You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Baba Ijesa: Yomi Fabiyi ní àṣeyọrí ńlá ní gbígba béèlì Omiyinka jẹ́
Nibayii to ku wakati diẹ ki awọn ọlọpaa gba oniduro James Olanrewaju, Baba Ijesa, awọn alatilẹyin rẹ kan ti n ṣọ ero ọkan wọn lori gbigba oniduro rẹ.
Ninu wọn ni Yomi Fabiyi ti oun naa jẹ gbajugbaja oṣere tiata ati alatilẹyin fun Baba Ijesa.
Fabiyi sọ fun BBC pe nitori pe awọn kan n tapa si ofin Naijiria pe ki wọn fi Ijesa si ahamọ lai ṣe igbẹjọ rẹ, gbigba beeli rẹ yi jẹ aṣeyọri to lamilaka.
- Iyabo Ojo fèsì lórí béèlì tí wọ́n fún Baba Ijesha
- Princess pàrokò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lẹ́yìn tí Baba Ijesha gba béélì
- Baba Ijesha gba béélì níléẹjọ́ Májísírétì, àmọ́ ọ̀rọ̀ kù kó tó jáde l’àhámọ́
- Ẹ fi Baba Ijesha sílẹ̀ fún mi, màá ṣe onídùróó rẹ̀ - Yomi Fabiyi
- Màá pe Kọ̀mísánà ọlọ́pàá Eko àti igbákejì rẹ̀ lẹ́jọ́ lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha - Amofin
- ''Àwa àgbààgbà òṣèré kò dákẹ́ lórí wàhálà láàrin Iyabọ Ojo ati Yomi Fabiyi nitori Baba Ijẹsha''
- 'Nígbá tí a rí Baba Ijesha lónìí ní Panti, ohun tójú wa rí, ẹnu kò lè sọ o!'
- Ṣé lóòtọ́ ni Iyabo Ojo ti bẹ Yomi Fabiyi lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha tó wà ní Panti?
O ni ọrọ yii ki ba ma ri bẹẹ ṣugbọn ''ai fun awọn afurasi ni beeli jẹ ọna kan ti wọn fi n pa awọn eeyan lahamọ, ti wọn fi n pa wọn lẹnu mọ, ti wọn si fi n fi ẹtọ dun awọn eeyan''
Fabiyi tẹsiwaju pe, awọn ko ni erongba lati ma ṣe ayẹyẹ lori gbigba beeli yii nitori igbẹjọ si wa niwaju ti Baba Ijesha yoo jẹ niwaju adajọ.
Yomi Fabiyi wa fi iyalẹnu rẹ han nipa gbogbo awọn ti wọn n sọ wi pe ki wọn mase fun Ijesa ni beeli.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Oluwo pe ìpàdé àpérò láti parí aáwọ̀ àgbẹ̀ àti darandaran
- Ẹ̀yin ọdọ́, ẹ sọ́ra fún ìtànjẹ láti darapọ̀ mọ́ ìyapa Naijiria - YAF
- Sunday Igboho, jọ̀ọ́ má gbé ìwọ́de Yoruba Nation wọ Iseyin - Aseyin ṣèkìlọ̀
- Sunday Igboho lọ sọ́dọ̀ Guru Maharaji lórí ìdásílẹ̀ Yoruba Nation
- "Sunday Igboho kò fí lààkáyé kún ìjìjàgbara rẹ̀ nípa àtakò sí ìbò 2023"
- Mò ń wá olè tó jí nńkan ní ọọ́físì mi, ẹ̀bùn owó iyebíye rèé - Afeez Eniola
- Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìlú Modakeke àti Ile Ife
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni Baba Ijesha ti jáde ní àhámọ́ ọlọ́pàá?
''Ṣe iyẹn wa tumọ si pe wọn da lare ni? Gbogbo ẹni to ba n hu iru iwa yi, wọn wa lara awọn to n jẹ ki Naijiria maa ni ifasẹyin.''
O wa gba araalu ni imọran lati tẹle ofin Naijiria ki idagbasoke baale ba orileede naa.
''Gbogbo wa la ni ipa la ti ko, ati oniroyin ati araalu,o yẹ ka lọ tun ero wa pa ki a ṣe ohun to tọ''
Lori boya yoo ṣi tẹsiwaju pẹlu atilẹyin fun Baba Ijesa, o ni oun ''ko si lẹyin ki eeyan fi irọ tabi amulumala lati fi ran ẹlomiran lẹwọn''
N ko ni ohunkohun lati sọ nipa beeli ti wọn fun Baba Ijesha - Princess
BBC Yoruba tun ba adẹrinposonu nni, Damilola Adekoya tawọn eeyan mọ si Princess sọrọ, ẹni tii se iya ọmọ ti wọn ni Baba Ijesha se asemase pẹlu rẹ.
Nigba to n ba wa sọrọ, Princess ẹni to mi kanlẹ wa sọ fun wa pe oun ko ni nkankan lati sọ lori ọrọ yii.
A tun gbiyanju lati ba agbẹjọro Baba Ijesa naa sọrọ lori igbesẹ ti wọn n gbe lati yanju gbogbo ohun to nii ṣe pẹlu gbigba oniduro rẹ.
Eeyan kan ti ko darukọ ara rẹ lo gbe ago ipe agbẹjọro Adesina Ogunlana, ti o si ni wọn ko ti le da wa lohun niisinyi.
Ireti wa ni pe wọn yoo pari gbogbo eto gbigba oniduro Baba Ijesa lonii, lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa ni ko san ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira fun gbigba oniduro rẹ.