Palestine vs Israel latest updates: Aàrẹ Joe Biden sọ̀rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ lórí ìja Isreal àti Palestine

Lati igba ti ọrọ laasigbo to n ṣẹlẹ laarin awọn eeyan Palestine ati Isreal ti bẹrẹ lo ti n bi Ige ati Adubi.Ogójì èèyàn ti pàdánù ẹ̀mí wọn nítorí ìjà tó ń wáyé láàrín Israel àti Palestine ní Lod

Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí lo si ti lọ si iṣẹlẹ naa ni eyi ti awọn eeyan ti n fi ero wọn han loriṣiiriṣi.

Fun igba akọkọ aare Joe Biden to n tukọ America sọrọ nipa ikọlu to n waye naa.

Aarẹ Joe Biden ṣalaye pe ohun ibanujẹ patapata lo n ṣẹlẹ lasiko yii.

O ni ki Nethanyau wa ojutu si iṣoro naa ki alaafia si jọba ni ẹkun agbaye yii.

Bakan naa ni Joe Biden ni: "Ireti mi ni pe ohun gbogbo yoo tete yanju laipẹ ti alaafia yoo si jọba.

Aarẹ America ni: " Orilẹ-ede Isreal ni ẹtọ lati gbeja ara rẹ nigba to ba ri ọpọlọpọ rọkẹẹti to n fo niluu wọn".

Nile ijọba ni White House ni America ni Joe Biden ti ba Nethanyahu sọrọ naa.

Aare Biden ko sọ nkankan nipa Palestine ninu ọrọ rẹ.

Ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ Republican ati awọn ọmọ ẹgbẹ Biden ni wọn n woye igbesẹ rẹ laori ẹtọ ọmọniyan to ni oun yoo gbe ṣaaju.

Joe Biden gab Adari Isreal, Benjamin Nethayau nimọran lati tete wa wọrọkọ fi ṣe ada ki ohun gbogbo pada si pẹlẹkutu.