Amnesty International: Saudi Arabia, Iran àti Egypt wà lára orile-ede àgbáyé tó ga jùlọ láti fi ikú ṣe ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ lọ́dún 2020

Ọdun 2020 ni wọn ṣe ayẹyẹ ìfópinsí sí fífi ikú ṣe ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ ni Iran.

Àjọ Amnesty International sọ pé àwọn orile-ede Iha Middle East ni ó pọ̀ jù lọ́dún 2020 gẹ́gẹ́ bí orile-ede tó n fi ikú ṣe ìjìyà ẹsẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bi àbájáde ìwádìí kan ṣe sọ, Iran, Egypt, Iraq ati Saudi Arabia ló kó ìdá mejidinlaadọrun nínú ọgọrun ènìyàn 483 ti wọ́n pa lágbàáyé.

Amensty fẹ̀sùn kàn wọ́n jẹ́ orílè-èdè tí kìí fi tí ọmọ ènìyàn ṣe, bí ọ̀pọ̀ orílè-èdè lágbàáyé kojú mọ ọ̀nà àti dóòlà ẹ̀mí àwọn ará ìlú lọ́wọ́ ààrùn Covid19.

Iye ènìyàn ti ìjọba tí pa ni àbájáde ìwádìí fi hàn pé o kéré jọjọ ni àgbáyé ṣùgbọ́n kò sí orile-ede China nibẹ.

Ìgbàgbọ́ ni pe orílẹ̀ èdè China máa n pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn lọ́dún ṣùgbọ́n wọ́n fi àkọsílẹ̀ ipaniyan yìí pamọ́ fún àgbáyé.

Ni orile-ede North Korea àti Vietnam pẹ̀lú kò sí ẹ̀rí àkọsílẹ̀ tó péye.

Ìpànìyàn 483 ni ó wáyé ní Ìpínlẹ̀ méjìdínlógún gẹ́gẹ́ bí àbájáde ìwádìí ọdún 2020 ṣe sọ èyí tó ṣàfihàn àdínkù ìdá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n yàtọ̀ sí ènìyàn 657 ti wọ́n pa ni ọdún 2019, to sì jẹ́ àdínkù sí ìdá àádọ́rin ènìyàn 1,634 ti wọ́n pa lọ́dún 2015 gẹ́gẹ́ bi Amnesty international ṣe sọ.

Ni ìhà middle East iye gbogbo ènìyàn ti wọ́n pa dinku lati 579 lọ́dún 2019 sí 437 lọ́dún 2020.

Èyí wáyé nítorí àdínkù Ìpànìyàn to máa ń wá láti orile-ede Saudi Arabia to jẹ́ ida marunlelọ́gọ́rin tiwọn tí pa ènìyàn mẹ́tàdínlógbọ̀n péré, bákan naa ni àdínkù ìdá àádọ́ta nínú Ìpànìyàn to máa n wáyé ni Iraq.

Ẹ̀wẹ̀, àbájáde kan fi yẹni pé ìdá ọ̀ọ́dúnrún ni Ìpànìyàn láti ọwọ́ ìjọba fi peléke si ni orile-èdè Egypt.

Eyí kò fi bẹ#e han nítorí irú ìwà yìí tí dinku ni àgbáyé nítorí náà idajọ́ ikú gẹ́gẹ́ bí ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ ni Egypt jẹ́ 107, eyi sì mú wọn jẹ́ orílè-èdè kẹta lágbàáyé tó máa n lo ìdájọ́ ikú gẹ́gẹ́ bí ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀.

Ènìyàn mẹ́tàlélógún tó jẹ́ ọkùnrin láàrin wọn ní wọ́n fi ẹ̀sùn tó níṣe pẹ̀lú òṣèlú kàn èyí tí àjọ Amnesty International ni ko ba ojú mu tó nítorí ìwà ìfìyàjẹni lásán ni kò tọ̀nà.

Àlékún ènìyàn metadinlaadota ló wáyé láàárín inú oṣù kẹwàá àti ìkọkànlá, lásìkò tí àwọn kan gbìyànjú lati ja ọgbà ẹ̀wọ̀n al-Aqrab tí ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́pàá ati àwọn ẹlẹ̀wọ̀n tí wọ́n dájọ́ ikú fún pàdánù ẹ̀mí wọn.

Iran to pa ènìyàn 246 lo jẹ́ orílè-èdè to gbé ipò kejì lágbàáyé lẹ́yìn China

Eyí kò fi bẹe han nítorí irú ìwà yìí tí dinku ni àgbáyé nítorí náà idajọ́ ikú gẹ́gẹ́ bí ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ ni Egypt jẹ́ 107, eyi sì mú wọn jẹ́ orílè-èdè kẹta lágbàáyé tó máa n lo ìdájọ́ ikú gẹ́gẹ́ bí ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀.

Ènìyàn mẹ́tàlélógún tó jẹ́ ọkùnrin láàrin wọn ní wọ́n fi ẹ̀sùn tó níṣe pẹ̀lú òṣèlú kàn èyí tí àjọ Amnesty International ni ko ba ojú mu tó nítorí ìwà ìfìyàjẹni lásán ni kò tọ̀nà.

Àlékún ènìyàn metadinlaadota ló wáyé láàárín inú oṣù kẹwàá àti ìkọkànlá, lásìkò tí àwọn kan gbìyànjú lati ja ọgbà ẹ̀wọ̀n al-Aqrab tí ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́pàá ati àwọn ẹlẹ̀wọ̀n tí wọ́n dájọ́ ikú fún pàdánù ẹ̀mí wọn.

Iran to pa ènìyàn 246 lo jẹ́ orílè-èdè to gbé ipò kejì lágbàáyé lẹ́yìn China

Ṣùgbọ́n Amnesty International sọ pé ó ṣeé se pé wọ́n ń ṣẹ èyí kí ayé ma bá bú ẹnu àtẹ́ lù wọ́n nítorí oroto yí dídi ààrẹ G20 kan ni

Ni orile-ede Amẹrika ààrẹ Donald Trump tí padà sí orí òfin Ìpànìyàn lẹ́yìn àlàfo ọdún mẹ́tàdínlógún, bákan náà ló si jan pípa ènìyàn Mẹ́wàá loǹtẹ̀ láàárín oṣù mefa2

India 🇮🇳 Oman, Qatar ati Taiwan náà tí padà sórí ìdájọ́ ikú

"Bi àgbáyé ṣe n wá ọ̀nà àbáyọ onírúurú àjàkálẹ̀ ààrùn bí Kọlẹra àti onírúurú àìsàn mìíràn, ọ̀pọ̀ àwọn ìjọba mìíràn n padà sí ìdí òfin Ìpànìyàn ní gbogbo ọ̀nà," èyí ni ọrọ Agnès Callamard, akọ̀wé àgbà àjọ Amnesty International.

" Ìdájọ́ ikú yìí kàn wá gbọ̀ngbọ̀n, bí wọ́n ṣe tún wá n ṣe èyí lásìkò àjàkálẹ̀ fihàn pé ara o rokun ara o radiyẹ"

Callamard sọ pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ló n dúró de ìdájọ́ ikú àwọn wọ́nyii kò sì ní àǹfààní láti rí ìrànwọ́ agbẹjọ́rò kó da tí agbẹjọ́rò bá ṣetán láti rán wọn lọ́wọ́.

"Lílo ìdájọ́ ikú nínú àlàyé yìí jẹ ẹ̀sẹ̀ sí ẹ̀dá ènìyàn àti títẹ ẹ̀tọ́ omonìyàn mọ́lẹ̀.