Deeper Life Church Kidnap: Àwọn ajínigbé tú Pásítọ̀ Ìjọ Deeper Life sílẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ méje lákàtà wọn

Mọlẹbi Pasitọ ijọ Deeper Life kan tawọn ajinigbe ji lọ ninu ile ijọsin rẹ ti n ke Halleluyah orin ọpẹ lẹyin to gba itusilẹ.

Ọjọ meje lo lo lahamọ ki o to pada sile lọdọ awọn mọlbi rẹ nilu Akure.

Ọkan lara awọn ọmọ rẹ,Fowokemi, lo fidi ọrọ yi mulẹ fun ileeṣẹ BBC lọjọ Aiku.

Fowokemi ko sọ boya awọn mọlẹbi san owo idoola bẹẹ si ni ko si aridaju pe awọn ọlọpaa lo doola Pasitọ naa.

Ohun to daju ti Fowokemi tun fi to wa leti ni pe ile iwosan ni Paitọ Ogedengbe wa nibi to ti n gba itọju lọwọ.

Lara ohun to n ja mọlẹbi laya nipa ijingbe Paitọ naa ni pe o ni ipenija ilera eyi to mu ki o nilo oogun loore koore.

Ileeṣẹ ọlọpaa ko ti sọ nipa bi wọn se doola Pasitọ naa ṣugbọn ni kete ti a ba ti ribi bawọn sọrọ, a o fi to yin leti.

Ọjọ Kẹwaa, Oṣu Karun un ni wọn ji pasitọ Godwin Mayomi Ogedengbe lẹyin to pari isin ninu ile ijọsin rẹ ni nkan bi aago mẹsan an alẹ.

Ohun to ti ṣẹlẹ ṣaaju

Awọn ẹbi ati ara Pasitọ ti wọn jigbe lọ ni ilu Akure ni awọn ko i tii gburo ẹnikẹni nigba ti wọn ti ji baba wọn gbe to jẹ pasitọ ijọ Deeper Life ni ilu Akure.

Ọmọbinrin Pasitọ Ogedengbe, Fowokẹmi ni inu ipaya ati ibẹru ni awọn wa nitori awọn ajinigbe naa ko tii kan si wọn.

O ni baba oun ni ilera to si ni awọn oogun ti oun lo ni ojoojumọ, amọ lati igba ti wọn ti jigbe lọ yii awọn ko gbọ nkankan.

Bakan naa lo ni ikọ Amọtẹkun ati ileeṣẹ ọlọpaa naa ni awọn ko i tii kofiri awọn ajinigbe naa, wi pe ki awọn ẹbi farabalẹ.

''Ohun ti o n bawa lẹru ni wi pe a ko mọ bọya baba mi wa ni alaafia abi boya nkan mi ti ṣẹlẹ''

''Ẹru n ba wa, ọkan wa si poruru si ijinigbe naa''

''A n rọ ijọba, ileeṣẹ ọlọpaa ati ikọ Amọtẹkun lati ba wa wa baba wa nitori ilẹra ara rẹ''

Ọjọ Kẹwaa, Oṣu Karun un ni wọn ji pasitọ Godwin Mayomi Ogedengbe lẹyin to pari isin ninu ile ijọsin rẹ ni nkan bi aago mẹsan an alẹ.

''Àwọn ajínigbé yabọ ṣọ́ọ́ṣì, jí Pásítọ̀ Ìjọ Deeper Life gbẹ lọ ni ìlú Akure''

Inu idaamu ati ipọnju ni awọn ẹbi Pasitọ ijọ Deeper Life Church,Godwin Mayomi Ogedengbe wa lẹyin ti awọn ajinigbe yabo ṣọọṣi rẹ ni ilu Akure, nipinlẹ Ondo.

Pasitọ Ogedengbe ni awọn ajinigbe naa jigbe lọ ni agbegbe Irẹṣẹ ni ilu Akurẹ.

Ọmọbinrin Pasitọ naa to ba BBC Yoruba sọrọ, Fowokẹmi Ogedengbe ni baba oun nikan ni wọn jigbe lọ nigba ti awọn agbegbọn naa yabọ ṣọọṣi.

Fowokemi ni ko pẹ ti awọn ijọ pari eto isin ni ṣọọsi, ti awọn agbebọn yawọle ni wọn ṣi n beere pe, ''pasitọ ijọ da''?

''Ori ikunlẹ ni pasitọ wa to n gbadura lẹyin ẹsin ki awọn ajinigbe to kii mọlẹ ti wọn si fi iya jẹ,ki wọn to gbe wọ inu ọkọ ti wọn si lọ''

''Iyawo pasitọ ati awọn ara ijọ diẹ ṣi wa ni ile ijọsin lasiko ti iṣẹlẹ naa waye, amọ awọn ajinigbe na wọn ki wọn to gbe pasitọ nikan lọ ni nkan bi aago mẹsan alẹ.''

''Awọn ajinigbe naa n sọ ede Pidgin nitori naa n ko le e sọ boya Yoruba ni wọn tabi Hausa.''

Fowokemi Ogedengbe fikun pe iya oun gbiyanju lati fi ọkọ tẹle wọn lẹyin ti wọn gbe baba oun, amọ niiṣe ni wọn bẹrẹ si ni yin ibọn lakọlakọ, ti wọn si salọ.

Nibayii, awọn ẹbi pasitọ naa ti fi tọ ileeṣẹ ọlọpaa ati ikọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Ondo leti lori iṣẹlẹ ijinigbe naa.

Amọ, awọn ajinigbe ko i tii pe awọn ẹbi lati bere ohunkohun to jọ mọ owo ẹmi lọwọ wọn.