Catholics in Nigeria: Father Mbaka ní kò sí wàhálà láàrín òun àti ìjọ Kátólìkì

Ìjọ Kátólìkì, ẹ jèbùrẹ́, ọmọdé ló ṣe èmi àtàwọn ọmọ ìjọ mi- Father Mbaka

Ẹniọwọ Ejike Mbaka, adari ijọ Adoration Ministries Enugu Nigeria, (AMEN) ti ọpọ mọ si Fada Mbaka titọrọ aforiji lọwọ ijọ Katoliki lapapọ lori awọn aṣiṣe rẹ gbogbo.

Ninu iwaasu rẹ lọjọ Aiku, Fada Mbaka rọ Ẹniọwọ Callistus Onaga to jẹ Biṣọbu ijọ Enugu lati forijioun at'awọnọmọ ijọ oun fun iwa ti wọn hu eleyi to taẹrẹ ba aṣọ ala ijọ naa.

Bakan naa lo tun kilọ fun awọn ọmọ ijọ rẹ pe ki wọn lọ ja ewe agbejẹ mọwọ lẹyin ti awọn kan ninu wọn fi ipa wọ olu ileejọsin ijọ Katoliki lẹkun naa lọjọru nigba ti o dawati.

"Mi o le ṣe lodi si ijo- ta ni mi?

Bawo ni eeyan to ti n ṣiṣẹ ninuijọ fun ọdun marundinlọgbọn bẹrẹ si tun ni maa ba ijọ naa ja. Gbogbo nnkan to wa ninu aye mi, ti ijọ ni."

Fada Mbaka ni ko si ija laarin oun ati Biṣọbu ẹkun naa tabi awọn alaṣẹ ijọ Katoliki rara bi otilẹ jẹ pe awọn kan fẹ ko ṣẹlẹ.

Fada Mbaka ni oun ko kansara sawọ ọmọ ijọ oun fun iwa jagidijagan ti wọn hu bikoṣe akitiyan wọn lati wa oluṣọagutan wọn nigba tiwọn ro pe o sọnu.