agbami isẹ lori rẹ eleyi ti wọn fi ri ọgbọn ninu wọn gba pada.
O ni igbesẹ ri bẹrẹ lati ṣawari awọn mẹwaa to ku ati pe wọn ko tii le sọ boya ọwọ awọn ajinigbe naa ni wọn ṣi wa tabi wọn ti bọ kuro lọwọ wọn.
Alukoro ọlọpaa Gambo Isah fi kun un pe gbogbo awọn ti wọn gba lọwọ awọn ajinigbepawo naa ni wọn ti pada sọdọ awọn ẹbi wọn.
Amọṣa awọn eeyan ilu naa kan sọ ọ di mimọ fun BBC pe awọn ọlọpaa ko mọ si bi awọn eeyan naa ṣe gba itusilẹ atipe awọn ọlọpaa kan n janu lasan ni.
Bi ẹ ko ba ni gbagbe, ni ipinlẹ Katsina yii kan naa to jẹ ipinlẹ ibinibi Aarẹ Muhammadu Buhari lawọn ajinigbe kan naa ti ji awọn akẹkọọ gbe ni Kankara.
- Wo orúkọ mẹ́rìnlá tó làmìlaaka tí Lizzy Anjorin sọ ọmọ rẹ̀
- Mi ò bú Baba Adeboye, mo kàn gégùn-ún fún àwọn tí kò ṣàtìlẹyìn fún Oduduwa Republic ni- Sunday Igboho
- À ń ṣe ìwádìí lọ́wọ́ bí ''candle'' ṣe pa Kayode Badru ní ìpínlẹ̀ Eko - Ọlọ́pàá
- Èèyàn 28 kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi tó dànù ní ìpínlẹ̀ Niger
- Amotekun Ondo ju afurasí ajínigbé mẹ́rin s'átìmọ́lé, dóòlà àwọn tí wọ́n jígbé
Àwọn agbébọn ya wọ mọ́ṣáláàṣí, wọ́n gbe èèyàn 40 lọ lásìkò àdúrà Tahajjud
Awọn agbebọn ti gbe eeyan bi ogoji to lọ fun adura Ramdan ni mọṣalaaṣi kan nipinlẹ Katsina.
Iroyin sọ pe ni nkan bi aago meji oru ọjọ Aje ni awọn agbebọn naa yawọ mọṣalaaṣi lasiko ti awọn eeyan naa n gbadura.
Adura oru yii, Lailatu jẹ aṣa awọn Musulumi fun ọjọ mẹwaa to ba kẹhin oṣu Ramadan.
Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn, Babangida Alolo sọ fun awọn akọroyin pe tọkunrin-tobinrin ni awọn olujọsin ti wọn gbe lọ.
Ìdí tí a ò fi pa àwọn ajínigbé tó gbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Kankara nìyìí'
- Mi ó ṣọ̀fọ̀, mo sọkún nítorípé... - Ìyàwó olóògbé Dare Adeboye sọ̀rọ̀ níbi ìsìn idágbére ọkọ rẹ̀
- Ẹ má kí mi ní ìkíni ọdún, ẹ ṣọdún nilée yín - Ààrẹ Buhari
- Èèyàn 28 kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi tó dànù ní ìpínlẹ̀ Niger
- À ń ṣe ìwádìí lọ́wọ́ bí ''candle'' ṣe pa Kayode Badru ní ìpínlẹ̀ Eko - Ọlọ́pàá
- Àyànmọ́ ló mú mi pàdé Princess, èrò wa jọra wọn- Iyabo Ojo
- Wo orúkọ mẹ́rìnlá tó làmìlaaka tí Lizzy Anjorin sọ ọmọ rẹ̀
Bakan naa ni agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Katsina, Gambo Isah, sọ fun BBC pe lootọ ni isẹlẹ naa waye.
Isah sọ pe ninu ogoji eeyan ti wọn jigbe, ọgbọn ti kuro ni akata wọn.
Wọn raaye salọ mọ ajinigbe lọwọ nitori bi awọn ọlọpaa ati araalu to le wọn ṣe finna mọ wọn.
"Lẹyin ti wọn gbe awọn eniyan naa, ọna kan to lọ si ipinlẹ Zamfara ni wọn gba lọ.
O ni: "Ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa ati awọn eeyan to le wọn lo mu ko ku eeyan mẹwaa si ahamọ wọn."
Ọgbẹni Isah sọ pe awọn ọlọpaa ṣi n lepa wọn. O ni l'agbara Ọlọrun, eeyan mẹwaa to ṣi wa nibẹ naa yoo gba ominira laipẹ.
Lati bi oṣu diẹ ni iṣẹlẹ ijinigbe ti n waye ni awọn ipinlẹ to wa ni Ariwa Naijiria, ṣugbọn igba akọkọ re e ti awọn agbebọn kọlu mọṣalaaṣi lati gbe awọn olujọsin.
- Mi ò bú Baba Adeboye, mo kàn gégùn-ún fún àwọn tí kò ṣàtìlẹyìn fún Oduduwa Republic ni- Sunday Igboho
- Ìjọ Kátólìkì, ẹ jèbùrẹ́, ọmọdé ló ṣe èmi àtàwọn ọmọ ìjọ mi- Father Mbaka
- À ń ṣe ìwádìí lọ́wọ́ bí ''candle'' ṣe pa Kayode Badru ní ìpínlẹ̀ Eko - Ọlọ́pàá
- Wo orísun agbára tí Sunday Igboho gbójúlé tí ọwọ́ ẹnikẹ́ni kò fi le tẹ̀ ẹ́
- Emmanuel Abina, ọmọ Olùdarí ìjọ GOFAMINT, Elijah Abina jáde láyé lẹ́yìn ikú ìyàwó rẹ̀
- Sultan Sokoto ní káwọn mùsùlùmí wojú ọ̀run fún oṣù tuntun láti parí àwẹ̀
- Báwo ni ìṣẹ̀lẹ̀ ikú Kayode Badru ṣe ṣẹlẹ̀ ní Celestial Church of Christ ni Eko? ẹ wo ohun tí a mọ̀!