Baba Ijesha: Yinka Quadri ní àwọn àgbààgbà òṣèré kò dákẹ́ lórí wàhálà láàrin Iyabọ Ojo ati Yomi Fabiyi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Agba ojẹ ninu awọn oṣere ni Naijiria, Yinka Quadri ti sọrọ lori itahusiraẹni to n waye laarin awọn oṣere meji, Iyabo Ojo ati Yomi Fabiyi lori ẹsun aṣemaṣe ti wọn fi kan oṣerekunrin, Olanrewaju Omiyinka, ti ọpọ eniyan mọ si Baba Ijẹsha.

Yinka Quadri ni lati igba ti iṣẹlẹ Baba Ijẹsha ti ṣẹlẹ ni awọn ko dakẹ gẹgẹ bi agba ninu ẹgbẹ awọn oṣere ni Naijiria , TAMPAN.

Ninu ọrọ rẹ, Quadri ni dajudaju ilẹ Yoruba ko fi aye gba ki nkan ma a daru nigba ti awọn agbaagba wa nibẹ.

Yinka Quadri ni: ''Ni ọlọkan o ju ọkan ni awọn agbaagba oṣere n ba Yomi Fabiyi ati Iyabo Ojo sọrọ lati pe fun alaafia lori ọrọ yii''

''A n pe wọn ni ẹyọ kọọkan bi a ṣe sunmọ wọn si, a ko dakẹ rara''

Amọ Yinka Quadri ni ọrọ awọn mejeeji ti wa ni ọdọ awọn alakoso ẹgbẹ awọn oṣere, ti wọn si n gbe igbeṣẹ lori rẹ.

Agba oṣere naa fikun wi pe laipẹ yii ni ẹgbẹ yoo sọrọ lori rẹ, ti wọn yoo si fi atẹjade lede.

Baba Ijesha yóò ṣì wà látìmọ́lé títí ilé ẹjọ́ yóò fi parí ìyanṣẹ́lódì- Kọmisọ́nnà Ọlọ́pàá

Kọmisọna Ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu ti ni titi igba ti awọn oṣiṣẹ ile ẹjọ yoo pari iyanṣẹlodi wọn ni Baba Ijesha yoo fi wa latimọle.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ pe awọn ko mọ ọ mọ ṣi fi oṣerekunrin, Olanrewaju Omiyinka Baba Ijẹsha, si ahamọ lai gba beeli rẹ.

Kọmisọnna ọlọpaa, Hakeem Odumosu, sọ ọrọ yii gẹgẹ bi esi si iwọde ti akẹẹgbẹ Baba Ijẹsha, Yomi Fabiyi ṣe ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n wadii ẹsun ọdaran, Panti, Yaba.

Ọjọru ni Fabiyi ati awọn eeyan kan ṣe iwọde naa lati beere fun gbigba beeli Omiyinka.

Ṣugbọn ṣa, kọmisanna ọlọpaa naa sọ pe imọran ileeṣẹ eto idajọ lo mu ki awọn o sẹ fi afurasi naa si ahamọ.

Eyi ti ko ṣẹyin bi awọn oṣiṣẹ ile ẹjọ ṣe wa ni iyanṣẹlodi.

Lasiko iwọde to ṣe, Yomi Fabiyi sọ pe ifiyajẹni ati fifi ẹtọ ẹni dun-un ni bi awọn ọlọpaa ko sẹ gba beeli akẹẹgbẹ oun.

Ninu alaye rẹ, kọmisanna ọlọpaa sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti pari iwadii rẹ lori ẹsun ti wọn fi kan Baba Ijẹsha pe o ba ọmọ ọdun mẹrinla ni ibalopọ.

"Nigba ti wọn ṣe iwọde wọn de SCIID, igbakeji kọmisanna to n dari ẹka naa, DCP Adegoke Fayoade ba wọn sọrọ."

"O sọ fun wọn pe nigba ti a pari iwadii wa, a fi abajade rẹ ranṣẹ si ileeṣẹ eto idajọ fun imọran. Imọran ti wọn si gba wa ni pe ka ṣi fi afurasi naa si ahamọ, titi ile ẹjọ yoo fi bẹrẹ iṣẹ pada."

Ọgbẹni Odumosu ṣalaye pe o ṣe e ṣe ki ileeṣẹ eto idajọ tun ero rẹ pa lori bi Baba Ijẹsha ṣe wa ni atimọle, ti iyanṣẹlodi ẹgbẹ JUSUN, ba fi tẹsiwaju kọja bo sẹ yẹ.

O sọ pe awọn oṣiṣẹ ile ẹjọ ti gba lati ma a ṣiṣẹ fun ọjọ mẹta laarin ọsẹ, ti wọn o si ma a fi ọjọ meji to ku yan iṣẹ lodi.

"Ṣugbọn, ti ile ẹjọ ba ṣi fi wa ni titi pa, ileeṣẹ eto idajọ le gbe igbesẹ miran, amọ lọwọlọwọ, imọran ti wọn fun wa ni a n tẹle."